Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ bí àwakọ̀ òfuurufú àti ẹnì kejì rẹ̀ ṣe máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ kí wọ́n lè gúnlẹ̀ láyọ̀

TỌKỌTAYA

2: Ìfọwọ́sowọ́pọ̀

2: Ìfọwọ́sowọ́pọ̀

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ

Ó túmọ̀ sí kí tọkọtaya jọ máa ṣe gbogbo nǹkan pọ̀, bí awakọ̀ òfuurufú àti ẹnì kejì rẹ̀ ṣe ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ kí wọ́n lè gúnlẹ̀ láyọ̀. Bí ìṣòro bá tiẹ̀ dé, kò sẹ́nì kankan nínú wọn táá máa ro ti ara rẹ̀ nìkan.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Wọn kì í ṣe méjì mọ́, bí kò ṣe ara kan.”​—Mátíù 19:6.

“Àgbájọ ọwọ́ la fi ń sọ̀yà. Torí náà, tọkọtaya gbọ́dọ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ kí ìgbéyàwó wọn lè yọrí sí rere.”​—Christopher.

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ

Tí tọkọtaya ò bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀, tí ìṣòro bá dé, ńṣe ni ẹnì kìíní á máa dá ẹnì kejì lẹ́bi dípò kí wọ́n yanjú ìṣòro tó wà nílẹ̀. Wọ́n á wá sọ ọ̀rọ̀ tí kò tó nǹkan di ńlá.

“Ìfọwọ́sọwọ́pọ̀ ni okùn ẹ̀mí ìgbéyàwó. Tí èmi àti ọkọ mi ò bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀, ńṣe la máa dà bí àwọn méjì tó kàn ń gbé pọ̀. Èyí sì máa ń fa ìṣòro, pàápàá tó bá di pé ká ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì.” ​—Alexandra.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

DÁN ARA RẸ WÒ

  • Ṣé mo máa ń sọ pé “èmi nìkan ni mo ni gbogbo owó tó ń wọlé fún mi”?

  • Ṣé ó máa ń ṣe mí bíi pé ìgbà tí ẹnì kejì mi ò bá sí nílé nìkan ni mo máa ń lè sinmi dáadáa?

  • Ṣé mo nífẹ̀ẹ́ àwọn mọ̀lẹ́bí ẹnì kejì mi bí òun náà ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn?

Ẹ BÁ ARA YÍN SỌ̀RỌ̀

  • Àwọn nǹkan wo la jọ máa ń ṣe tó fi hàn pé a fọwọ́ sowọ́ pọ̀?

  • Ibo ló yẹ ká ti sunwọ̀n sí i?

  • Kí ni àwọn nǹkan tá a lè jọ máa ṣe táá mú ká túbọ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀?

ÀBÁ

  • Fojú inú wò ó pé ẹ̀yin méjéèjì ń gbá bọ́ọ̀lù, ojú ilé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lẹ̀yin méjèèjì sì wà. Wá ronú nípa àwọn nǹkan tó o lè ṣe kẹ́ ẹ lè jọ wà ní ojú ilé kan náà.

  • Kàkà kó o máa ronú pé ‘Báwo ni mo ṣe lè borí?’ bi ara rẹ pé ‘Báwo ni àwa méjèèjì ṣe lè borí?’

“Gbàgbé nípa ẹni tó jàre tàbí ẹni tó jẹ̀bi. Ìyẹn kọ́ ló ṣe pàtàkì, bí kò ṣe pé kí àláàfíà àti ìṣọ̀kan wà nínú ìgbéyàwó yín.”​—Ethan.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: ‘Ẹ má ṣe máa wá ire ara yín nìkan, ṣùgbọ́n ire àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.’​—Fílípì 2:​3, 4.