Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Másórétì fara balẹ̀ ṣe àdàkọ Ìwé Mímọ́

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | BÍ ỌLỌ́RUN ṢE PA​—BÍBÉLÌ MỌ́

Bíbélì Bọ́ Lọ́wọ́ Àwọn Tó Fẹ́ Yí Ọ̀rọ̀ Inú Rẹ̀ Pa Dà

Bíbélì Bọ́ Lọ́wọ́ Àwọn Tó Fẹ́ Yí Ọ̀rọ̀ Inú Rẹ̀ Pa Dà

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO: A ti sọ̀rọ̀ nípa ohun méjì tó lè mú ká má mọ ohun tó ń jẹ́ Bíbélì rárá, àkọ́kọ́ ni bí ohun tí wọ́n kọ ọ́ sí ṣe lè tètè jẹrà àti báwọn kan ṣe fẹ́ rẹ́yìn Bíbélì. Àmọ́ kò tán síbẹ̀, àwọn adàwékọ àtàwọn atúmọ̀ èdè náà ti gbìyànjú láti yí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pa dà. Nígbà míì, wọ́n máa ń fẹ́ yí ọ̀rọ̀ Bíbélì pa dà kó lè bá ẹ̀kọ́ tiwọn mu, dípò ẹ̀kọ́ tó wà nínú Bíbélì. Jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ kan:

  • Ilé ìjọsìn: Láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin àti ìkejì Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn tó kọ Ìwé Márùn-ún Àkọ́kọ́ ti Àwọn Ará Samáríà fi gbólóhùn yìí sí ìparí Ẹ́kísódù 20:17, pé “ní Aargaareezem. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò kọ pẹpẹ sí.” Àwọn ará Samáríà tipa bẹ́ẹ̀ gbà pé èyí máa mú kí Ìwé Mímọ́ ṣètìlẹ́yìn fún bí àwọn ṣe ń kọ́ tẹ́ńpìlì sí “Aargaareezem,” tàbí Òkè Gérísímù.

  • Ẹ̀kọ́ mẹ́talọ́kan: Ní nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún [300] ọdún lẹ́yìn tí wọ́n parí kíkọ Bíbélì, ẹlẹ́kọ̀ọ́ Mẹ́talọ́kan kan fi ọ̀rọ̀ yìí kún 1 Jòhánù 5:7, “ní ọ̀run, Baba, Ọ̀rọ̀, àti Ẹ̀mí Mímọ́: àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí jẹ́ ọ̀kan.” Gbólóhùn yìí kò sí nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀. Onímọ̀ nípa Bíbélì kan tó ń jẹ́ Bruce Metzger sọ pé: “Láti ọgọ́rùn-ún ọdún kẹfà ni ọ̀rọ̀ yìí ti ń fara hàn lemọ́lemọ́ nínú ìwé àfọwọ́kọ àwọn Látìn Àtijọ́ àti ti Vulgate lédè Látìn.”

  • Orúkọ Ọlọ́run: Ọ̀pọ̀ àwọn tó túmọ̀ Bíbélì pinnu láti yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú Ìwé Mímọ́. Ìdí sì ni pé wọ́n fara mọ́ àṣà kan táwọn Júù ń dá. Torí náà, wọ́n yọ orúkọ tí Ẹlẹ́dàá ń jẹ́ gangan kúrò, wọ́n sì fi orúkọ oyè rọ́pò rẹ̀, ìyẹn “Ọlọ́run” tàbí “Olúwa.” Bẹ́ẹ̀ sì rèé, kì í ṣe Ẹlẹ́dàá nìkan ni Bíbélì pè ní orúkọ yẹn, àwọn ibì kan wà tí Bíbélì ti pe àwọn èèyàn, òrìṣà àti Èṣù ní “ọlọ́run.”—Jòhánù 10:34, 35; 1 Kọ́ríńtì 8:5, 6; 2 Kọ́ríńtì 4:4. *

OHUN TÓ JẸ́ KÍ BÍBÉLÌ WÀ DÒNÍ: Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn kan lára àwọn tó ṣe àdàkọ Bíbélì kò ka nǹkan sí, àwọn míì sì jẹ́ ẹlẹ̀tàn. Àmọ́, èyí tó pọ̀ jù lára wọn ló jẹ́ ọ̀jáfáfá, tí wọ́n sì fara balẹ̀ ṣe àdàkọ Bíbélì. Àwọn Másórétì ṣe àdàkọ Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún kẹfà sí ìkẹwàá Sànmánì Kristẹni. Àdàkọ tí wọ́n ṣè yìí la wá mọ̀ sí Ìwé Másórétì. Ìtàn fi hàn pé wọ́n máa ń fara balẹ̀ ka ẹyọ ọ̀rọ̀ àti lẹ́tà, kó lè dá wọn lójú pé kò sí àṣìṣe kankan. Tí wọ́n bá rí ohun kan tó dà bí àṣìṣe nínú èyí tí wọ́n fi ń ṣe àdàkọ, wọ́n á kọ ọ́ sí etí ìwé tí wọ́n ń ṣe lọ́wọ́. Àwọn Másórétì kò yí ọ̀rọ̀ inú Bíbélì pa dà. Ọ̀jọ̀gbọ́n Moshe Goshen-Gottstein sọ pé “Ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jù lọ ni wọ́n kà á sí tẹ́nì kan bá mọ̀ọ́mọ̀ yí ọ̀rọ̀ Bíbélì pa dà lọ́nàkọnà.”

Ìkejì, bí àwọn ìwé àfọwọ́kọ ṣe wà lóríṣiríṣi lónìí ti jẹ́ kó rọrùn fún àwọn ọ̀mọ̀wé tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì láti rí ibi tí àṣìṣe wà. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ọdún ni àwọn aṣáájú ẹ̀sìn fi ń kọ́ àwọn èèyàn pé Bíbélì èdè Látìn táwọn ń lò ni ojúlówó Bíbélì tó bá ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ mu. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi fọ̀rọ̀ tiwọn kún 1 Jòhánù 5:7, bá a ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Àṣìṣe yìí tún wọnú Bíbélì King James Version lédè Gẹ̀ẹ́sì. Àmọ́ àwọn ìwé àfọwọ́kọ míì tí wọ́n ṣàwárí fi hàn pé kò sí ọ̀rọ̀ yẹn nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀. Bruce Metzger sọ pé: “Gbólóhùn tó wà [nínú 1 Jòhánù 5:7] yẹn kò sí nínú gbogbo àwọn ìwé àfọwọ́kọ ayé ìgbàanì míì tí wọ́n rí, àwọn ìwé àfọwọ́kọ bíi (Syriac, Coptic, Armenian, Ethiopic, Arabic, Slavonic), àyàfi nínú ti èdè Látìn nìkan.” Èyí ló mú kí wọ́n yọ gbólóhùn náà kúrò nínú Bíbélì King James Version tí wọ́n tún ṣe àtàwọn Bíbélì míì.

Bíbélì àfọwọ́kọ Chester Beatty P46 tí wọ́n fi òrépèté kọ, ó ti wà láti ọgọ́rùn-ún ọdún kejì Sànmánì Kristẹni

Ǹjẹ́ àwọn ìwé àfọwọ́kọ míì tọ́jọ́ wọn ti pẹ́ fi hàn pé ọ̀rọ̀ Bíbélì kò tíì yí pa dà? Nígbà tí wọ́n rí Àkájọ Ìwé Òkun Òkú lọ́dún 1947, àwọn ọ̀mọ̀wé fi ohun tó wà nínú ìwé Másórétì lédè Hébérù wéra pẹ̀lú èyí tó wà nínú àwọn àkájọ Bíbélì tí wọ́n ti kọ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún kan ṣáájú ìgbà rẹ̀. Ẹnì kan lára àwùjọ tó ṣiṣẹ́ lórí Àkájọ Ìwé Òkun Òkú sọ pé àkájọ ìwé kan péré “fi ẹ̀rí hàn lọ́nà tó ṣe kedere pé àwọn adàwékọ náà kò figbá kan bọ̀kan nínú, wọ́n sì fara balẹ̀ ṣe iṣẹ́ náà. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ó ti lé ní ẹgbẹ̀rún ọdún kan tí wọ́n ti kọ̀ ọ́ kó tó di pé wọ́n ṣe àdàkọ rẹ̀.”

Ilé ìkówèésí Chester Beatty nílùú Dublin, lórílẹ̀-èdè Ireland, pàtẹ àkójọ àwọn òrépèté tó fẹ́rẹ̀ẹ́ ní gbogbo Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì nínú àtàwọn ìwé àfọwọ́kọ míì tó ti wà láti nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún kejì Sànmánì Kristẹni, ìyẹn nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn tí wọ́n parí kíkọ Bíbélì. Ìwé The Anchor Bible Dictionary ṣàlàyé pé: “Àwọn òrépèté yìí ti jẹ́ ká rí àwọn ìsọfúnni tó túbọ̀ ṣe kedere nípa ọ̀rọ̀ inú Bíbélì, ó sì tún ti jẹ́ kó ṣe kedere sí wa pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò yí pa dà.”

“Òótọ́ pọ́ńbélé ni pé kò sí ìwé ayé ìgbàanì tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ péye bíi Bíbélì”

ÀBÁJÁDE RẸ̀: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ àwọn ìwé àfọwọ́kọ wọ̀nyí ti pẹ́ tí wọ́n sì wà lóríṣiríṣi, síbẹ̀ ó ti mú kí ọ̀rọ̀ Bíbélì sunwọ̀n sí i. Sir Frederic Kenyon sọ nípa Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì pé: “Kò sí ìwé ayé ìgbàanì kankan tó ní àwọn ẹ̀rí tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ láti fi ti ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ lẹ́yìn. Àwọn ọ̀mọ̀wé tí kì í ṣe ẹlẹ́tanú sì gbà pé ohun tó wà nínú Bíbélì láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà ló ṣì wà nínú rẹ̀ di báyìí.” Ọ̀mọ̀wé William Henry Green sọ nípa Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù pé: “Òótọ́ pọ́ńbélé ni pé kò sí ìwé ayé ìgbàanì tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ péye bíi Bíbélì.”

^ ìpínrọ̀ 6 Tó o bá fẹ́ àlàyé sí i, wo Àsomọ́ 1 nínú Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ó wà lórí ìkànnì www.mr1310.com/yo.