Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ẹ Dẹ́kun Ṣíṣàníyàn”

“Ẹ Dẹ́kun Ṣíṣàníyàn”

“Ẹ Dẹ́kun Ṣíṣàníyàn”

“Owó tán nínú àkáǹtì wa ní báńkì, títí kan owó tó wà nínú àkáǹtì tá a ṣí lórúkọ àwọn ọmọ wa. Àìmọye oṣù ni owó kankan ò fi wọlé fún wa.”

● Mò ń bójú tó iléèwé kan tó wà ní àrọko kan lórílẹ̀-èdè Íńdíà, ó sì ń gbèrú dáadáa. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí iye akẹ́kọ̀ọ́ tó wà níléèwé náà jẹ́ nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500]. Nígbà tó yá, iléèwé kan tó lóókọ nígboro ìlú náà bẹ̀rẹ̀ sí gbé àwọn bọ́ọ̀sì wá sí àdúgbò wa, wọ́n sì ṣe àwọn nǹkan táá mú kí àtibẹ̀rẹ̀ iléèwé lọ́dọ̀ wọn rọrùn. Èyí mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ tó ń wá síléèwé lọ́dọ̀ mi lọ sí ìgboro láti máa bá ẹ̀kọ́ wọn lọ níléèwé náà. Bó ṣe di pé iye àwọn ọmọ tó ń wá síléèwé lọ́dọ̀ mi lọ sílẹ̀ látorí nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] sí ọgọ́ta [60] nìyẹn. Ohun tó tiẹ̀ tún wá mú kí ọ̀rọ̀ náà burú jù ni pé, láàárín ìgbà yẹn, ẹnì kan tá a jọ dòwò pọ̀ níléèwé náà dalẹ̀ àdéhùn wa, ó sì jẹ mí lówó. Ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ iléèwé ni mo jẹ lówó, bí mo ṣe wọko gbèsè nìyẹn.

Ìdílé wa jókòó pà pọ̀ láti jíròrò ohun tá a máa ṣe. Gbogbo wa pátá la fi hàn pé a lẹ́mìí ìfara ẹni rúbọ, a sì sapá láti tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ìyànjú Jésù pé ká jẹ́ kí ojú wa “mú ọ̀nà kan” tó bá dọ̀rọ̀ ìnáwó, ìyẹn ni pé a ò náwó kọjá ohun tó ń wọlé fún wa. (Mátíù 6:22, 25) Ìgbà kan tiẹ̀ wà tá ò lo ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wa mọ́, torí owó epo àti owó tá a máa fi bójú tó o. Ká bàa lè dín iye tá à ń ná sórí oúnjẹ kù, ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ la máa ń lọ sọ́jà, torí pé iye tí wọ́n ń ta àwọn oúnjẹ tó ṣẹ́ kù máa lọ sílẹ̀ lákòókò yẹn. A tún dín iye oúnjẹ tá a máa ń jẹ kù.

Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá, ìdí nìyẹn tá a fi kà á sí ohun pàtàkì láti máa péjọ pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwa láwọn ìpàdé Kristẹni. (Hébérù 10:25) Torí náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àtijẹ àtimu kò rọrùn rárá, a pinnu pé a ò ní ṣaláì máa lọ sáwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ, bó bá tiẹ̀ gba pé ká rìnrìn àjò ọ̀nà jíjìn. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gba pé ká máa rìnrìn àjò ọ̀nà jíjìn láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Dípò ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, a máa ń gun alùpùpù, bó tiẹ̀ jẹ́ pé alùpùpù ò lè gbé ju èèyàn méjì lọ lẹ́ẹ̀kan náà.

Àmọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ò wá ní ká dín àkókò tá à ń lò lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ kù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìyàwó mi pẹ̀lú ọmọbìnrin wa bẹ̀rẹ̀ sí í lo àkókò púpọ̀ sí i láti máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà míì, wọ́n máa ń rìnrìn kìlómítà mẹ́fà sí mẹ́jọ láti lọ kọ́ àwọn tó fìfẹ́ hàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Èmi àti ọmọ wa ọkùnrin tún sapá láti máa lo àkókò púpọ̀ sí i láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Ní báyìí, àtijẹ àtimu wa kò le bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Ìdílé wa ti kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí pé kò yẹ kéèyàn máa ka àwọn nǹkan ìní tara sí pàtàkì ju bó ṣe yẹ lọ. A tún kẹ́kọ̀ọ́ pé a ò gbọ́dọ̀ máa ṣàníyàn ju bó ṣe yẹ lọ nípa àwọn ohun tó bá ju agbára wa lọ. Sáàmù 55:22 ti fún wa níṣìírí gan-an ni. Ó sọ pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró. Kì yóò jẹ́ kí olódodo ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n láé.” A ti rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé ni ọ̀rọ̀ yìí nígbà tí àtijẹ àtimu le koko fún wa!—Ẹnì kan ló kọ ọ́ ránṣẹ́.