Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | OJÚ TÍ ỌLỌ́RUN FI Ń WO SÌGÁ MÍMU

Ojú Wo ni Ọlọ́run fi Ń Wo Sìgá Mímu?

Ojú Wo ni Ọlọ́run fi Ń Wo Sìgá Mímu?

Naoko, tá a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú sọ ohun tó jẹ́ kó jáwọ́ nínú sìgá mímu, ó ní: “Ohun tí mo kọ́ nípa àwọn ànímọ́ Ọlọ́run nínú Bíbélì àti ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe ló mú kí n yí ìgbésí ayé mi pa dà.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kò sọ̀rọ̀ nípa sìgá, síbẹ̀ ó jẹ́ ká mọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo sìgá mímu. * Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti jáwọ́ nínú àṣà náà nítorí ohun tí wọ́n kọ́ nínú Bíbélì. (2 Tímótì 3:16, 17) Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àkóbá mẹ́ta táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa tí sìgá ń ṣe àti ohun tí Bíbélì sọ nípa wọn.

SÌGÁ MÍMU MÁA Ń DI BÁRAKÚ

Èròjà olóró kán wà nínú tábà tí wọ́n ń pè ní nicotine. Èyí ló máa ń mú kó ṣòro láti jáwọ́ nínú sìgá mímu. Èròjà yìí máa ń ṣiṣẹ́ bí oògùn amóríyá tàbí kó pani lọ́bọ̀ọ́lọ̀. Ìwádìí fi hàn pé sìgá mímu máa ń tú èròjà nicotine sínú ọpọlọ léraléra. Torí náà, téèyàn bá fa ọwọ́ sìgá kan péré, ńṣe ni gàásì nicotine yìí á kàn máa wọnú agbárí rẹ̀ lọ tààràtà, abájọ ó fi jẹ́ pé, ẹni tó ń mu páálí sìgá kan lóòjọ́ ń fa nǹkan bí igba [200] gàásì èròjà nicotine sínú ọpọlọ, èyí sì pọ̀ ju èròjà nicotine tí wọ́n máa ń fi sínú àwọn oògùn òyìnbó èyíkéyìí. Béèyàn bá ṣe ń fa èròjà olóró tó wà nínú àwọn tábà yìí léraléra tó, bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa tètè di bárakú tó. Tí èròjà yìí bá ti wọra tán, àìfararọ tó máa ń wáyé téèyàn bá fẹ́ jáwọ́ kì í ṣe kèrémí, pàápàá tí kò bá rí sìgá mu.

“Ẹ̀yin jẹ́ ẹrú rẹ̀ nítorí ẹ ń ṣègbọràn sí i.” —Róòmù 6:16

Ṣé wàá lè ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ tí tábà bá ti di bárakú fún ẹ?

Bíbélì jẹ́ ká ní èrò tó tọ̀nà nípa rẹ̀, ó ní: “Ẹ kò ha mọ̀ pé bí ẹ bá ń jọ̀wọ́ ara yín fún ẹnikẹ́ni bí ẹrú láti ṣègbọràn sí i, ẹ̀yin jẹ́ ẹrú rẹ̀ nítorí ẹ ń ṣègbọràn sí i?” (Róòmù 6:16) Tó bá wá di pé, téèyàn kò bá tíì rí sìgá mu ara rẹ̀ kì í lélẹ̀, a jẹ́ pé ẹni náà ti di ẹrú fún àṣà burúkú nìyẹn. Àmọ́, Ọlọrun tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà kò fẹ́ ká wà lábẹ́ àṣà tó lè ṣàkóbá fún ara wa, ọpọlọ wa àti ìrònú wa. (Sáàmù 83:18; 2 Kọ́ríńtì 7:1) Bí èèyàn bá mọrírì ohun tí Jèhófà ti ṣe láyé rẹ̀, tó sì ń fi ọ̀wọ̀ tó yẹ hàn fún un, irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa mọ̀ pé tí òun bá ṣì jẹ́ ẹrú fún àṣà tó léwu yìí, kò sí bí òun ṣe lè wu Ọlọ́run délẹ̀délẹ̀. Èyí á jẹ́ kéèyàn lè jáwọ́ nínú ìfẹ́ ọkàn tó ń tini sínú àṣà burúkú yìí.

Ọmọ ilẹ̀ Jámánì kan tó ń jẹ́ Olaf ti bẹ̀rẹ̀ sí í mu sìgá látìgbà tó ti wà lọ́mọ ọdún méjìlá [12]. Ọdún mẹ́rìndínlógún [16] sì ni sìgá fi di bárakú fún un lára kó tó di pé ó jáwọ́. Ó sọ pé: “Lọ́jọ́ tí mo kọ́kọ́ fa sìgá, kò jọ pè ó lè pa mi lára, ńṣe ló kàn dà bí eré ọwọ́. Ṣùgbọ́n bí ọdún ṣe ń gorí ọdún ni iye sìgá tí mò ń mu ń pọ̀ sí i. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí mi ò ní sìgá kankan lọ́wọ́, ìdààmú bá mi débi pé mo bẹ̀rẹ̀ sí í ha gbogbo àjókù sìgá tó wà nínú àwo eérú, mo sì dì í pọ̀ sínú àjákù ìwé ìròyìn kan. Ìgbà tí mo fà á tán, tí ara mi sì wálẹ̀, àánú ara mi ṣe mí.” Kí lo mú kí Olaf jáwọ́ nínú àṣà tó ń tini lójú yìí? Ó sọ pé: “Ohun pàtàkì tó jẹ́ kí n jáwọ́ ni pé mo fẹ́ ṣe  ohun tó wu Jèhófà, torí pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa àti ìrètí ọjọ́ iwájú ti fún mi lókun láti jáwọ́ nínú àṣà tó ti di bárakú fún mi yìí.”

SÌGÁ MÁA Ń ṢÀKÓBÁ FÚN ARA

Ìwé náà The Tobacco Atlas sọ pé: “Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti rí i pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ẹ̀ya ara ni sìgá máa ń ṣàkóbá fún, tó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ ké ẹ̀mí kúrú. Gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé sìgá mímu máa ń ṣokùnfà àwọn àrùn bí àrùn jẹjẹrẹ, àrùn ọkàn àti àrùn tó ń ba ẹ̀dọ̀ fóró jẹ́. Gẹ́gẹ́ bí Àjọ ìlera Àgbáyé ṣe sọ, ó tún máa ń fa àwọn àìsàn burúkú bí ikọ́ ẹ̀gbẹ èyí tó lè ṣekú pani.

“Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.”—Mátíù 22:37

Ṣé wàá lè fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, o sì mọyì ara rẹ tí o bá jẹ́ kí sìgá sọ ẹ dìdàkudà?

Jèhófà Ọlọ́run fi Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kọ́ wa ká lè jẹ́ ẹni tó mọyì ẹ̀mí wa, ẹ̀yà ara wa àti ìrònú wa. Jésù, ọmọ Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nípa kókó yìí nígbà tó sọ pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.” (Mátíù 22:37) Ó dájú pé, Ọlọ́run ò fẹ́ ká lo ara wa nílòkulò tàbí ká máa fi ẹ̀mí wa wewu. Bí a ṣe túbọ̀ ń mọ̀ sí i nípa Jèhófà àti àwọn ìlérí tó ti ṣe, á jẹ́ ká lè nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ká sì tún mọrírì àwọn ohun tó ti ṣe fún wa. Èyí á jẹ́ ká yàgò fún ohunkóhun tó lè sọ ara wá di eléèérí.

Dókítà kan tó ń jẹ́ Jayavanth ní orílẹ̀-èdè Íńdíà tó ti mú sìgá fún ọdún méjìdínlógójì [38] sọ pé: “Ohun tí mo kà nínú àwọn ìwé tó sọ̀rọ̀ nípa ìṣègùn jẹ́ kí n mọ̀ pé sìgá ń ṣe àkóbá fún ara. Kì í ṣe pé mi ò mọ̀ pé àṣà náà burú. Kódà, mo máa ń sọ fún àwọn tó wá gba ìtọ́jú lọ́dọ̀ mi pé kò dáa kí wọ́n máa mu sìgá. Èmi gan-an sì ti gbìyànjú bí ẹ̀ẹ̀marùn-ún sí ẹ̀ẹ̀mẹfà láti jáwọ́ àmọ́ kò rọrùn fún mi.” Kí ló ran dókítà yìí lọ́wọ́ tó fi lè jáwọ́ pátápátá? Ó sọ pé: “Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló jẹ́ kí ń jáwọ́. Àti pé mo fẹ́ ṣe ohun tó wu Jèhófà, èyí jẹ́ kí n tètè jáwọ́ nínú àṣà náà.”

SÌGÁ MÁA Ń ṢÀKÓBÁ FÚN ÀWỌN ẸLÒMÍÌ

Èéfín sìgá tàbí ti tábà tó rọra ń tú yẹ́ ẹ́ sínú afẹ́fẹ́ léwu gan-an. Ẹni tó bá fa èyí tó ń tú sínú afẹ́fẹ́ yìí lè ní àrùn jẹjẹrẹ àti àwọn àìsàn míì. Kódà, èéfín yìí ń pa ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ [600,000] èèyàn lọ́dọọdún. Àwọn obìnrin àti ọmọdé ló sì pọ̀ jù lára àwọn tí èéfín burúkú yìí ń pa. Àjọ Ìlera Àgbáyé kìlọ̀ pé: “Kò sí ìwọ̀n èéfín sìgá bó ti wù kó kéré tó tí kì í ṣe ìpalára fún èèyàn.”

“Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” —Mátíù 22:39

Tó o bá ń tu èéfín sìgá sínú afẹ́fẹ́ ǹjẹ́ ìyẹn fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn dénú?

 Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé, ìfẹ́ fún aládùúgbò wa, ìyẹn àwọn mọ̀lẹ́bí, ọ̀rẹ́, àti àwọn tó wà ní sàkání wa ló gbọ́dọ̀ gba ipò kejì ní ìgbésí ayé wa lẹ́yìn tí a bá ti fi ìfẹ́ fún Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́. Ó wá sọ pé “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Mátíù 22:39) Tí a ò bá jáwọ́ nínú àṣà tó ń ṣàkóbá fún àwọn tó sún mọ́ wa, ìyẹn ò ní fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. Àmọ́, tá a bá nífẹ̀ẹ́ wọn dénú, ńṣe la máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: “Kí olúkúlùkù má ṣe máa wá àǹfààní ti ara rẹ̀, bí kò ṣe ti ẹnì kejì.”—1 Kọ́ríńtì 10:24.

Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Armen tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Armenia sọ pé: “Àwọn ẹbí mi bẹ̀ mí pé kí ń jáwọ́ nínú sìgá mímu nítorí ó ń pa àwọn lára. Àmọ́ mo kọ̀ jálẹ̀ torí mí ò rò pé ó lè ṣe àkóbá kankan fún wọn.” Armen wá sọ ohun tó yí èrò rẹ̀ pa dà, ó ní: “Ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mo kọ́ àti ìfẹ́ tí mo ní fún Jèhófà ló jẹ́ kí n jáwọ́ nínú sìgá, mo sì gbà kedere pé, bí sìgá ṣe ń ṣàkóbá fún mi náà ló ń ṣe ìpalára fún àwọn míì tó sún mọ́ mi.”

SÌGÁ MÍMU MÁA TÓ DÓPIN!

Ẹ̀kọ́ Bíbélì ló ran Olaf, Jayavanth àti Armen lọ́wọ́ tí wọ́n fi bọ́ lọ́wọ́ àṣà tó ń tini lójú yìí, tó sì ń ṣe ìpalára fún wọn àtàwọn míì. Kì í ṣe nítorí àkóbá tí sìgá ń ṣe ni wọ́n fi jáwọ́, bí kò ṣe nítorí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọn sì fẹ́ láti ṣe ohun tó wù ú. Báwo la ṣe mọ̀ pé ìfẹ́ ló jẹ́ kí wọ́n jáwọ́? Jòhánù kìíní orí karùn-ún ẹsẹ kẹta sọ pé: “Nítorí èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.” Ká sòótọ́, kì í ṣe gbogbo ìgbà ló máa ń rọrùn láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, àmọ́ téèyàn bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run látọkàn wá, á rọrùn láti ṣègbọràn.

Jèhófà Ọlọrun ń lo ètò ẹ̀kọ́ tó ga jù lọ tó ń lọ lọ́wọ́ kárí ayé láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè bọ́ lọ́wọ́ àṣà yìí, kí wọ́n má baà di ẹrú fún tábà. (1 Tímótì 2:3, 4) Láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run tó máa wà lábẹ́ ìdarí Jésù Kristi máa mú gbogbo ètò ìṣòwò tó kún fún ìwà ìwọra tó sì ti sọ ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn di ẹrú fún tábà kúrò pátápátá. Jésù máa fòpin sí sìgá mímu pátápátá, á sì mú kí gbogbo àwọn tó bá ṣe ìgbọràn sí i ní ìlera pípe.—Aísáyà 33:24; Ìṣípayá 19:11, 15.

Tó o bá ṣì ń sapá láti jáwọ́ nínú sìgá mímu, má ṣe jẹ́ kó sú ẹ. Tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tó o sì ṣe tán láti tẹ̀ lé èrò rẹ̀ nípa sìgá mímu, ìwọ náà lè rí ohun tí á ràn ẹ́ lọ́wọ́ tí wàá fi bọ́ lọ́wọ́ àṣà burúkú yìí. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà á dùn láti wá ọ wá, wọ́n á kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ kí o lè fí àwọn ìlànà Bíbélì sílò. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé, tó o bá fẹ́ kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí o lè jáwọ́ nínú àṣà tó ń di bárakú yìí, ó ṣe tán láti fún ẹ lókun àti agbára tí o nílò.—Fílípì 4:13.

^ ìpínrọ̀ 3 Sìgá Mímu tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbí ń tọ́ka sí fífa èéfín tábà látara sìgá tàbí ìkòkò àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n fi tábà ṣe. Àmọ́, ìlànà Bíbélì tí a gbé yẹ̀ wò níbí tún kan àwọn tó máa ń mu sìgá ìgbàlódé tó ń lo bátìrì tàbí àwọn tó ń jẹ ewé tábà tàbí tó ń fín áṣáà.