Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Mímọ́, Mímọ́, Mímọ́ Ni Jèhófà”

“Mímọ́, Mímọ́, Mímọ́ Ni Jèhófà”

Sún Mọ́ Ọlọ́run

“Mímọ́, Mímọ́, Mímọ́ Ni Jèhófà”

TÍ O bá fẹ́ fi ọ̀rọ̀ kan ṣàpèjúwe ẹni tí Jèhófà Ọlọ́run jẹ́, ọ̀rọ̀ wo lo máa lò? Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni, wòlíì Aísáyà rí ìran kan nínú èyí tó ti gbọ́ ohùn àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n ń yin Jèhófà pé ó jẹ́ ẹni mímọ́, ìyẹn sì jẹ́ ọ̀rọ̀ tó fi irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ gan-an hàn. Ó yẹ kí ohun tí Aísáyà rí àti ohun tó gbọ́ mú ká ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Jèhófà, ó sì yẹ kó mú ká sún mọ́ ọn. Bí a ṣe ń ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Aísáyà 6:1-3, máa fojú inú wò ó pé o wà níbẹ̀.

Kí ni Aísáyà rí? Ó sọ pé: “Mo . . . rí Jèhófà, tí ó jókòó lórí ìtẹ́ tí ó ga fíofío, tí a sì gbé sókè.” (Ẹsẹ 1) Kì í ṣe pé Aísáyà rí Jèhófà Olúwa ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run gangan. Nítorí pé, ojú èèyàn kò lè rí àwọn tó ń gbé ní ọ̀run. Bíbélì sọ ní kedere pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó ti rí Ọlọ́run nígbà kankan rí.” (Jòhánù 1:18) Ìran ni ohun tí Aísáyà rí. * Àmọ́, ìran náà ṣe kedere débi pé, ó ya Aísáyà lẹ́nu, ńṣe ló ṣe Aísáyà bíi pé Jèhófà ló rí.

Lẹ́yìn náà, Aísáyà láǹfààní láti rí ohun kan tó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun nìkan ló tíì rí irú rẹ̀ rí nínú ìran. Ó sọ pé: “Àwọn séráfù dúró lókè [Jèhófà]. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ìyẹ́ apá mẹ́fà. Méjì ni ó fi ń bo ojú rẹ̀, méjì sì ni ó fi ń bo ẹsẹ̀ rẹ̀, méjì sì ni ó fi ń fò káàkiri.” (Ẹsẹ 2) Àwọn séráfù jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí tí ipò wọn ga gan-an. Aísáyà nìkan ló sọ̀rọ̀ nípa wọn nínú gbogbo àwọn tó kọ Bíbélì. Gbogbo ìgbà làwọn Séráfù ṣe tán láti lọ sí ibikíbi tí Jèhófà bá rán wọn àti láti ṣe ohunkóhun tó fẹ́ kí wọ́n ṣe. Wọ́n bo ojú wọn àti ẹsẹ̀ wọn, láti fi ọ̀wọ̀ àti ìrẹ̀lẹ̀ hàn fún Ẹni tí wọ́n láǹfààní láti dúró níwájú rẹ̀.

Yàtọ̀ sí pé ohun tí Aísáyà dẹ́rù bà á, ohun tó gbọ́ tún bà á lẹ́rù. Àwọn séráfù yìí pa ohùn wọn pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ akọrin ọ̀run láti kọrin. Aísáyà sọ pé: “Ẹni tibí sì ń ké sí ẹni tọ̀hún pé: ‘Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.’” (Ẹsẹ 3) Ọ̀rọ̀ Hébérù tá a túmọ̀ sí “mímọ́” ní ìtumọ̀ pé ohun kan mọ́ nigín-nigín tàbí pé ó mọ́ gaara. Ọ̀rọ̀ náà tún kan pé, “ohun kan kò ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan.” Nínú orin tó jọ pé wọ́n ń kọ ní àkọgbà, àwọn séráfù náà mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ náà “mímọ́” ní ìgbà mẹ́ta, wọ́n ń tẹnu mọ́ ọn pé Jèhófà jẹ́ mímọ́ látòkèdélẹ̀. (Ìṣípayá 4:8) Nítorí náà, ìjẹ́mímọ́ jẹ́ apá tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú ìwà Jèhófà. Látòkèdélẹ̀, Jèhófà mọ́ nigín-nigín, ó mọ́ gaara, kò sì ní ẹ̀bi kankan.

Mímọ̀ tí a mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ mímọ́ yẹ kó mú ká sún mọ́ ọn. Kí nìdí? Láìdà bí àwọn alákòóso èèyàn tí wọ́n lè dìdàkudà, Jèhófà kò ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan. Ìjẹ́mímọ́ rẹ̀ fi dá wa lójú pé títí láé ni yóò máa jẹ́ Bàbá tí kò lábùkù, Olùṣàkóso tó jẹ́ olóòótọ́ àti Onídàájọ́ tí kì í ṣe ojúsàájú. A ní ìdánilójú pé, Ọlọ́run tó jẹ́ ẹni mímọ́ kò ní já wa kulẹ̀ láé.

Bíbélì kíkà tá a dábàá fún December:

Aísáyà 1-23

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Ìwé Insight on the Scriptures ṣàlàyé pé: “Bí Ọlọ́run bá fi ìran han ẹnì kan lákòókò tí ẹni náà wà lójúfò, ńṣe ló máa ń dà bíi pé, wọ́n yàwòrán ìran náà sọ́kàn onítọ̀hún. Ẹni náà lè rántí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó bá yá, ó sì lè ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ tàbí kó fi ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ ṣàkọsílẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ náà.”—Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 26]

Mímọ̀ tá a mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ mímọ́ yẹ kó mú ká sún mọ́ ọn