Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌBÉÈRÈ 7

Kí Ni Bíbélì Sọ Tẹ́lẹ̀ Nípa Ọjọ́ Wa?

“Orílẹ̀-èdè máa dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba . . . Gbogbo nǹkan yìí jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ wàhálà tó ń fa ìrora.”

Mátíù 24:7, 8

“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wòlíì èké máa dìde, wọ́n sì máa ṣi ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà; torí pé ìwà tí kò bófin mu máa pọ̀ sí i, ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ máa tutù.”

Mátíù 24:11, 12

“Tí ẹ bá gbọ́ nípa àwọn ogun, tí ẹ sì gbọ́ ìròyìn nípa àwọn ogun, ẹ má bẹ̀rù; àwọn nǹkan yìí gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀, àmọ́ òpin ò tíì dé.”

Máàkù 13:7

“Ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára máa wáyé, àìtó oúnjẹ àti àjàkálẹ̀ àrùn sì máa wà láti ibì kan dé ibòmíì; ẹ máa rí àwọn ohun tó ń bani lẹ́rù, àwọn àmì tó lágbára sì máa wà láti ọ̀run.”

Lúùkù 21:11

“Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yóò jẹ́ àkókò tí nǹkan máa le gan-an, tó sì máa nira. Torí àwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn nìkan, wọ́n á nífẹ̀ẹ́ owó, wọ́n á jẹ́ afọ́nnu, agbéraga, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìmoore, aláìṣòótọ́, ẹni tí kò ní ìfẹ́ àdámọ́ni, kìígbọ́-kìígbà, abanijẹ́, ẹni tí kò lè kó ara rẹ̀ níjàánu, ẹni tó burú gan-an, ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ ohun rere, ọ̀dàlẹ̀, alágídí, ajọra-ẹni-lójú, wọ́n á fẹ́ràn ìgbádùn dípò Ọlọ́run, wọ́n á jọ ẹni tó ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn, àmọ́ ìṣe wọn ò ní fi agbára rẹ̀ hàn.”

2 Tímótì 3:1-5