Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JÍ! No. 3 2021 | Ẹ̀rí Wo Ló Fi Hàn Pé Ẹlẹ́dàá Wà?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé Ẹlẹ́dàá kan wà tó dá ayé àtàwọn nǹkan tó wà nínú ẹ̀, àmọ́ ohun táwọn kan sọ ni pé kò sí Ẹlẹ́dàá kan níbì kan. Tó o bá ka ìwé yìí, wàá rí àwọn ohun tó gbàfiyèsí tó sì ń múni ronú jinlẹ̀ gan-an lórí ọ̀rọ̀ yìí, wàá sì lè mọ̀ bóyá Ẹlẹ́dàá wà lóòótọ́ àbí kò sí. Ṣé ayé àtọ̀run àtàwọn ohun tó wà níbẹ̀ ṣàdédé wà ni àbí iṣẹ́ ọwọ́ Ẹlẹ́dàá kan ni? Ó ṣe pàtàkì gan-an pé kó o mọ ìdáhùn ìbéèrè yìí.

 

Kí Lèrò Tìẹ?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣe kàyéfì nípa bí ayé àtàwọn ohun tó wà nínú ẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀.

Ohun Tí Ayé Àtàwọn Nǹkan Tó Wà Lójú Ọ̀run Jẹ́ Ká Mọ̀

Tó bá jẹ́ pé bí ayé àtàwọn ohun tó wà lójú ọ̀run yìí ṣe rí ló mú káwọn ohun abẹ̀mí lè gbé ayé, ṣé kò bọ́gbọ́n mu láti gbà pé ẹnì kan ló dìídì ṣètò wọn lọ́nà yẹn?

Ohun Táwọn Ohun Alààyè Jẹ́ Ká Mọ̀

Àwọn ohun alààyè mú kí ayé yìí rẹwà gan-⁠an kó sì ṣàrà ọ̀tọ̀. Ṣé ẹnì kan ló dá wọn ni àbí wọ́n kàn ṣàdédé wà?

Àwọn Nǹkan Táwọn Onímọ̀ Sáyẹ́ǹsì Ò Lè Ṣàlàyé

Ṣé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lè ṣàlàyé bí ayé àti ọ̀run ṣe bẹ̀rẹ̀?

Kí Ni Bíbélì Jẹ́ Ká Mọ̀?

Ṣe ohun tí Bíbélì sọ àti ohun táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ bára mu?

Ìdí Tó Fi Yẹ Kó O Mọ̀ Bóyá Ẹlẹ́dàá Wà

Tó o bá gbà pé Ẹlẹ́dàá wà, wàá rí ọ̀pọ̀ àǹfààní ní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú.

Ṣé Ẹlẹ́dàá Wà Lóòótọ́?

Ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Ẹlẹ́dàá wà lóòótọ́.