Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀kọ́ Tó Ń Jẹ́ Ká Sún Mọ́ Ọlọ́run

Ẹ̀kọ́ Tó Ń Jẹ́ Ká Sún Mọ́ Ọlọ́run

Yàtọ̀ sí pé Ẹlẹ́dàá wa ló lágbára jù láyé àti lọ́run, ó tún láwọn ìwà àti ìṣe tó fani mọ́ra gan-an. Ó fẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa òun, ká sì di ọ̀rẹ́ òun. (Jòhánù 17:3; Jémíìsì 4:8) Torí náà, ó sọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa ara rẹ̀ fún wa.

Ẹlẹ́dàá Wa Ní Orúkọ

“Kí àwọn èèyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ayé.”​—SÁÀMÙ 83:18.

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà. Òun ló dá ayé àtọ̀run àti gbogbo ohun alààyè tó wà nínú wọn. Òun nìkan ṣoṣo la gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn.​—Ìfihàn 4:11.

Ọlọ́run Onífẹ̀ẹ́ Ni Jèhófà

“Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.”​—1 JÒHÁNÙ 4:8.

Nínú Bíbélì, Jèhófà jẹ́ ká mọ àwọn ìwà àti ìṣe tí òun ní. Bákan náà, tá a bá ń kíyè sí àwọn ohun tí Ọlọ́run dá, a máa túbọ̀ mọ àwọn ìwà àti ìṣe rẹ̀. Ìfẹ́ ló gbawájú nínú àwọn ìwà àti ìṣe Jèhófà. Ìfẹ́ yìí ló ń mú kí Jèhófà ṣe gbogbo ohun tó ń ṣe. Bá a bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà sí i, bẹ́ẹ̀ làá ṣe túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ sí i.

Jèhófà Máa Ń Dárí Jini

“Ọlọ́run tó ṣe tán láti dárí jini ni ọ́.”​—NEHEMÁYÀ 9:17.

Jèhófà mọ̀ pé aláìpé ni wá. Torí náà, ‘ó ṣe tán láti dárí jì wá.’ Tá a bá bẹ Jèhófà pé kó dárí jì wá, tá a sì sapá gan-an ká lè jáwọ́ nínú ohun tí ò dáa tá à ń ṣe, ó máa dárí jì wá, kò sì ní fìyà ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti dá tẹ́lẹ̀ jẹ wá.​—Sáàmù 103:​12, 13.

Jèhófà Máa Ń Gbọ́ Àdúrà Wa

“Jèhófà wà nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é . . . Ó ń gbọ́ igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́.”​—SÁÀMÙ 145:18, 19.

Jèhófà ò sọ pé ó dìgbà tá a bá ṣàwọn ayẹyẹ tàbí ètùtù kan ká tó lè jọ́sìn òun, kò sì ní ká máa lo ère nínú ìjọsìn òun. Ó máa ń tẹ́tí sí àdúrà wa bí ìgbà tí òbí kan ń tẹ́tí sí àwọn ọmọ rẹ̀.