Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Tí Oríṣiríṣi Bíbélì Fi Wà?

Kí Nìdí Tí Oríṣiríṣi Bíbélì Fi Wà?

Kí nìdí tí oríṣiríṣi ìtumọ̀ Bíbélì fi wà lóde òní? Tó o bá rí ìtumọ̀ Bíbélì tuntun tí wọ́n ṣe jáde, báwo ló ṣe máa ń rí lára rẹ, ṣé ó máa ń jẹ́ kó o lóye Bíbélì ni àbí ó máa ń jẹ́ kó sú ẹ? Tó o bá mọ ibi tí Bíbélì ti wá, ó máa jẹ́ kó o lè fọgbọ́n ṣàyẹ̀wò rẹ̀.

Àmọ́ lákọ̀ọ́kọ́ ná, ta ló kọ Bíbélì, ìgbà wo sì ni wọ́n kọ ọ́?

BÍBÉLÌ ÌPILẸ̀ṢẸ̀

Apá méjì ni wọ́n pín Bíbélì sí. Apá àkọ́kọ́ ní ìwé mọ́kàndínlógójì [39] nínú, tí gbogbo wọn jẹ́ “àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run.” (Róòmù 3:2) Ọlọ́run fi ẹ̀mí darí àwọn ọkùnrin olóòótọ́ láti kọ àwọn ìwé yìí, ó sì gba ọ̀pọ̀ ọdún. Ó tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún [1,100] ọdún tí wọ́n fi kọ ọ́, bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni títí di àkókò kan lẹ́yìn ọdún 443 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Èdè Hébérù ni wọ́n fi kọ ọ̀pọ̀ lára wọn, ìdí nìyẹn tá a fi ń pe apá yìí ní Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, tí wọ́n tún ń pè ní Májẹ̀mú Láéláé.

Ìwé mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27] ló wà nínú apá kejì, “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ló sì jẹ́. (1 Tẹsalóníkà 2:13) Ọlọ́run fi ẹ̀mí rẹ̀ darí àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi láti kọ apá yìí láàárín àkókò kúkúrú, ìyẹn nǹkan bí ọgọ́ta [60] ọdún, bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 41 Sànmánì Kristẹni sí ọdún 98 Sànmánì Kristẹni. Èdè Gíríìkì ni wọ́n fi kọ èyí tó pọ̀ jù, ìdí nìyẹn tá a fi ń pe apá yìí ní Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, tí wọ́n tún ń pè ní Májẹ̀mú Tuntun.

Ìwé mẹ́rìndínláàádọ́rin [66] tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí rẹ̀ darí yìí ló para pọ̀ di odindi Bíbélì, ìyẹn ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run bá wa sọ. Àmọ́ kí nìdí tí wọ́n fi ń ṣe ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì jáde? Mẹ́ta pàtàkì lára àwọn ìdí náà rèé.

  • Káwọn èèyàn lè rí Bíbélì kà ní èdè abínibí wọn.

  • Kí wọ́n lè ṣàtúnṣe sí àwọn àṣìṣe táwọn adàwékọ ti ṣe, kí wọ́n sì dá Bíbélì pa dà sí bó ṣe wà ní ìpilẹ̀ṣẹ̀.

  • Kí wọ́n lè lo àwọn ọ̀rọ̀ tó bágbà mu.

Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn kókó yìí ṣe nípa lórí ìtumọ̀ Bíbélì méjì tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe.

BÍBÉLÌ SEPTUAGINT TI ÈDÈ GÍRÍÌKÌ

Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] ọdún kí Jésù tó wá sáyé, àwọn ọ̀mọ̀wé Júù bẹ̀rẹ̀ sí í túmọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sí èdè míì, ìyẹn èdè Gíríìkì. Ìtumọ̀ yìí ni wọ́n wá mọ̀ sí Bíbélì Septuagint ti Èdè Gíríìkì. Kí nìdí tí wọ́n fi ṣe é? Kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ fún àwọn Júù tó ń sọ èdè Gíríìkì dípò èdè Hébérù, láti máa rí “ìwé mímọ́” kà.​—2 Tímótì 3:15.

Bíbélì Septuagint tún ṣèrànwọ́ fún ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn tí kì í ṣe Júù, tó ń sọ èdè Gíríìkì, láti mọ ohun tí Bíbélì kọ́ni. Lọ́nà wo? Ọ̀jọ̀gbọ́n W.  F. Howard sọ pé: “Láti àárín ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ló ti wá di Bíbélì àwọn Kristẹni. Àwọn míṣọ́nnárì máa ń lọ láti sínágọ́gù kan sí òmíràn kí wọ́n lè ‘fi ẹ̀rí hàn látinú ìwé mímọ́ pé Jésù ni Mèsáyà náà.’ ” (Ìṣe 17:​3, 4; 20:20) Onímọ̀ nípa Bíbélì kan tó ń jẹ́ F. F. Bruce sọ pé: “Èyí jẹ́ ọ̀kan lára ìdí tí ọ̀pọ̀ àwọn Júù kò “fi gba ti Bíbélì Septuagint mọ́.”

Bí Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ṣe ń tẹ àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù lọ́wọ́ ní ṣísẹ̀ntẹ̀lé, wọ́n ń pa á pọ̀ mọ́ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ti ìtumọ̀ Septuagint, òun ló wá para pọ̀ di odindi Bíbélì tá à ń lò báyìí.

BÍBÉLÌ LÁTÌN VULGATE

Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] ọdún lẹ́yìn tí wọ́n parí kíkọ Bíbélì, onímọ̀ nípa ẹ̀sìn kan tó ń jẹ́ Jerome túmọ̀ Bíbélì sí èdè Látìn, ìtumọ̀ yìí la wá mọ̀ sí Látìn Vulgate. Àmọ́, wọ́n ti ṣe ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì sí èdè Látìn tẹ́lẹ̀, kí wá nìdí tí wọ́n fi ní láti ṣe ìtúmọ̀ míì? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà The International Standard Bible Encyclopedia ṣàlàyé pé: Ńṣe ni Jerome fẹ́ ṣàtúnṣe “àwọn àṣìtúmọ̀, àṣìṣe tó hàn gbangba, àtàwọn àfikún àti àyọkúrò tí kò pọn dandan.”

Jerome ṣàtúnṣe àwọn àṣìṣe yẹn. Àmọ́ nígbà tó yá, ṣọ́ọ̀ṣì ṣe àṣìṣe tó burú jù lọ nínú ìtàn! Wọ́n sọ pé ìtumọ̀ Bíbélì Látìn Vulgate nìkan làwọn èèyàn gbọ́dọ̀ máa lò, àṣẹ yẹn sì wà bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún! Dípò tí wọ́n á fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye Bíbélì, ńṣe ni wọ́n sọ Bíbélì Vulgate di ìwé táwọn èèyàn ò lè kà torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò mọ èdè Látìn kà rárá.

ÀWỌN ÌTUMỌ̀ BÍBÉLÌ TUNTUN Ń PỌ̀ SÍ I

Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì, irú bí Bíbélì Syriac Peshitta táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún karùn-ún Sànmánì Kristẹni. Àmọ́ ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìnlá ni wọ́n tó sapá gan-an láti mú káwọn èèyàn lè rí Ìwé Mímọ́ kà ní èdè abínibí wọn.

Nígbà tí ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìnlá ń parí lọ, ọ̀gbẹ́ni John Wycliffe nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, bẹ̀rẹ̀ sí í túmọ̀ Bíbélì sí èdè Gẹ̀ẹ́sì tó jẹ́ èdè táwọn èèyàn ilẹ̀ yẹn mọ̀ dáadáa. Nípa bẹ́ẹ̀ wọ́n bọ́ lọ́wọ́ èdè Látìn tó ti di èdè àtijọ́ táwọn èèyàn ò sọ mọ́. Kò pẹ́ sígbà yẹn tí ọ̀gbẹ́ni Johannes Gutenberg fi mú kí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà tẹ̀wé yára sí i, èyí ló mú kó rọrùn fáwọn onímọ̀ nípa Bíbélì láti ṣe àwọn ìtumọ̀ Bíbélì tuntun jáde lóríṣiríṣi èdè táwọn èèyàn ń sọ nílẹ̀ Yúróòpù, tí wọ́n sì pín in kiri.

Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì, àwọn alátakò ń ṣàròyé pé kò sídìí láti ní ju Bíbélì èdè Gẹ̀ẹ́sì kan ṣoṣo lọ. Àlùfáà ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejìdínlógún tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ John Lewis kọ̀wé pé: “Èdè máa ń yí pa dà, torí náà ó pọn dandan ká máa ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìtumọ̀ Bíbélì tọ́jọ́ wọn ti pẹ́ ká lè ṣàtúnṣe rẹ̀, èyí máa jẹ́ kọ́rọ̀ inú rẹ̀ bóde mu, kó sì yéni.”

Lóde òní, àwọn onímọ̀ nípa Bíbélì máa ń ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìtumọ̀ Bíbélì tọ́jọ́ wọn ti pẹ́. Ìdí ni pé wọ́n ti wá lóye àwọn èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ dáadáa àti pé lẹ́nu àìpẹ́ yìí wọ́n ti rí ọ̀pọ̀ Bíbélì àfọwọ́kọ ayé ìgbàanì tó wúlò gan-an. Èyí ti jẹ́ kí wọ́n lè ṣe ìtumọ̀ tó péye tó sì bá Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ mu dáadáa.

Torí náà, àwọn ìtumọ̀ Bíbélì òde òní wúlò gan-an. Síbẹ̀ náà, ó ṣì yẹ ká ṣọ́ra fún àwọn kan lára wọn o. * Àmọ́ tó bá jẹ́ ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún Ọlọ́run ló mú káwọn tó ṣe àtúnṣe Bíbélì kan ṣe é, á jẹ́ pé ìtumọ̀ Bíbélì tí wọ́n ṣe máa ṣe wá láǹfààní tó pọ̀.

 

^ ìpínrọ̀ 24 Wo àpilẹ̀kọ náà “Báwo Lo Ṣe Lè Mọ Bíbélì Tí Wọ́n Túmọ̀ Lọ́nà Tó Dára?” nínú Ilé Ìṣọ́ May 1, 2008.