Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ọ̀rẹ́?

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ọ̀rẹ́?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Ọ̀rẹ́ lè jẹ́ kí ìgbésí ayé ẹni nítumọ̀ ká sì láyọ̀. Àwọn ọ̀rẹ́ gidi máa jẹ́ ká níwà tó dáa.​—Òwe 27:17.

 Àmọ́, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì ká fọgbọ́n yan àwọn ọ̀rẹ́ wa. Ó jẹ́ ká mọ̀ pé ewu wà níbẹ̀ tá a bá yan ọ̀rẹ́ tí ò dáa. (Òwe 13:20; 1 Kọ́ríńtì 15:33) Irú àwọn ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ lè mú ká ṣèpinnu tí ò mọ́gbọ́n dání tàbí kí wọ́n ba ìwà rere wa jẹ́.

Nínú àpilẹ̀kọ yìí a máa sọ̀rọ̀ nípa

 Ta la lè pè ní ọ̀rẹ́ gidi?

 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀rẹ́ gidi kọjá ẹni ká jọ nífẹ̀ẹ́ ohun kan náà. Bí àpẹẹrẹ, Sáàmù 119:63 sọ pé: “Ọ̀rẹ́ mi ni gbogbo àwọn tó bẹ̀rù rẹ a àti àwọn tó ń pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́.” Kíyè sí i pé àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run tí wọ́n sì ń fi ìlànà rẹ̀ sílò ni onísáàmù náà yàn lọ́rẹ̀ẹ́.

 Bíbélì tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn ànímọ́ tó yẹ kí ọ̀rẹ́ gidi ní. Bí àpẹẹrẹ:

  •   “Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo, ó sì jẹ́ ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.”​—Òwe 17:17.

  •   “Àwọn ọ̀rẹ́ kan wà tí wọ́n ṣe tán láti ṣe ara wọn níkà, àmọ́ ọ̀rẹ́ kan wà tó ń fà mọ́ni ju ọmọ ìyá lọ.”​—Òwe 18:24.

 Àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká rí i pé ọ̀rẹ́ gidi máa ń dúró tini, ó máa ń nífẹ̀ẹ́, ó jẹ́ onínúure, ó sì lawọ́. Ọ̀rẹ́ gidi ni ẹni tá a lè fọkàn tán pé ó máa ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a bá níṣòro. Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń fìgboyà tọ́ wa sọ́nà tá a bá ń ṣe ohun tí ò tọ́.​—Òwe 27:6, 9.

 Àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rẹ́ gidi tó wà nínú Bíbélì?

 Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó jẹ́ ọ̀rẹ́ gidi bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ orí wọn, ibi tí wọ́n ti tọ́ wọn dàgbà, àṣà ìbílẹ̀ wọn àti ipò wọn láwùjọ yàtọ̀ síra. Ẹ jẹ́ ká wo mẹ́ta lára irú àwọn ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀.

  •   Rúùtù àti Náómì. Ìyàwó ni Rúùtù jẹ́ fún ọ̀kan lára àwọn ọmọ Náómì, kò sì sí àní-àní pé gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ ni Náómì fi ju Rúùtù lọ. Kò tán síbẹ̀ o, àṣà ìbílẹ̀ ibi tí Rúùtù ti wá yàtọ̀ pátápátá sí ti Náómì. Láìka èyí sí ọ̀rẹ́ wọn wọ̀ gan-an.​—Rúùtù 1:16.

  •   Dáfídì àti Jónátánì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí Jónátánì fi ọgbọ̀n (30) ọdún ju Dáfídì lọ, síbẹ̀ Bíbélì sọ pé “ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́” ni wọ́n​—1 Sámúẹ́lì 18:1.

  •   Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Ọ̀gá àti olùkọ́ ni Jésù jẹ́ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, torí náà ó ní ọlá àṣẹ lórí wọn. (Jòhánù 13:13) Síbẹ̀ kò fojú pa wọ́n rẹ́, kàkà bẹ́ẹ̀ Jésù ka gbogbo àwọn tó ń tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ rẹ̀ sí ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ó sọ pé: “Mo pè yín ní ọ̀rẹ́, torí pé mo ti jẹ́ kí ẹ mọ gbogbo ohun tí mo gbọ́ látọ̀dọ̀ Baba mi.”​—Jòhánù 15:14, 15.

 Ṣé ó ṣeé ṣe kéèyàn di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?

 Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣeé ṣe fún èèyàn láti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé: “Àwọn adúróṣinṣin ni ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́.” (Òwe 3:32) Lédè míì, Ọlọ́run máa ń jẹ́ ọ̀rẹ́ àwọn tó jẹ́ ọmọlúàbí, olóòótọ́, tó ń bọ̀wọ̀ fúnni, tó sì ń sapá láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Ìwé Mímọ́ dìídì pe Ábúráhámù tó jẹ́ olóòótọ́ ní ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.​—2 Kíróníkà 20:7; Àìsáyà 41:8; Jémíìsì 2:23.

a Ohun tí wọ́n ń bá bọ̀ nínú Sáàmù yìí fi hàn pé Ọlọ́run ni “rẹ” tí wọ́n lò nínú ẹsẹ yìí ń tọ́ka sí.