Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍLẸ̀-ÈDÈ DOMINICAN

Ifarada Mu Itura Wa

Ifarada Mu Itura Wa

Bá A Ṣe Ń Dọ́gbọ́n Wàásù

Ọdún 1957 ni Rafael Pared, tí òun àti Francia, ìyàwó rẹ̀ ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì, di akéde. Ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] ni nígbà náà. Ó rántí bí àwọn ọlọ́pàá ṣe rọra máa ń ṣọ́ òun kiri nígbà tóun bá ń wàásù. Wọ́n ń wá bí wọ́n ṣe máa mú òun àtàwọn tí wọ́n jọ ń wàásù. Rafael sọ pé: “Nígbà míì, ṣe la máa ń yọ́ gba ọ̀nà ẹ̀yìn àtàwọn horo, a sì máa ń fo ògiri kí wọ́n má bàa mú wa.” Andrea Almánzar sọ ohun tóun àtàwọn míì máa ń ṣe kí wọ́n má bàa mú wọn, ó ní: “Ṣe la máa ń dọ́gbọ́n wàásù. Tá a bá ti wàásù nílé kan, a máa fo ilé mẹ́wàá ká tó wàásù nílé míì.”

Ìtura Dé Nígbẹ̀yìngbẹ́yín!

Ní ọdún 1959, ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọgbọ̀n [30] ọdún tí Trujillo ti ń ṣèjọba, àmọ́ ọ̀rọ̀ òṣèlú orílẹ̀-èdè náà bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà. Ní June 14, ọdún 1959, àwọn ọmọ ilẹ̀ Dominican kan tó wà nígbèkùn ya bo orílẹ̀-èdè náà kí wọ́n lè fipá gbàjọba lọ́wọ́ Trujillo. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀bẹ sélẹ̀ mọ́ àwọn ọlọ̀tẹ̀ yìí lọ́wọ́, tí wọ́n pa àwọn kan lára wọn, tí wọ́n sì fi àwọn míì sẹ́wọ̀n, àwọn ọ̀tá Trujillo túbọ̀ ń pọ̀ sí i, wọ́n sì gbà pé àwọn lè borí rẹ̀, torí náà ọwọ́ àtakò wọn túbọ̀ ń le sí i.

Ní January 25, ọdún 1960, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Kátólíìkì ti ń lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú ìjọba Trujillo, wọ́n kọ lẹ́tà kan tó fi hàn pé wọn ò fara mọ́ bí ìjọba náà ṣe ń fi ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn du àwọn aráàlú. Bernardo Vega tó jẹ́ òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Dominican sọ pé: “Nígbà tí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ṣọ́ọ̀ṣì rí bí àwọn kan ṣe gbógun ti ìjọba lóṣù June ọdún 1959, tí ìjọba sì fipá lo agbára lórí wọn àtàwọn tí kò fara mọ́ ìjọba náà lábẹ́lẹ̀, wọ́n kẹ̀yìn sí Trujillo fún ìgbà àkọ́kọ́.”

Ó dùn mọ́ wa pé lóṣù May ọdún 1960, ìjọba mú òfin tí wọ́n fi de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kúrò. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n fi ka iṣẹ́ wa léèwọ̀, ìtura dé láti ibi tí a kò fọkàn sí. Trujillo fúnra rẹ̀ ló mú ìfòfindè náà kúrò lẹ́yìn tí òun àtàwọn aṣáájú ẹ̀sìn Kátólíìkì ti wojú ara wọn.