JÍ! January 2015 | Bí O Ṣe Lè Láyọ̀

Àwọn ìlànà inú Bíbélì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti gbé ìgbésí ayé aláyọ̀. Wo mẹ́rin lára àwọn ìlànà Bíbélì yìí.

Ohun Tó Ń lọ Láyé

Àwọn kókó ọ̀rọ̀: pípa ètò ààbò igbó kìjikìji Ecuador tì, ìṣòro rírí kòkòrò àrùn HIV nínu ẹ̀jẹ̀ àti ìjà lórí ẹni tó máa tọ́jú ajá ní Ọsirélíà.

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Bí O Ṣe Lè Láyọ̀

Ṣé àwọn ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì lè fún wa láyọ̀? Àpilẹ̀kọ yìí jíròrò ìlànà mẹ́rin tó lè ràn wá lọ́wọ́.

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ

Bí Ẹ Ṣe Lè Gbà Fún Ara Yín

Àwọn nǹkan mẹ́rin tó lè ràn ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ lọ́wọ́ láti paná àríyànjiyàn, kẹ́ ẹ sì jọ wá ojútùú sí ìṣòro yín.

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ

Tí Ọmọ Rẹ Bá Ń Purọ́

Kí ló yẹ kó o ṣe bí ọmọ rẹ bá ń purọ́? Àpilẹ̀kọ yìí fún wa ní ìmọ̀ràn Bíbélì lórí bó o ṣe lè kọ́ ọmọ rẹ láti máa sọ òtítọ́.

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Ìmọ́tótó

Wo ìmọ̀ràn Bíbélì tó ti ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ láti wà ní mímọ́, kí ìlera wọn sì dáa.

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Ilẹ̀ Ayé

Ṣé ayé máa pa rẹ́?

“Àmì Ìrántí Kan Tó Ṣe Kedere”

Kí nìdí tí wọn ò fi tún àwókù ilé kan ní Hiroshima, Japan kọ láti ọdún 1945? Kà nípa ilé yẹn àti bó ṣe tan mọ́ ìlérí tí Bíbélì ṣe nípa ọjọ́ iwájú.

Àwọn Nǹkan Míì Tó Wà Lórí Ìkànnì

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Yẹra fún Wíwo Àwòrán Ìṣekúṣe?

Kí ló jọra nínú wíwo àwòrán ìṣekúṣe àti mímu sìgá?

Jẹ́ Onínúure àti Ọ̀làwọ́

Wo bí Kọ́lá àti Tósìn ṣe túbọ̀ gbádùn ara wọn nígbà tí wọ́n jọ lo nǹkan ìṣeré wọn.