Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wàá Jàǹfààní Tó O Bá Mọ̀ Pé Ọlọ́run Bìkítà Nípa Rẹ

Wàá Jàǹfààní Tó O Bá Mọ̀ Pé Ọlọ́run Bìkítà Nípa Rẹ

Ọlọ́run dá ara wa lọ́nà àrà tó fi jẹ́ pé ó lè wo ara rẹ̀ sàn. Tí ara èèyàn bá bó, tàbí tí nǹkan bá gún èèyàn lára, “ńṣe ni oríṣiríṣi iṣẹ́ máa bẹ̀rẹ̀ nínú àgọ́ ara wa, tó máa mú kí egbò náà jinná, ì báà jẹ́ ńlá tàbí kékeré.” [Johns Hopkins Medicine] Kíá ni ara ti máa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láti mú kí ẹ̀jẹ̀ dá, egbò náà á bẹ̀rẹ̀ sí í jinná, ẹran á sì bẹ̀rẹ̀ sí í bo ojú egbò náà.

RÒ Ó WÒ NÁ: Tí Ẹlẹ́dàá wa bá lè dá ara wa lọ́nà tó fi lè wo ara rẹ̀ sàn, ṣé kò yẹ kí ọkàn wa balẹ̀ pé ó máa mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé òun máa wo ẹ̀dùn ọkàn wa sàn? Onísáàmù náà kọ̀wé pé: “Ó ń mú àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn lára dá, ó sì ń di àwọn ojú ibi tí ń ro wọ́n.” (Sáàmù 147:3) Àmọ́, tó o bá ní ẹ̀dùn ọkàn tàbí ìdààmú ọkàn tó lágbára, báwo ló ṣe lè dá ẹ lójú pé Jèhófà máa di àwọn ojú ibi tó ń ro ẹ́ ní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú?

OHUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ́ WA NÍPA ÌFẸ́ ỌLỌ́RUN

Ọlọ́run ṣe ìlérí pé: “Má fòyà, nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ. Má wò yí ká, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Dájúdájú, èmi yóò fi okun fún ọ. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́.” (Áísáyà 41:10) Tí ẹnì kan bá mọ̀ pé Jèhófà bìkítà nípa òun, ọkàn onítọ̀hún á balẹ̀, á sì lè kojú onírúurú àdánwò. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pe irú ìbàlẹ̀ ọkàn yìí ní “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.” Pọ́ọ̀lù tún fi kún un pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.”​—Fílípì 4:4-7, 9, 13.

Ìwé Mímọ́ ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára nínú àwọn ìlérí Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, Ìṣípayá 21:4, 5 sọ ohun tí Ọlọ́run máa ṣe àti ìdí tó fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé e:

  • “Yóò sì nu omijé gbogbo” kúrò lójú àwọn èèyàn. Jèhófà máa mú gbogbo ìyà àti ìdààmú ọkàn tó ń bá wa fínra kúrò, tó fi mọ́ àwọn ìṣòro kan tó dà bíi pé kò tó nǹkan lójú àwọn míì.

  • Olódùmarè Ọba àti Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo “jókòó lórí ìtẹ́” nínú ògo lọ́run, ó máa lo agbára àti àṣẹ rẹ̀ láti mú ìyà tó ń jẹ wá kúrò, ó sì máa ràn wá lọ́wọ́.

  • Jèhófà fi dá wa lójú pé àwọn ìlérí òun “ṣeé gbíyè lé, wọ́n sì jẹ́ òótọ́.” Ìyẹn ni pé nítorí pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tòótọ́, ó máa mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ dájúdájú.

“‘Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ sì wí pé: “Wò ó! Mo ń sọ ohun gbogbo di tuntun.” Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó wí pé: “Kọ̀wé rẹ̀, nítorí pé ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣeé gbíyè lé, wọ́n sì jẹ́ òótọ́.’”​—Ìṣípayá 21:4, 5.

Àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá sáyé àti Bíbélì jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Baba wa ọ̀run jẹ́. Láìsọ̀rọ̀, àwọn ìṣẹ̀dá ń jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́, ó tún jẹ́ ká rí i pé a lè sún mọ́ ọn bí ọ̀rẹ́ kòríkòsùn, àmọ́ ńṣe ni Bíbélì ń rọ̀ wá ní tààràtà pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” (Jákọ́bù 4:8) Ìṣe 17:27 sọ pé: “Kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.”

Bó o bá ṣe túbọ̀ ń mọ Ọlọ́run tó, bẹ́ẹ̀ láá ṣe máa dá ẹ́ lójú sí i pé ‘ó bìkítà fún ẹ.’ (1 Pétérù 5:7) Àwọn àǹfààní wo lo máa rí tó o bá gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run?

Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Toru lórílẹ̀-èdè Japan. Ìyá rẹ̀ tó jẹ́ Kristẹni ló tọ́ ọ dàgbà, àmọ́ ó wọnú ẹgbẹ́ burúkú kan tí wọ́n ń pè ní yakuza. Ó sọ pé: “Mo gbà pé Ọlọ́run kórìíra mi àti pé ńṣe ló ń fi ikú àwọn èèyàn mi jẹ mí níyà.” Toru sọ pé àwọn nǹkan burúkú tí òun ń fojú rí àti bí nǹkan ṣe rí lára òun ló sọ òun di “òǹrorò àti ìkà ẹ̀dá.” Ó sọ ohun tó gbà á lọ́kàn nígbà yen, ó ní: “Mo fẹ́ pa ẹnì kan tó lókìkí jù mí lọ, kí èmi náà sì wá kú ní rèwerèwe lẹ́yìn náà, èyí á mú kí òkìkí mi kàn káàkiri ayé.”

Àmọ́ nígbà tó yá, Toru àti Hannah ìyàwó rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìgbé ayé rẹ̀ yí pa dà sí rere, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ronú lọ́nà tó tọ́. Hannah sọ pé: “Níṣojú mi báyìí ni ọkọ mi yí pa dà.” Ní báyìí, Toru fi ìdánilójú sọ pé: “Ọlọ́run kan wà tó bìkítà nípa ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lóòótọ́. Kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni kú, ó sì ṣe tán láti dárí ji àwọn tó bá ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ó máa ń tẹ́tí sí àwọn ọ̀rọ̀ tá ò lè bá ẹlòmíì sọ àfi òun nìkan, òun nìkan sì ni ọ̀rọ̀ wa yé jù lọ. Láìpẹ́, Jèhófà máa mú gbogbo ìṣòro, ìyà àti ìrora kúrò. Kódà ní báyìí, ó máa ń ràn wá lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà tá ò tiẹ̀ lè ronú kàn. Ó máa ń bójú tó wa, nígbà tá a bá sorí kọ́.”​—Sáàmù 136:23.

Ìtàn Toru fi hàn pé tí èèyàn bá mọ̀ pé Ọlọ́run lè mú gbogbo àjálù kúrò tó sì lè nu omijé kúrò lójú ẹni, èyí máa ń fini lọ́kàn balẹ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dára, ó tún lè mú kí èèyàn máa gbé ìgbé ayé tó dára ní báyìí. Ó dájú pé nínú ayé tí wàhálà àti ìdààmú kún inú rẹ̀ yìí, o ṣì lè ní ìfọ̀kànbalẹ̀ torí pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ rẹ, ó sì bìkítà nípa rẹ.