Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 77

Ìmọ́lẹ̀ Nínú Ayé Tó Ṣókùnkùn

Ìmọ́lẹ̀ Nínú Ayé Tó Ṣókùnkùn

(2 Kọ́ríńtì 4:6)

  1. 1. Nínú ayé òkùnkùn yìí,

    Ìmọ́lẹ̀ kan ń tàn yòò.

    Ọjọ́ iwájú aláyọ̀

    Ti fẹ́rẹ̀ẹ́ wọlé dé.

    (ÈGBÈ)

    Iṣẹ́ ìwàásù wa

    Ń tàn yòò kárí ayé yìí

    Bí ‘mọ́lẹ̀ òwúrọ̀

    Kò ní sókùnkùn mọ́;

    Láìpẹ́, ọjọ́ aláyọ̀

    Yóò wọlé dé.

  2. 2. Ó yẹ ká jí àwọn tó ń sùn

    Torí àkókò ń lọ.

    Ká ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè

    La òpin tó ń bọ̀ já.

    (ÈGBÈ)

    Iṣẹ́ ìwàásù wa

    Ń tàn yòò kárí ayé yìí

    Bí ‘mọ́lẹ̀ òwúrọ̀

    Kò ní sókùnkùn mọ́;

    Láìpẹ́, ọjọ́ aláyọ̀

    Yóò wọlé dé.