Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 118

“Fún Wa Ní Ìgbàgbọ́ sí I”

“Fún Wa Ní Ìgbàgbọ́ sí I”

(Lúùkù 17:5)

  1. 1. Jèhófà, Bàbá wa, aláìpé ni wá.

    Ìwà àìtọ́ lọkàn wa máa ń fà sí.

    Ẹ̀ṣẹ̀ kan wà tó máa ń tètè wé mọ́ wa:

    Àìnígbàgbọ́ nínú rẹ, Ọlọ́run.

    (ÈGBÈ)

    Jèhófà, jọ̀ọ́, fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i.

    Ràn wá lọ́wọ́ bá a ṣe nílò rẹ̀ tó.

    Nínú àánú rẹ, fún wa nígbàgbọ́ sí i,

    Ká lè fìwà àtọ̀rọ̀ wa yìn ọ́.

  2. 2. Láìsí ‘gbàgbọ́, a kò lè múnú rẹ dùn.

    A gbọ́dọ̀ gbà pé ìgbàgbọ́ lérè.

    Ìgbàgbọ́ wa máa ń jẹ́ ká nífaradà;

    Ó ń dáàbò bò wá, a sì nírètí.

    (ÈGBÈ)

    Jèhófà, jọ̀ọ́, fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i.

    Ràn wá lọ́wọ́ bá a ṣe nílò rẹ̀ tó.

    Nínú àánú rẹ, fún wa nígbàgbọ́ sí i,

    Ká lè fìwà àtọ̀rọ̀ wa yìn ọ́.