Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ṣé Jésù Ni Orúkọ Ọlọ́run?

Ṣé Jésù Ni Orúkọ Ọlọ́run?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Jésù pe ara rẹ̀ ní “Ọmọ Ọlọ́run.” (Jòhánù 10:36; 11:4) Jésù kò pe ara rẹ̀ ní Ọlọ́run Olódùmarè.

 Yàtọ̀ sí yẹn, Jésù gbàdúrà sí Ọlọ́run. Nígbà tó sì ń kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bí wọ́n ṣe máa gbàdúrà, ó sọ pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.”—Mátíù 6:9.

 Jésù ṣí orúkọ Ọlọ́run payá nígbà tó fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, tí wọ́n kọ láyé àtijọ́, ó sọ pé: “Gbọ́, Ìwọ Ísírẹ́lì, Jèhófà Ọlọ́run wa jẹ́ Jèhófà kan ṣoṣo.”—Máàkù 12:29; Diutarónómì 6:4.