Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OHUN TÓ Ń FÚNNI LÁYỌ̀

Ìrètí

Ìrètí

“[Mo ní] àwọn èrò àlàáfíà, kì í ṣe ti ìyọnu àjálù, láti fún yín ní ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan.”​Jeremáyà 29:11.

Ìwé kan tó ń jẹ́ Hope in the Age of Anxiety sọ pé, ‘TÍ ÈÈYÀN BÁ FẸ́ SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN BÓ ṢE YẸ, Ó ṢE PÀTÀKÌ PÉ KÍ ÈÈYÀN NÍ ÌRÈTÍ.’ Ó tún sọ pé “tẹ́nì kan bá ní ìrètí, nǹkan ò ní máa tojú sú u, kò ní máa ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀, kò sì ní máa bẹ̀rù.”

Bíbélì sọ pé ó ṣe pàtàkì pé ká ní ìrètí, àmọ́ ó tún kìlọ̀ fún wa pé ká ṣọ́ra fún ìrètí ẹ̀tàn. Sáàmù 146:3 sọ pé: “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọ̀tọ̀kùlú, tàbí lé ọmọ ará ayé, ẹni tí ìgbàlà kò sí lọ́wọ́ rẹ̀.” Dípò tá a fi máa gbẹ́kẹ̀ lé àwọn èèyàn láti bá wa yanjú àwọn ìṣòro wa, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Ẹlẹ́dàá wa, torí pé òun ló lágbára láti mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Àwọn nǹkan wo ló ṣèlérí fún wa? Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára wọn.

ÌWÀ BURÚKÚ Ò NÍ SÍ MỌ́, ÀWỌN OLÓDODO MÁA WÀ NÍ ÀLÀÁFÍÀ TÍTÍ LÁÉ: Sáàmù 37:​10, 11 sọ pé: “Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́ . . . Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” Ẹsẹ 29 wá fi kún un pé “àwọn olódodo ni yóò . . . máa gbé títí láé” lórí ilẹ̀ ayé.

OGUN KÒ NÍ SÍ MỌ́: “Jèhófà . . . mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé. Ó ṣẹ́ ọrun sí wẹ́wẹ́, ó sì ké ọ̀kọ̀ sí wẹ́wẹ́; ó sun àwọn kẹ̀kẹ́ nínú iná.”​—Sáàmù 46:​8, 9.

KÒ NÍ SÍ ÀÌSÀN, ÌYÀ TÀBÍ IKÚ MỌ́: “Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé . . . Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.”​—Ìṣípayá 21:​3, 4.

Ọ̀PỌ̀ RẸPẸTẸ OÚNJẸ MÁA WÀ FÚN GBOGBO ÈÈYÀN: “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.”​—Sáàmù 72:16.

KRISTI MÁA FI ÒDODO ṢÀKÓSO GBOGBO AYÉ NÍNÚ ÌJỌBA RẸ̀: “A sì fún [Jésù Kristi] ní agbára ìṣàkóso àti iyì àti ìjọba, pé kí gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè àti àwọn èdè máa sin àní òun. Agbára ìṣàkóso rẹ̀ jẹ́ agbára ìṣàkóso tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin tí kì yóò kọjá lọ, ìjọba rẹ̀ sì jẹ́ èyí tí a kì yóò run.”​—Dáníẹ́lì 7:14.

Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé àwọn ìlérí yìí máa ṣẹ? Nígbà tí Jésù wà láyé, ó ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn lóòótọ́ pé òun ni Ọba tí Ọlọ́run yàn. Ó mú àwọn aláìsàn lára dá, ó bọ́ àwọn aláìní, ó tiẹ̀ tún jí òkú dìde. Ohun tó kọ́ àwọn èèyàn ló tiẹ̀ tún wá ṣe pàtàkì jù, torí pé ẹ̀kọ́ yẹn kún fún àwọn ìlànà tó lè jẹ́ kí wọ́n máa bá ara wọn gbé ní ìṣọ̀kan àti àlàáfíà títí ayé. Jésù tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, tó fi mọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó máa fi hàn pé a ti wà ní òpin àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí.

OHUN TÓ LE Ń BỌ̀ WÁ DẸ̀RỌ̀

Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn nǹkan burúkú láá máa ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, kì í ṣe àkókò àlàáfíà àti ààbò. Lára àwọn àmì tó máa fi hàn pé a ti wà ní “ìparí ètò àwọn nǹkan” ni ogun kárí ayé, àìtó oúnjẹ, àjàkálẹ̀ àrùn àti ìmìtìtì ilẹ̀. (Mátíù 24:​3, 7; Lúùkù 21:​10, 11; Ìṣípayá 6:​3-8) Jésù tún sọ pé: “Nítorí pípọ̀ sí i ìwà àìlófin, ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ yóò di tútù.”​—Mátíù 24:12.

Ó hàn kedere pé ìfẹ́ àwọn èèyàn ti di tútù gan-an báyìí. Ọ̀ǹkọ̀wé Bíbélì míì tún sọ ní 2 Tímótì 3:​1-5, pé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ọ̀pọ̀ èèyàn máa jẹ́ onímọ̀tara-ẹ̀ni-nìkan, wọ́n á sì nífẹ̀ẹ́ owó àti fàájì. Wọ́n á jẹ́ agbéraga àti òǹrorò. Àwọn ìdílé ò ní máa fi ìfẹ́ hàn sí ara wọn, àwọn ọmọ ò sì ní gbọ́ tàwọn òbí wọn. Ẹ̀sìn á sì kún fún àgàbàgebè lóríṣiríṣi.

Bí nǹkan ṣe le koko lákòókò yìí fi hàn pé àwọn ọjọ́ ìkẹ̀yìn ayé la wà yìí. Ó tún jẹ́ ẹ̀rí pé Ìjọba Ọlọ́run ò ní pẹ́ dé mọ́, tí gbogbo nǹkan tó le á sì wá dẹ̀rọ̀. Jésù tiẹ̀ sọ àsọtélẹ̀ kan tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn tá a wà yìí, ó ní: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”​—Mátíù 24:14.

Ìhìn rere yẹn ń kìlọ̀ fún àwọn tó ń hùwà burúkú pé kí wọ́n yí pa dà, ó sì ń fún àwọn olódodo ní ìrètí pé, láìpẹ́ gbogbo ìbùkún tí Ọlọ́run ṣèlérí máa ní ìmúṣẹ. Ṣó o fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn ìbùkún yẹn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, jọ̀wọ́ lọ sí ojú ìwé tó gbẹ̀yìn nínú ìwé yìí.