Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 99

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún Àwa Ará

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún Àwa Ará

(Ìfihàn 7:9, 10)

  1. 1. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwa ará;

    A wà kárí ayé.

    Ẹlẹ́rìí òótọ́ ni wá,

    À ń pàwà títọ́ mọ́.

    Ẹgbẹẹgbẹ̀rún niye wa;

    Ṣe la túbọ̀ ń pọ̀ sí i.

    Látibi gbogbo kárí ayé,

    À ń fògo f’Ọ́lọ́run.

  2. 2. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwa ará;

    À ń ṣiṣẹ́ ìwàásù.

    Ìhìnrere aláyọ̀

    Là ń kéde fáráyé.

    Nígbà míì, ó lè rẹ̀ wá.

    Ká má ṣe sorí kọ́.

    Jésù ọ̀gá wa ń mára tù wá;

    Ó ń fọkàn wa balẹ̀.

  3. 3. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwa ará;

    Jáà ló ń dáàbò bò wá.

    À ń jọ́sìn Ọlọ́run wa

    Nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀.

    Ojoojúmọ́ là ń pọ̀ sí i.

    À ń ṣiṣẹ́ ìwàásù.

    A sì ń bá Ọlọ́run wa ṣiṣẹ́;

    À ń sìn ín tọ̀sántòru.