Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ TÓ DÁ LÓRÍ ÀKÒRÍ Ẹ̀YÌN ÌWÉ

Bó O Ṣe Lè Jẹ́ Bàbá Rere

Bó O Ṣe Lè Jẹ́ Bàbá Rere

Ọmọ ilẹ̀ South Africa kan tó ń jẹ́ Michael * ti ṣe gudugudu méje kó bàa lè jẹ́ bàbá rere. Ṣùgbọ́n, kò sígbà tí inú rẹ̀ kì í bà jẹ́ tó bá rántí ọmọ rẹ̀ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] tó yàyàkuyà. Ṣe ló máa ń rò pé òun kò tọ́mọ náà dáadáa. Ó máa ń ṣàròyé pé bóyá nǹkan wà tó yẹ kí òun ṣe tí òun kò ṣe.

Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ fún ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Terry tó ń gbé nílẹ̀ Sípéènì, ó jọ pé òun tọ́ ọmọ rẹ̀ yanjú. Ohun tí Andrew ọmọ rẹ̀ sọ ni pé: “Ọ̀pọ̀ ohun tí mo máa ń rántí jù nípa ìgbà èwe mi ni bí bàbá mi ṣe máa ń kàwé sí mi létí, bó ṣe máa ń bá mi ṣeré, tó sì máa ń mú mi jáde ká lè jọ wà pa pọ̀. Bàbá mi ló jẹ́ kó rọrùn fún mi láti kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan.”

Ká sòótọ́, kò rọrùn rárá láti jẹ́ bàbá rere. Ṣùgbọ́n, àwọn ìlànà kan wà tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn bàbá ló ti wá gbà pé táwọn bá fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, àwọn máa ṣe ara wọn àti ìdílé wọn láǹfààní. Jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì yìí àti bó ṣe wúlò fún àwọn bàbá.

1. Máa Wáyè Gbọ́ Ti Ìdílé Rẹ

Báwo ni ẹ̀yin bàbá ṣe lè fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ yín jẹ yín lógún? Iṣẹ́ ribiribi lẹ̀ ń ṣe bí ẹ ṣe ń pèsè ilé tó dáa fún wọn láti gbé, tẹ́ ẹ sì ń sapá láti bọ́ àwọn ọmọ yín. Ohun tẹ́ ẹ̀ ń ṣe yìí fi hàn pé ẹ nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ yín. Àmọ́, tí ẹ kì í bá lo àkókò tó pọ̀ tó pẹ̀lú wọn, ó lè jẹ́ kí wọ́n máa rò pé ẹ fẹ́ràn iṣẹ́ yín, àwọn ọ̀rẹ́ yín tàbí eré ìnàjú ju àwọn lọ.

Ìgbà wo ló yẹ kí bàbá bẹ̀rẹ̀ sí í wáyè gbọ́ tàwọn ọmọ rẹ̀? Àtìgbà tí ọmọ ti wà nínú oyún ni ìyá ti máa ń fà mọ́ ọmọ rẹ̀. Ìwádìí fi hàn pé tọ́mọ bá ti pé oṣù méjì nínú oyún ló ti lè gbọ́ ohun téèyàn bá ń sọ. Bàbá náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í fà mọ́ ọmọ rẹ̀ nígbà tó ṣì wà nínú oyún. Ó lè máa tẹ́tí sí bí ọmọ náà ṣe ń dún nínú ikùn ìyá rẹ̀, kó máa bá a sọ̀rọ̀, kó sì máa kọrin fún un.

Ìlànà Bíbélì: Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn bàbá máa ń kópa nínú títọ́ àwọn ọmọ wọn. Bíbélì gba àwọn bàbá níyànjú láti máa wáyè gbọ́ ti àwọn ọmọ wọn. Abájọ tí Diutarónómì 6:6, 7 fi sọ pé: “Kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí sì wà ní ọkàn-àyà rẹ; kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ gbìn wọ́n sínú ọmọ rẹ, kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.”

2. Bàbá Rere Máa Ń Tẹ́tí sí Ọmọ Rẹ̀

Fara balẹ̀ gbọ́ tẹnu ọmọ rẹ láì dá a lẹ́bi

Láti lè bá ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ bó ṣe tọ́, o gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó máa ń tẹ́tí sí ohun tí ọmọ náà bá ń sọ. O gbọ́dọ̀ fara balẹ̀ gbọ́rọ̀ rẹ̀ láì faraya.

Tí àwọn ọmọ rẹ bá mọ̀ pé o kì í pẹ́ bínú àti pé o máa dá àwọn lẹ́bi, wọn kò ní sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn fún ẹ. Àmọ́ tó o bá fara balẹ̀ gbọ́ ohun tí wọ́n ní í sọ, ṣe lò ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ ọ́ lógún. Wọ́n á sì máa fẹ́ láti sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wọn fún ẹ.

Ìlànà Bíbélì: Àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì wúlò nínú gbogbo ohun tí à ń ṣe lójoojúmọ́. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé: “Kí olúkúlùkù ènìyàn yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú.” (Jákọ́bù 1:19) Àwọn bàbá tó ń fi ìmọ̀ràn Bíbélì yìí sílò yóò lè bá àwọn ọmọ sọ̀rọ̀ fàlàlà láìsí ìṣòro.

3. Máa Gbóríyìn fún Wọn, Kó O sì Máa Fìfẹ́ Bá Wọn Wí

Tí inú bá tiẹ̀ bí ẹ tàbí tí ohun tọ́mọ rẹ ṣe bá ká ẹ lára gan-an, má ṣe kanra mọ́ ọn. Ìfẹ́ ni kó o fi bá a wí kó lè mọ̀ pé àǹfààní ọjọ́ iwájú òun lò ń bá òun sọ. Èyí lè gba pé kó o gbà á nímọ̀ràn, kó o tọ́ ọ sọ́nà, kó o kó ọ lóhun tó yẹ kó ṣe tàbí kó o bá a wí.

Tó o bá fẹ́ kí ìbáwí wọ ọmọ lọ́kàn, o ní láti máa gbóríyìn fún un déédéé. Òwe àtijọ́ kan sọ pé: “Bí àwọn èso ápù ti wúrà nínú àwọn ohun gbígbẹ́ tí a fi fàdákà ṣe ni ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó tọ́.” (Òwe 25:11) Abájọ tí wọ́n fi máa ń sọ pé yiniyini kẹ́ni ṣè míì. Tó o bá ń yin àwọn ọmọ rẹ, orí wọn máa wú, ara máa tù wọ́n, wọ́n á sì rí i pé o mọyì àwọn. Bàbá tó bá ń gbóríyìn fáwọn ọmọ rẹ̀ déédéé yóò jẹ́ kí wọ́n lè nígboyà, kí wọ́n sì máa bá iṣẹ́ rere nìṣó.

Ìlànà Bíbélì: “Ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe máa dá àwọn ọmọ yín lágara, kí wọ́n má bàa soríkodò.”Kólósè 3:21.

4. Nífẹ̀ẹ́ Aya Rẹ Dénú, Kó O sì Máa Fọ̀wọ̀ Wọ̀ Ọ́

Bí bàbá bá ṣe ń ṣe sí aya rẹ̀ máa ń nípa lórí àwọn ọmọ rẹ̀. Àwọn kan tó ṣèwádìí nípa ìdàgbàsókè ọmọ sọ pé: “Ọ̀kan lára ohun tó dáa jù tí bàbá lè ṣe fáwọn omọ rẹ̀ ni pé kó máa ṣìkẹ́ ìyá wọn. . . . Bàbá àti ìyá tó bá ń ṣìkẹ́ ara wọn ń pa kún ayọ̀ àwọn ọmọ wọn àti àlàáfíà ìdílé wọn.”—Ìwé The Importance of Fathers in the Healthy Development of Children. *

Ìlànà Bíbélì: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, . . . Kí olúkúlùkù yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀.”Éfésù 5:25, 33.

5. Máa Fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Sílò

Bí bàbá bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tọkàntọkàn, ogún tó dáa jù lọ ló ń fi sílẹ̀ fáwọn ọmọ rẹ̀, ìyẹn ni àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Baba wọn ọ̀run.

Ọkùnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń jẹ́ Antonio ti ṣiṣẹ́ kára fún ọ̀pọ̀ ọdún láti tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́fà dàgbà. Nínú lẹ́tà tí ọmọbìnrin rẹ̀ kan kọ sí i, ó sọ pé: “Bàbá mi ọ̀wọ́n, mo fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún bí ẹ ṣe tọ́ mi dàgbà láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí n sì nífẹ̀ẹ́ ara mi àtàwọn aládùúgbò mi. Ẹ ti jẹ́ kí n níwà ọmọlúwàbí. Ìwà àti ìṣe yín jẹ́ kí n mọ̀ pé ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ẹ sì fẹ́ràn mi dénú. Ẹ ṣeun fún bí ẹ ṣe ka Jèhófà sí ẹni pàtàkì jù nígbèsí ayé yín àti bí ẹ ṣe fi hàn pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run làwa ọmọ yín jẹ́!”

Ìlànà Bíbélì: “Kí ìwọ sì fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo okunra rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ. Kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí sì wà ní ọkàn-àyà rẹ.”Diutarónómì 6:5, 6.

Ó ṣe kedere pé àwọn kókó márùn-ún yìí nìkan kò tó láti mọ béèyàn ṣe lè jẹ́ bàbá rere. Àti pé a kì í ṣe ẹni pípé, kò sí bá a ṣe lè jẹ́ bàbá rere tó, a máa ṣe àṣìṣe nígbà míì. Àmọ́, tó o bá ṣe àwọn ohun tá a sọ yìí, tó o nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ, tó o sì sapá láti fún wọn ní ohun tí wọ́n nílò, o jẹ́ bàbá rere. *

^ ìpínrọ̀ 3 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

^ ìpínrọ̀ 19 Kódà tí bàbá àti ìyá ò bá gbé pọ̀ mọ́, àmọ́ tó bá ń fọ̀wọ̀ wọ aya rẹ̀, ìyẹn á jẹ́ kí ìrẹ́pọ̀ wà láàárín àwọn ọmọ àti ìyá wọn.

^ ìpínrọ̀ 25 Àlàyé tún wà lórí ìtọ́sọ́nà fún àwọn ìdílé nínú ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. O lè rí i lórí ìkànnì www.mr1310.com..