Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bó O Ṣe Lè Dáàbò Bo Ara Ẹ Lọ́wọ́ Àwọn Ìsọfúnni Tí Kì Í Ṣòótọ́

Bó O Ṣe Lè Dáàbò Bo Ara Ẹ Lọ́wọ́ Àwọn Ìsọfúnni Tí Kì Í Ṣòótọ́

 Lónìí, ó rọrùn gan-an láti rí ìsọfúnni ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Bí àpẹẹrẹ, o lè rí ìsọfúnni nípa bó o ṣe lè dáàbò bo ara ẹ àti ohun tó o lè ṣe kí ìlera ẹ lè túbọ̀ dáa sí. Àmọ́ bó o ṣe ń ṣèwádìí, o gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fáwọn ìsọfúnni tí kì í ṣòótọ́, irú bíi:

 Bí àpẹẹrẹ, lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn Corona, akọ̀wé àgbà fún Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé kìlọ̀ nípa àjàkálẹ̀ àrùn míì tó burú gan-an, ìyẹn sì ni ìsọfúnni tí kì í ṣòótọ́ táwọn èèyàn ń tàn kálẹ̀. Ó sọ pé: “Àwọn ìmọ̀ràn tó lè ṣàkóbá fún ìlera wa àtàwọn ìtọ́jú ìṣègùn tó léwu ló kún ìgboro báyìí. Àwọn ìròyìn tí kì í ṣòótọ́ ló pọ̀ jù nínú tẹlifíṣọ̀n àti lórí rédíò. Oríṣiríṣi ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn làwọn èèyàn ń gbé sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ẹ̀mí ìkórìíra túbọ̀ ń gbéèràn, ìyẹn sì ń mú kí wọ́n máa hùwà ìkà sáwọn kan tàbí kí wọ́n máa fojú burúkú wo àwùjọ àwọn èèyàn kan.”

 Ohun kan ni pé, kì í ṣòní làwọn èèyàn ti ń tan ìsọfúnni tí kì í ṣòótọ́ kálẹ̀. Àmọ́ Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé, láwọn ọjọ́ ìkẹyìn “àwọn èèyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà á máa burú sí i, wọ́n á máa ṣi àwọn èèyàn lọ́nà, wọ́n á sì máa ṣi àwọn náà lọ́nà.” (2 Tímótì 3:​1, 13) Íńtánẹ́ẹ̀tì sì ti mú kó rọrùn láti gba irú àwọn ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ ká sì fi ránṣẹ́ láìfura. Torí náà, àwọn ìsọfúnni tí kì í ṣòótọ́ àti ìròyìn èké lè máa wọ orí fóònù àti ìkànnì àjọlò wa látìgbàdégbà.

 Báwo lo ṣe lè dáàbò bo ara ẹ kí àwọn ìsọfúnni àti ìròyìn èké má bàa ṣì ẹ́ lọ́nà? Jẹ́ ká wo àwọn ìlànà Bíbélì tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.

  •   Kì í ṣe gbogbo ohun tó o rí tàbí tó o gbọ́ ló yẹ kó o gbà gbọ́

     Ohun tí Bíbélì sọ: “Aláìmọ̀kan máa ń gba gbogbo ọ̀rọ̀ gbọ́, àmọ́ aláròjinlẹ̀ máa ń ronú lórí ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan.”​—Òwe 14:15.

     Bí àpẹẹrẹ, tá ò bá ṣọ́ra, àwọn àwòrán àtàwọn fídíò kéékèèké tí àwọn èèyàn máa ń gbé sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì pàápàá lórí ìkànnì àjọlò lè tàn wá jẹ. Wọ́n sábà máa ń fi àwọn àwòrán tàbí fídíò yìí fi pani lẹ́rìn-ín. Àmọ́, àwọn èèyàn lè dọ́gbọ́n sí àwọn àwòrán àti fídíò yìí kó sì gbé ìtumọ̀ míì síni lọ́kàn. Kódà àwọn èèyàn lè ṣe fídíò tó máa dà bíi pé ẹnì kan sọ tàbí ṣe ohun kan, kó sì jẹ́ pé ẹni náà ò ṣe bẹ́ẹ̀.

     “Àwọn ìsọfúnni tí kì í ṣòótọ́ táwọn tó ń ṣèwádìí sábà máa ń rí lórí ìkànnì àjọlò máa ń jẹ́ àwọn àwòrán àti fídíò tí wọ́n ti fọgbọ́n yí pa dà.”​—Axios Media.

     Bi ara ẹ pé: ‘Ṣé ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an ló wà nínú fídíò yìí àbí wọ́n kàn fi ń pani lẹ́rìn-ín?’

  •   Fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ibi tí ìsọfúnni kan ti wá àtohun tó wà nínú ẹ̀

     Ohun tí Bíbélì sọ: “Ẹ máa wádìí ohun gbogbo dájú.”​—1 Tẹsalóníkà 5:21.

     Tó o bá gba ìsọfúnni kan kódà kó jẹ́ èyí táwọn èèyàn ń sọ kiri ìgboro, kọ́kọ́ ṣèwádìí dáadáa kó o lè mọ̀ bóyá òótọ́ ni kó o tó gbà á gbọ́, kó o sì tó fi ránṣẹ́. Báwo lo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?

     Ṣàyẹ̀wò ibi tí ìsọfúnni náà ti wá, kó o lè mọ̀ bóyá ó ṣeé gbára lé. Àwọn iléeṣẹ́ agbéròyìn jáde àtàwọn àjọ míì lè pẹ́ ọ̀rọ̀ sọ tàbí kí wọ́n fi àbùmọ́ sí ìròyìn kan torí èrè tara wọn tàbí torí kí wọ́n lè gbè sẹ́yìn ẹgbẹ́ òṣèlú kan. Fi ohun tí iléeṣẹ́ agbéròyìn jáde kan sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ kan wé ohun tí iléeṣẹ́ agbéròyìn jáde míì sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ kan náà. Nígbà míì, àwọn ọ̀rẹ́ wa lè fi ìsọfúnni tí kì í ṣòótọ́ ránṣẹ́ sí wa lórí ìkànnì àjọlò láìmọ̀. Torí náà, má ṣe gba ìròyìn kan gbọ́ láìkọ́kọ́ ṣèwádìí nípa ibi tó ti wá.

     Kó o tó gba ìròyìn kan gbọ́, rí i dájú pé ìsọfúnni inú ẹ̀ péye, ó sì jẹ́ ti lọ́ọ́lọ́. Wo déètì ọjọ́ tí ìròyìn náà jáde, kó o sì rí i dájú pé ẹ̀rí tó ṣe kedere, tó sì lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ wà tó fi hàn pé ìròyìn náà jẹ́ òótọ́. Ó yẹ kó o ṣọ́ra tó o bá ń ka ìròyìn nípa ọ̀rọ̀ kan tó ta kókó àmọ́ tí wọ́n ṣàlàyé lọ́nà ṣákálá, tàbí tí wọ́n gbé ìròyìn náà kalẹ̀ lọ́nà táa mú kéèyàn ronú tàbí hùwà lọ́nà kan.

     “Níbi táyé dé báyìí, bó ti ṣe pàtàkì kéèyàn máa fọwọ́ déédéé, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe pàtàkì kéèyàn máa yẹ ìsọfúnni wò dáadáa.”​—Sridhar Dharmapuri, Ọ̀gá Àgbà Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ìtọ́jú Oúnjẹ fún Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé.

     Bi ara ẹ pé: ‘Ṣé èrò ara ẹni ló wà nínú ìròyìn yìí àbí òkodoro òtítọ́, ṣé kì í sì ṣe pé ẹni náà gbè sápá kan?’

  •   Má ṣe gbà pé òótọ́ ni ìsọfúnni kan, kìkì nítorí pé ó bá èrò ẹ mu

     Ohun tí Bíbélì sọ: “Ẹni tó bá gbẹ́kẹ̀ lé ọkàn ara rẹ̀ jẹ́ òmùgọ̀.”​—Òwe 28:26.

     Ó jẹ́ ìwà ẹ̀dá láti gba ìsọfúnni kan gbọ́ tó bá ti bá ohun tá a rò mu. Àwọn iléeṣẹ́ tó ń gbé ìròyìn jáde lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì sábà máa ń fi ìròyìn nípa àwọn nǹkan tá a nífẹ̀ẹ́ sí tàbí tá a ti wá nígbà kan rí ránṣẹ́ sí wa. Àmọ́, ti pé ìròyìn kan dá lórí ohun tá a nífẹ̀ẹ́ sí kò túmọ̀ sí pé ìroyìn náà jóòótọ́.

     “Torí pé àwa èèyàn máa ń ronú jinlẹ̀, a ní àwọn nǹkan tó wù wá, ohun tá à ń retí, ohun tó ń bà wá lẹ́rù, àtohun tó ń sún wa ṣe nǹkan, ìyẹn máa ń jẹ́ ká gbà pé òótọ́ ni ìsọfúnni kan tó bá ti bá èrò wa mu.”​—Ọ̀jọ̀gbọ́n Peter Ditto.

     Bi ara ẹ pé: ‘Ṣé torí pé ìsọfúnni yìí bá èrò mi mu ni mo ṣe gbà pé òótọ́ ni?’

  •   Má ṣe máa tan ìròyìn tí kì i ṣe òótọ́ kálẹ̀

     Ohun tí Bíbélì sọ: “O ò gbọ́dọ̀ tan ìròyìn èké kálẹ̀.”​—Ẹ́kísódù 23:1.

     Rántí pé ìsọfúnni tó o bá fi ránsẹ́ sáwọn míì lè mú kí wọ́n ronú tàbí hùwà lọ́nà tí kò tọ́. Kódà tó bá jẹ́ pé o ò mọ̀ọ́mọ̀ fi ìsọfúnni tí kì í ṣòótọ́ ránṣẹ́, àbájáde ẹ̀ ṣì lè burú gan-an.

     “Ká sọ pé gbogbo èèyàn máa ń ṣe sùúrù, kí wọ́n sì fara balẹ̀ bi ara wọn pé, ʻṢé ìsọfúnni yìí dá mi lójú kí n tó fi ránṣẹ́?’ ìyẹn á jẹ́ kí ìsọfúnni tí kì í ṣòótọ́ tá à ń rí lórí ìkànnì dín kù.”​—Peter Adams, ìgbà kejì ààrẹ Àjọ Tó Ń Dáni Lẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ìròyìn.

     Bi ara ẹ pé: ‘Ṣé òótọ́ ni ìsọfúnni tí mo fẹ́ fi ránṣẹ́ yìí?’