Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN

“Jèhófà Dárí Jì Yín Fàlàlà”

“Jèhófà Dárí Jì Yín Fàlàlà”

Òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà Edward Herbert tó gbé láyé ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún mẹ́rin sẹ́yìn sọ pé: “Ẹni tí kì í dárí ji àwọn ẹlòmíì ti dí ọ̀nà tó yẹ kí òun fúnra rẹ̀ gbà.” Ọ̀rọ̀ yẹn sọ ìdí tó fi yẹ ká máa dárí ji àwọn èèyàn, torí bó pẹ́ bó yá, àwa náà lè fẹ́ kí àwọn èèyàn dárí jì wá. (Mátíù 7:12) Àmọ́, ìdí pàtàkì míì tún wà tó fi yẹ ká máa dárí jini. Wo ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nínú Kólósè 3:13.—Kà a.

Torí a jẹ́ aláìpé, a máa ń ṣe ohun tó lè bí àwọn míì nínú nígbà míì, àwọn náà sì lè ṣe bẹ́ẹ̀ sí wa. (Róòmù 3:23) Àmọ́ bí gbogbo wa bá tiẹ̀ jẹ́ aláìpé, kí la lè ṣe kí àlàáfíà lè jọba láàárín àwa àtàwọn èèyàn? Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá pé ká jẹ́ ẹni tó máa ń rí ara gba nǹkan sí, ká sì máa dárí jini. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] ọdún ni wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ yẹn sílẹ̀, ó ṣì wúlò fún wa lónìí bó ṣe wúlò fún wọn nígbà yẹn. Jẹ́ ká fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ.

“Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” Ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí kéèyàn rí ara gba nǹkan sí tàbí ká ní àmúmọ́ra. Ìwé kan tí a ṣèwádìí nínú rẹ̀ fi hàn pé Kristẹni tó bá nírú ìwà yìí “máa ń ṣe tán láti fara da àwọn ìwà kan tí kò dáa táwọn ẹlòmíì ní.” Ọ̀rọ̀ náà “lẹ́nì kìíní-kejì” jẹ́ ká mọ̀ pé ńṣe ló yẹ kí gbogbo wa jọ máa ní sùúrù fún ara wa. Ìyẹn ni pé, tí àwa fúnra wa bá ń rántí pé a ní àwọn ìwà kan tó lè máa bí àwọn míì nínú, a kò ní jẹ́ kí ohun tí a kò nífẹ̀ẹ́ sí nínú ìwà wọn dá wàhálà sílẹ̀ láàárín àwa àti wọn. Tó bá jẹ́ pé àwọn ẹlòmíì ló ṣẹ̀ wá ńkọ́?

“Ẹ máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì.” Gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀wé kan ṣe sọ, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí ‘dárí jini fàlàlà’ “kì í ṣe ọ̀rọ̀ kan náà tí a sábà máa ń lò fún gbójú fo ẹ̀ṣẹ̀ dá tàbí dárí jini . . . àmọ́ ó tún tẹ̀wọ̀n ju ìyẹn lọ̀, ó gba pé ká dárí jini tọkàntọkàn.” Ìwé ìwádìí míì sọ pé, ọ̀rọ̀ yìí lè túmọ̀ sí “ká ṣe nǹkan tó máa múnú ẹlòmíì dùn, ká ṣe èèyàn lóore tàbí ṣe wọ́n láǹfààní.” Tá a bá fẹ́ fi hàn pé a yọ́nú sí ẹnì kan, àá dárí jì í kódà bí a bá tiẹ̀ ní ẹ̀sùn lòdì sí i. Àmọ́, kí nìdí tó fi yẹ ká máa dárí ji àwọn èèyàn lọ́nà yìí? Ìdí ni pé ó lè máà pẹ́ tí àwa náà á fi ṣe ohun tó lè dun ẹlòmíì tí àá sì fẹ́ kí òun náà dárí jì wá.

“Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe.” Ìdí tó ṣe pàtàkì jù lọ tó fi yẹ ká máa dárí ji àwọn èèyàn fàlàlà ni pé, Ọlọ́run máa ń dárí jì wá fàlàlà. (Míkà 7:18) Tiẹ̀ ronú nípa oore ńlá tí Jèhófà ń ṣe fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà ná. Jèhófà kì í dẹ́ṣẹ̀, torí náà kò nílò ìdáríjì látọ̀dọ̀ àwa ẹlẹ́ṣẹ̀. Síbẹ̀, ó máa ń mọ̀ọ́mọ̀ dárí ji àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, Jèhófà ló ta yọ jù lọ tó bá kan ti ká dárí ji àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà!

Jèhófà ló ta yọ̀ jù lọ tó bá kan ti ká dárí ji àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà!

Torí pé Jèhófà jẹ́ aláàánú, ìyẹn máa ń mú ká fẹ́ sún mọ́ ọn, ká sì máa fara wé e. (Éfésù 4:32–5:1) Á dáa ká bi ara wa pé, ‘níwọ̀n bí Jèhófà ti ń dárí jì mí fàlàlà, tí àwọn èèyàn aláìpé bíi tèmi bá ṣẹ̀ mí, tí wọ́n sì tọrọ àforíjì, Ṣó wá yẹ kí n kọ̀ láti dárí jì wọ́n?’—Lúùkù 17:3, 4.