Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

1 Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Gbàdúrà?

1 Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Gbàdúrà?

1 Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Gbàdúrà?

ÀDÚRÀ. Àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì kan wà táwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí gan-an, wọ́n sì máa ń fẹ́ mọ̀ nípa rẹ̀. Ṣàgbéyẹ̀wò ìbéèrè méje táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè nípa àdúrà, kó o sì máa fọkàn bá wa nìṣó bá a ṣe ń wá ìdáhùn sí wọn látinú Bíbélì. A kọ àwọn àpilẹ̀kọ yìí kó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ bó o ṣe lè gbàdúrà tàbí bí àdúrà rẹ ṣe lè sunwọ̀n sí i.

KÒ SÍ inú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àti ìsìn tí àwọn èèyàn kì í ti í gbàdúrà. Àwọn èèyàn máa ń dá gbàdúrà wọ́n sì tún máa ń gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí àwùjọ. Wọ́n máa ń gbàdúrà nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì, tẹ́ńpìlì, sínágọ́gù, mọ́ṣáláṣí àti ní ojúbọ. Wọ́n lè tẹ́ ohun kan sílẹ̀ láti máa gbàdúrà lórí rẹ̀, wọ́n lè lo ìlẹ̀kẹ̀ àdúrà, àgbá àdúrà, ère, ìwé àdúrà tàbí ohun kan tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ sí tí wọ́n gbé kọ́.

Àdúrà táwa èèyàn máa ń gbà ló mú ká yàtọ̀ sáwọn ẹ̀dá yòókù lórí ilẹ̀ ayé. Òótọ́ ni pé, kò fi bẹ́ẹ̀ sí ìyàtọ̀ láàárín àwa àtàwọn ẹranko. Àwa èèyàn nílò oúnjẹ, afẹ́fẹ́ àti omi bíi tàwọn ẹranko. Bákan náà, wọ́n bí wa, a wà láàyè, a sì ń kú bíi tiwọn. (Oníwàásù 3:19) Àmọ́ àwa ẹ̀dá èèyàn nìkan la máa ń gbàdúrà. Kí nìdí?

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé nítorí pé a ní láti gbàdúrà. Ó ṣe tán gbogbo èèyàn ló gbà pé àdúrà jẹ́ ọ̀nà tá a máa ń gbà bá ẹni mímọ́ àti ẹni tó ti wà láti ayérayé sọ̀rọ̀. Bíbélì sì jẹ́ ká mọ̀ pé, Ọlọ́run ti dá èèyàn pẹ̀lú ìfẹ́ láti gbàdúrà. (Oníwàásù 3:11) Jésù sọ nígbà kan pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.”—Mátíù 5:3.

Èèyàn lè sọ pé, nítorí ‘àìní nípa ti ẹ̀mí’ yìí làwọn ẹlẹ́sìn fi kọ́ àwọn ilé ìsìn ńláńlá tí wọ́n sì ṣe ọ̀ṣọ́ sí wọn, èyí ló tún mú kí wọ́n máa fi ọ̀pọ̀ wákàtí gbàdúrà. Èrò àwọn kan ni pé àwọn fúnra àwọn tàbí àwọn míì ló máa bójú tó àìní àwọn nípa tẹ̀mí. Àmọ́, ǹjẹ́ o mọ̀ pé agbára èèyàn kò gbé e láti ranni lọ́wọ́ lórí ọ̀ràn yìí? Aláìlera làwa èèyàn, a kì í pẹ́ láyé, a kò sì mọ ọ̀la. Ẹnì kan tó lọ́gbọ́n jù wá lọ, tó lágbára jù wá lọ, ẹni tó ti wà láti ayérayé ló lè fún wa lóun tá a nílò. Kí sì làwọn nǹkan tẹ̀mí tá a nílò, tó ń mú ká máa gbàdúrà?

Gbé èyí yẹ̀ wò: Ǹjẹ́ ìgbà kankan wà tó o nílò ìtọ́sọ́nà, ọgbọ́n tàbí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tó ju òye ẹ̀dá èèyàn lọ? Ǹjẹ́ ìgbà kan wà rí tó o nílò ìtùnú nítorí àdánù kan, tó o nílò ìtọ́sọ́nà nígbà tó o fẹ́ ṣe ìpinnu kan tó lágbára tàbí tó o nílò ìdáríjì nígbà tí ìbànújẹ́ bá ẹ nítorí àṣìṣe rẹ?

Bíbélì sọ pé ìwọ̀nyí jẹ́ ìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà. Bíbélì ni ìwé tó ṣeé gbára lé jù lọ tó sọ̀rọ̀ lórí kókó yìí, àkọsílẹ̀ àdúrà àwọn olóòótọ́ lọ́kùnrin lóbìnrin sì wà nínú rẹ̀. Wọ́n gbàdúrà fún ìtùnú, ìtọ́sọ́nà, ìdáríjì àti ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tó le gan-an.—Sáàmù 23:3; 71:21; Dáníẹ́lì 9:4, 5, 19; Hábákúkù 1:3.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àdúrà yìí yàtọ̀, wọ́n fi nǹkan kan jọra. Àwọn tó gbàdúrà ń ṣe ohun tó yẹ kéèyàn ṣe kí àdúrà ẹni lè ní ìtẹ́wọ́gbà, èyí táwọn èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ tẹ̀ lé tàbí kà sí lóde òní. Wọ́n mọ ẹni tó yẹ kí wọ́n gbàdúrà sí.