Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JESÚS MARTÍN | ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

“Jèhófà Gbà Mí Sílẹ̀ Lákòókò tó Nira Jù Lọ Nígbèésí Ayé Mi”

“Jèhófà Gbà Mí Sílẹ̀ Lákòókò tó Nira Jù Lọ Nígbèésí Ayé Mi”

Wọ́n bí mi lọ́dún 1936 nílùú Madrid. Mánigbàgbé ni ọdún yẹn jẹ́ fún àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Sípéènì, torí ọdún yẹn ni ogun abẹ́lé tó gbóná janjan bẹ̀rẹ̀ lórílẹ́-èdè náà.

 Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún mẹ́ta tí ogún abẹ́lé yẹn fi jà, ó sì fa ẹ̀dùn ọkàn àti ìnira fáwọn èèyàn títí kan bàbá mi. Bàbá mi nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. Àmọ́ inú bí wọn gán-an nígbà tí wọ́n rí bí àwọn àlùfáà Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ṣe lọ́wọ́ sí ogún yẹn. Torí náà, wọn pinnu pé èmi àti àbúrò mi ò ní ṣèrìbọmi ni Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì.

Francisco Franco ní àjọṣe tímọ́tìmọ́ pẹ̀lú Ṣọ́ọ́ṣì Kátólíìkì

 Lọ́dún 1950, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì wá sílé wa. Bàbá mi fetí sí wọn, wọ́n sì gbà láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá (14) péré ni mí nígbà yẹn, mo sì fẹ́ràn àtimáa gbá bọ́ọ̀lù. Bàbá mi máa ń fẹ́ kí n ka àwọn ìwé tí àwọn Ẹlẹ́rìí yẹn fún wọn, àmọ́ mi ò fẹ́ ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú wọn. Nígbà tí mo pa dà délé níbi tí mo ti lọ gbá bọ́ọ̀lù lọ́sàn-án ọjọ́ kan, mo béèrè lọ́wọ́ màmá mi pé, ṣé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn wá síbí lónìí? Wọ́n sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n tiẹ̀ wà pẹ̀lú dádì ẹ nínú ilé.” Ni mo bá sá pa dà síbi tí mo ti ń bọ̀!

 Bàbá mi ò jẹ́ kí bí mi ò ṣe nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ kó ìrẹ̀wẹ̀sì báwọn, èyí sì wú mi lórí gan-an. Kódà, wọ́n nífẹ̀ẹ́ ohun tí wọ́n ń kọ́ nínú Bíbélì débi pé wọ́n ṣèrìbọmi lọ́dún 1953, wọ́n sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìgbésẹ̀ tí wọ́n gbé yìí mú kí n ronú jinlẹ̀ gan-an, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í bi wọ́n lọ́pọ̀ ìbéèrè. Mo tiẹ̀ ní kí wọ́n fún mi ní Bíbélì kan. Wọ́n wá ní kí arákùnrin Máximo Murcia máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọdún méjì lẹ́yìn náà, mo ṣèrìbọmi lọ́mọ ọdún mọ́kàndínlógún (19) nínú Odò Jarama tó wà ní ìlà oòrùn ìlú Madrid, bí èmi náà ṣe di Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìyẹn.

Iṣẹ́ Ìwàásù Lásìkò Ìjọba Bóofẹ́bóokọ̀

 Ó ṣòro láti wàásù ká sì pàdé pọ̀ làwọn ọdún 1950. Ìdí ni pé Francisco Franco tó jẹ́ aláṣẹ ìjọba bóofẹ́bóokọ̀ ní Sípéènì fẹ́ kí gbogbo àwọn tó wà lórílẹ́-èdè náà máa ṣe ẹ̀sìn Kátólíìkì. Ìyẹn mú kí àwọn ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ sí í halẹ̀ mọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. A wá ń pàdé láwọn ilé àdáni, àmọ́ a máa ń ṣọ́ra gan-an kí àwọn aládùúgbò má bàa fura sí wa kí wọ́n sì sọ fáwọn ọlọ́pàá. A tún máa ń wàásù láti ilé dé ilé, àmọ́ a máa ń fọgbọ́n ṣe é. Tá a bá ti wàásù ní ilé méjì sí mẹ́ta ládùúgbò kan, àá tètè kúrò níbẹ̀ lọ sí àdúgbò míì. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbọ́rọ̀ wá, àmọ́ kì í ṣe gbogbo wọn ló nífẹ̀ẹ́ sí i.

Arákùnrin F. W. Franz sọ̀rọ̀ ní àpéjọ agbègbè kan tá a ṣe lábẹ́lẹ̀

 Mo rántí ìgbà kan tí mo pàdé àlùfáà Kátólíìkì kan bá a ṣe ń wàásù láti ilé de ilé, nígbà tí mo sọ ìdí tá a fi wá, ó béèrè pé: “Ta ló fún yín láṣẹ láti máa wàásù, ṣé o ò mọ̀ pé mó lè fi ẹjọ́ ẹ sun àwọn ọlọ́pàá?” Mo wá sọ fún un pé: “Ìyẹn kì í ṣe bàbàrà, ó ṣe tán àwọn ọ̀tá Jésù gbìyànjú láti fàṣẹ ọba mú un, ṣé kò wa yẹ káwa ọmọlẹ́yìn ẹ̀ náà máa retí ohun kan náà?” Ohun tí mo sọ yìí bí àlùfáà náà nínú, ló bá wọlé lọ pe àwọn ọlọ́pàá lórí fóònù. Lójú ẹsẹ̀, mo kúrò níbẹ̀.

 Láìka àwọn ìṣòro tá a dojú kọ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù sí, ìwọ̀nba àwọn akéde tó wà lórílẹ̀-èdè Sípéènì rí i pé ọ̀pọ̀ èèyàn lórílẹ̀-èdè náà nífẹ̀ẹ́ sì ẹ̀kọ́ òtítọ́. Ní February 1956, ètò Ọlọ́run sọ mi di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. a Nígbà yẹn, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún (19) ṣì ni mí. Ọ̀pọ̀ àwa tá a jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nígbà yẹn la kéré, a ò sì nírìírí. Àmọ́ àwọn míṣọ́nnárì tó wà pẹ̀lú wa ràn wá lọ́wọ́ wọ́n sì fún wa níṣìírí, a mọyì wọn gan-an. Ètò Ọlọ́run rán èmi àti aṣáájú-ọ̀nà kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ lọ sí ìlú Alicante níbi tí kò sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Láàárín oṣù mélòó kan, a pín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé, ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì la sì ń darí.

 Bá a ṣe dọ́gbọ́n ṣiṣẹ́ ìwàásù wa tó, àwọn èèyàn kíyè sí wa. Torí a ó tíì lò ju oṣù mélòó kan ní Alicante tí àwọn ọlọ́pàá fi mú wa, wọ́n sì gba àwọn Bíbélì wa. Ọjọ́ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) la lò ní àtìmọ́lé. Lẹ́yìn náà, wọ́n gbé wa lọ sí Madrid, ibẹ̀ ni wọ́n sì ti tú wa sílẹ̀. À ṣé mi ò tiẹ̀ tíì rí nǹkan kan.

Àkókò tó Nira Jù Lọ Nígbèésí Ayé Mi

 Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mọ́kànlélógún (21), wọ́n ní kí n wá wọṣẹ́ ológun. Torí náà, mo lọ sí àgọ́ àwọn sójà tó wà nílùú Nador. Ìlú yìí wà lára àwọn agbègbè tí Sípéènì ń ṣàkóso ní àríwá orílẹ̀-èdè Morocco. Nígbà tí mo dé iwájú ọ̀gá àwọn sójà, mo fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ṣàlàyé ìdí tí mi ò fi ní lè wọṣẹ́ ológun tàbí kí n tiẹ̀ wọṣọ wọn. Àwọn ọlọ́pàá wá mú mi lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Rostrogordo tó wà ní Melila títí wọ́n máa fi gbọ́ ẹjọ́ mi.

Ọgbà ẹ̀wọ̀n Rostrogordo tó wà ní Melilla

 Kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ mi, olórí àwọn ọmọ ogun Sípéènì ní Morocco sọ pé kí àwọn sójà nà mí kí orí mi lè pé. Torí náà, wọ́n fi mí ṣẹlẹ́yà, wọ́n sì nà mí fún ogún (20) ìṣẹ́jú títí mo fi ṣubú tí mí o sì mọ nǹkan kan mọ́. Àfi bíi pé ìyẹn ò tó, ní ọ̀gá wọn bá tún fi bàtà tẹ orí mi mọ́lẹ̀ títí ẹ̀jẹ̀ fi ń dà lára mi. Lẹ́yìn náà, wọn mú mi lọ sí ọ́fíìsì rẹ̀, ló bá ń pariwo pé: “Má rò pé mo ti ṣe tán pẹ̀lú ẹ o, mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni. Ohun tí máa sì máa ṣe sí ẹ nìyẹn lójoojúmọ́!” Ó ní kí àwọn ẹ̀ṣọ́ lọ tì mí mọ́ inú àjà ilẹ̀. Ibẹ̀ dúdú gan-an, ṣe ló dà bíi pé mi ò ní jáde níbẹ̀ mọ́.

 Mo ṣì rántí ìgbà tí mo wà lẹ́wọ̀n, tí mo sùn sílẹ̀ tí ẹ̀jẹ̀ sì bo gbogbo orí mi. Mi ò ní ju aṣọ ìbora kékeré kan. Gbogbo ohun tí mò ń rí ò ju àwọn eku tó ń sáré kiri lọ. Ṣe ni mo kàn ń bẹ Jèhófà pé kó fún mi lókun kí n lè fara dà á. Kódà, léraléra ni mo ń gbàdúrà nínú àjà ilẹ̀ tó ṣókùnkùn gan-an yẹn. b

 Lọ́jọ́ kejì, ọ̀gá sójà míì tún nà mí. Ó sì rí i dájú pé ẹ̀mí mi fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́ kó tó tẹ́ ẹ lọ́rùn. Ṣe ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé bóyá ni màá lè fara dà á mọ́. Ní alẹ́ ọjọ́ kejì tí mo lò ní yàrà ẹ̀wọ̀n yẹn, mo bẹ Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́.

 Lọ́jọ́ kẹta, wọ́n tún mú mi lọ sí ọ́fíìsì ọ̀gá àwọn sójà, lọ́tẹ̀ yìí, ẹ̀rù ń bà mí torí mo rò pé wọ́n tún máa nà mí. Ṣe ni mo ń gbàdúrà sí Jèhófà bí mo ṣe ń lọ sínú ọ́fíìsì ẹ̀. Sí ìyàlẹ́nu mi, Don Esteban c tó jẹ́ akọ̀wé àwọn ológun ló ń dúró dè mí níbẹ̀ kó lè fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò.

 Nígbà tí Don Esteban rí ohun tí mo fi di orí mi, ó béèrè pé kí ló ṣe mí lórí? Mi ò kọ́kọ́ fẹ́ sọ̀rọ̀ torí ẹ̀rù ń bà mí, àmọ́ mo pa dà sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún un. Nígbà tó gbọ́, ó sọ pé: “Fọkàn balẹ̀, ẹnì kankan ò ní lù ẹ́ mọ́, àmọ́ ìyẹn ò sọ pé wọn ò ní gbé ẹ lọ sí ilé ẹjọ́ o.”

 Bó ṣe sọ, ní gbogbo àkókò tí mo lò lẹ́wọ̀n yẹn, kò sí ẹnì kankan tó tún lù mí. Mi ò mọ̀ ìdí tó fi jẹ́ pé ọjọ́ yẹn gan-an ló wá fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò. Ohun tí mo mọ̀ ni pé Jèhófà dáhùn àdúrà mi lọ́nà ìyanu. Lọ́jọ́ yẹn, mo rí i bí Jèhófà ṣe gbà mí sílẹ̀ lákòókò tó nira jù lọ nígbèésí ayé mi, kò sì jẹ́ ki wọ́n fìyà jẹ mí kọjá ohun tí mo lè fara dà. (1 Kọ́ríńtì 10:13) Torí pé Jèhófà ni mo gbẹ́kẹ̀ lé, ọkàn mi balẹ̀ bí wọ́n ṣe ń gbọ́ ẹjọ́ mi.

Nígbà tí mo wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Ocaña

 Lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ẹjọ́ mi, wọ́n rán mi lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún mọ́kàndínlógún (19), wọ́n tún fi ọdún mẹ́ta kún un torí wọ́n ní mo ṣàìgbọràn. Lẹ́yìn tí mo lo ọdún kan àti oṣù mẹ́ta ní ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà ní Morocco, wọ́n gbé mi lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà ní Ocaña. Ibẹ̀ ò jìnnà sí ìlú Madrid, ibẹ̀ ni mo sì ti lo àkókò tó kù lẹ́wọ̀n. Mo rí ọwọ́ Jèhófà nílùú Ocaña tí wọ́n gbé mi lọ, torí ibẹ̀ tù mi lára ju ìlú Rostrogordo tí mo kọ́kọ́ wà tẹ́lẹ̀. Bẹ́ẹ̀dì àti àwọn aṣọ ìbora tí mo lè fi sùn wà nínú yàrá ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi mí sí. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni wọ́n yàn mí láti máa bójú tó ìnáwó ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ó máa ń ṣe mí bíi pé mo dá wà. Ohun tó jẹ́ kó túbọ̀ nira fún mi ni pé mi ò wà pẹ̀lú àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà.

 Àwọn òbí mi máa ń wá sọ́dọ̀ mi lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan àmọ́ mo ṣì nílò ìṣírí. Wọ́n sọ fún mi pé àwọn arákùnrin míì náà kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun. Torí náà, mo bẹ Jèhófà pé kó rán àwọn arákùnrin wá sí ọgbà ẹ̀wọ̀n tí mo wà, bó tiẹ̀ jẹ́ ẹnì kan. Jèhófà tún gbọ́ àdúrà àtọkànwá mi ju bí mo ṣe rò lọ. Torí kò pẹ́ sígbà yẹn ni arákùnrin Alberto Contijoch, Francisco Diaz, àti Antonio Sánchez dé si ọgbà ẹ̀wọ̀n tí mo wà ní Ocaña. Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an. Bí mo tún ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í rí ìṣírí gbà pa dà látọ̀dọ̀ àwọn ará nìyẹn lẹ́yìn ọdún mẹ́rin tí mo ti dá wà lẹ́wọ̀n. Bó ṣe di pé àwa mẹ́rẹ̀ẹrin jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tá a sì tún ń wàásù fáwọn tá a jọ wà lẹ́wọ̀n nìyẹn.

Wọ́n Tú Mi Sílẹ̀ Mo Sì Pa Dà Sẹ́nu Iṣẹ́

 Nígbà tó dọdún 1964, wọ́n dá mi sílẹ̀ lẹ́wọ̀n. Ọdún mẹ́fà àti ààbọ̀ ni mo lò lẹ́wọ̀n dípò ọdún méjìlélógún (22) tí wọn dá fún mi tẹ́lẹ̀. Ọjọ́ tí wọn dá mi sílẹ̀ lẹ́wọ̀n ni ìgbà àkọ́kọ́ tí mo máa lọ sípàdé, mo sì gbádùn ìpàdé náà gan-an. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìwọ̀nba owó tó ṣẹ́ kù lọ́wọ́ mi ni mo fi wọkọ̀ pa dà sí Madrid. Mo dé ìpàdé kí ìpàdé náà tó bẹ̀rẹ̀. Inú mi dùn láti wà pẹ̀lú àwọn ará lẹ́ẹ̀kan sí i. Àmọ́ ìyẹn nìkan kọ́ ló gbà mí lọ́kàn. Mo tún ń ronú nípa bí mo ṣe máa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà láìjáfara bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọlọ́pàá ṣì ń halẹ̀ mọ́ wa. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló nífẹ̀ẹ́ sì ìhìn rere tá à ń wàásù. Ìyẹn jẹ́ ká rí i pé iṣẹ́ ṣì pọ̀ fún wa láti ṣe.

 Lásìkò yẹn, mo pàdé arábìnrin kan tó ń jẹ́ Mercedes. Aṣáájú- ọ̀nà àkànṣe ni. Mercedes nírẹ̀lẹ̀ gan-an, ó sì máa ń sapá kó lè wàásù fún àwọn tó bá pàdé. Onínúure ni, ó sì lawọ́. Àwọn ìwà yìí ló mú kọ́kàn mi fà sí i. Mo dẹnu ìfẹ́ kọ ọ́, ó sì gbà. Ọdún kan lẹ́yìn náà, a ṣègbéyàwó. Ìbùkún ńlá nìyàwó mí jẹ́ nígbèésí ayé mi.

Èmi àti ìyàwó mi kété lẹ́yìn ìgbéyàwó wa

 Lẹ́yìn oṣù díẹ̀ tá a ṣègbéyàwó, ètò Ọlọ́run sọ pé ká bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò. Ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la máa ń bẹ̀ wò lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. A máa ń bá àwọn ará ṣèpàdé, àá sì báwọn lọ sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ọ̀pọ̀ àwọn ìjọ tuntun ni wọ́n ń dá sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè Sípéènì. Àwọn ará sì nílò ìrànlọ́wọ́ àti ìṣírí. Mo tún láǹfààní láti ṣiṣẹ́ fúngbà díẹ̀ ni ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń ṣiṣẹ́ lábẹ́lẹ̀ nílùú Barcelona.

 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a máa ń ṣiṣẹ́ lábẹ́lẹ̀, nǹkan yí pa dà lọ́dún 1967 nígbà tí ìjọba ṣòfin pé gbogbo ará ìlú lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ẹ̀sìn tó bá wù wọ́n. Nígbà tó dọdún 1970, a forúkọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Àtìgbà yẹn la ti lè pàdé pọ̀ láìsí pé àwọn ọlọ́pàá ń yọ wá lẹ́nu. A lè ní Ilé Ìjọsìn tiwa ká sì ní ẹ̀ka ọ́fíìsì.

A Gba Iṣẹ́ Ìsìn Tuntun

 Lọ́dún 1971, ètò Ọlọ́run ní kí èmi àti ìyàwó mi wá máa sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Barcelona. Àmọ́ ọdún kan lẹ́yìn náà, ìyàwó mi lóyún, a sì bí Abigail ọmọbìnrin wa tó rẹwà. Bá a ṣe fi Bẹ́tẹ́lì sílẹ̀ nìyẹn tá a sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn míì, ìyẹn títọ́jú ọmọ wa.

 Nígbà tí Abigail dàgbà, ètò Ọlọ́run bi wá pé ṣé a máa fẹ́ pa dà sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alábòójútó arìnrìn-àjò. A gbàdúrà nípa ọ̀rọ̀ náà, a sì fọ̀rọ̀ lọ àwọn ará tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn. Alàgbà kán sọ fún mi pé: “Jesús, tí wọ́n bá bi ẹ́ pé, ṣé wàá fẹ́ pa dà sẹ́nu iṣẹ́ arìnrìn-àjò, sọ fún wọn pé, bẹ́ẹ̀ ni.” Bá a ṣe tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà pa dà nìyẹn, a sì gbádùn ẹ̀ gan-an. Àwọn ìjọ tí ò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sílé wa la ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ká lè máa bójú tó Abigail ọmọ wa. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ọmọ wa náà tójú bọ́ ó sì bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé tiẹ̀, ìyẹn sì mú ká láǹfààní láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún lọ́nà àkànṣe.

 Ọdún mẹ́tàlélógún (23) lèmi àtìyàwó mi fi ṣiṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò. Mo gbádùn iṣẹ́ ìsìn yẹn gan-an torí ó jẹ́ kí n lè fi ìrírí mi ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, tí mo bá jẹ́ olùkọ́ nílé ẹ̀kọ́ àwọn alàgbà tàbí tàwọn aṣáájú-ọ̀nà, Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Madrid la máa ń dé sì. Ó máa ń yà mí lẹ́nu tí mo bá rò ó torí pé Odò Jarama tí mo ti ṣèrìbọmi lọ́dún 1955 kò ju kìlómítà mẹ́ta lọ sí Bẹ́tẹ́lì. Nígbà yẹn, mi ò tiẹ̀ rò ó rárá pé mo ṣì máa pa dà sí àgbègbè yìí láti máa ran àwọn ọ̀dọ́kùnrin àti ọ̀dọ́bìnrin lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.

Nígbà tí mo ń ṣiṣẹ́ olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run

 Àtọdún 2013 la ti pa dà sẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Kí n sòótọ́, kò rọrùn láti fi iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò sílẹ̀ ká sì pa dà sẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, àmọ́ ohun tó dáa jù nìyẹn. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, mo ṣàìsàn gan-an, kódà wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ ọkàn tó díjú gan-an fún mi. Láwọn àkókò yẹn, Jèhófà ni mo gbára lé bí mo ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ kò sì já mi kulẹ̀ rí. Yàtọ̀ síyẹn, fún ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́ta (56) nìyàwó mi fi jẹ́ alátìlẹyìn gidi fún mi, torí ó ti ràn mí lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn mi.

 Mo máa ń rántí àwọn àkókò alárinrin tí mo fi jẹ́ olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ àwọn aṣáájú-ọ̀nà àti tàwọn alàgbà. Mi ò jẹ́ gbàgbé ayọ̀ tó máa ń hàn lójú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yẹn. Bí wọ́n ṣe múra tán láti kẹ́kọ̀ọ́ máa ń jẹ́ kí n rántí ìgbà tí mo ṣì wà lọ́dọ̀ọ́ àti bí mo ṣe nítara nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Kí n sòótọ́, mo fara da àwọn ipò tó nira gan-an, àmọ́ àwọn ìrírí alárinrin tí mo ní fún mi láyọ̀. Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ni mo kọ́ lákòókò tó nira gan-an yẹn, àmọ́ èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé kí n má gbára lé ara mi rárá àti rárá. Àwọn ìṣòro tí mo dojú kọ ti jẹ́ kí n rí ọwọ́ agbára Jèhófà láyé mi, òun ló sì fún mi lókun làwọn àkókò tó nira jù lọ nígbèésí ayé mi.​—Fílípì 4:13.

Èmi àti ìyàwó mi ṣì ń ṣiṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún

a Aṣáájú ọ̀nà àkànṣe làwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún tó yọ̀ǹda ara wọn láti lọ síbi tí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti rí i pé a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sì i.

b Yàrá ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi mí sí kéré gan-an, kò sì nílé ìgbọ̀nsẹ̀. Orí ilẹ̀ tó dọ̀tí ni mo ń sùn sì pẹ̀lú aṣọ ìbora kan. Oṣù méje sì ni mo lò níbẹ̀.

c “Don” ni wọ́n máa ń lò láti bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn láwọn orílẹ̀-èdè tó ń sọ èdè Sípáníìṣì, ohun ló sì máa ṣáájú orúkọ ẹni yẹn.