Àwọn Ìṣẹ̀dá Ọlọ́run Ń Fi Ògo Rẹ̀ Hàn

Tá a bá ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ìṣẹ̀dá tó wà ní àyíká wa, a máa rí àwọn ànímọ́ Ẹlẹ́dàá wa, àá sì lè túbọ̀ sún mọ́ ọn.

Àwọn Ìṣẹ̀dá Ọlọ́run Ń Fi Ògo Rẹ̀ Hàn

Ṣó o máa ń kíyèsí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá lójoojúmọ́? Tó o bá ń kíyè sí àwọn nǹkan yìí, wàá rí i pé ọgbọ́n Ọlọ́run ò lópin, ó sì nífẹ̀ẹ́ wa gan-an.

Ìmọ́lẹ̀ àti Àwọ̀

Oríṣiríṣi àwọ̀ tí Jèhófà fi sọ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ lọ́jọ̀ jẹ́ ẹ̀rí pé ìfẹ́ tó ní sí wa jinlẹ̀ gan-an.

Omi

Ojoojúmọ́ ni omi ń jẹ́rìí sí agbára ńlá àti ọgbọ́n Ẹlẹ́dàá wa Jèhófà Ọlọ́run.

Àwọn Ohun Abẹ̀mí Ń Ṣiṣẹ́ Pọ̀

Àwọn ohun tó wà láyé ńkọ́? Ṣé ẹ̀rí wà pé gbogbo nǹkan alààyè ni ètò wà fún àti pé ńṣe ni gbogbo wọn ń ṣiṣẹ́ pọ̀?

Iṣẹ́ Ọnà

Àwọn iṣẹ́ ọnà tó wà nínú ìṣẹ̀dá ò kàn ṣàdédé wà. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló ń fi hàn pé ẹnì kan ló fi ọgbọ́n ṣiṣẹ́ àrà náà.