Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ṣé “Ẹ̀ṣẹ̀ Méje Tó La Ikú Lọ” Wà Lóòótọ́?

Ṣé “Ẹ̀ṣẹ̀ Méje Tó La Ikú Lọ” Wà Lóòótọ́?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Bíbélì ò dárúkọ “ẹ̀ṣẹ̀ méje tó la ikú lọ.” Àmọ́ ó sọ pé ẹni tó bá ń dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì ò ní rígbàlà. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì pe àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì yìí, bí àgbèrè, ìbọ̀rìṣà, ìbẹ́mìílò, ìrufùfù ìbínú àti mímu àmuyíràá ní “àwọn iṣẹ́ ti ara.” Ó wá sọ pé: “Àwọn tí ń fi irúfẹ́ nǹkan báwọ̀nyí ṣe ìwà hù kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.”​—Gálátíà 5:19-​21. a

Ṣebí Bíbélì mẹ́nu ba ‘ohun méje tí ó ṣe ìríra fún Olúwa’?

 Òótọ́ ni. Bíbélì Mímọ́ túmọ̀ Òwe 6:16 lọ́nà yìí: “Ohun mẹ́fà ni Olúwa kórìíra: nítòótọ́, méje ni ó ṣe ìríra fún ọkàn rẹ̀.” Àmọ́ kò túmọ̀ sí pé àwọn ohun tí Òwe 6:17-​19 mẹ́nu bà nìkan ló burú lójú Ọlọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ohun tó mẹ́nu bà kó onírúurú ẹ̀ṣẹ̀ pọ̀, títí kan ẹ̀ṣẹ̀ tó jẹ mọ́ èrò, ọ̀rọ̀ àti ìṣe. b

Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà, “ẹ̀ṣẹ̀ tó la ikú lọ”?

 Àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì kan lo ọ̀rọ̀ yìí ní 1 Jòhánù 5:16. Bí àpẹẹrẹ, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀ sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn wà tí ó la ti ikú lọ.” Ọ̀rọ̀ náà ‘ẹ̀ṣẹ̀ tí ó la ikú lọ’ tún lè túmọ̀ sí ‘ẹ̀ṣẹ̀ tí ń fa ikú wá báni.’ Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín ‘ẹ̀ṣẹ̀ tí ń fa ikú wá báni’ àti ‘ẹ̀ṣẹ̀ tí kì í fa ikú wá báni’?​—1 Jòhánù 5:16.

 Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ló ń yọrí sí ikú. Àmọ́ ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi lè gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Róòmù 5:12; 6:23) Torí náà, ẹbọ ìràpadà Kristi ò lè ṣe ètùtù fún ‘ẹ̀ṣẹ̀ tí ń fa ikú wá báni.’ Téèyàn bá dá irú ẹ̀ṣẹ̀ yìí, ohun tó túmọ̀ sí ni pé ẹni náà ń mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀, kò sì ṣe tán láti yíwà pa dà. Bíbélì tún pe irú ẹ̀ṣẹ̀ yìí ní ẹ̀ṣẹ̀ tí “a kì yóò dárí [rẹ̀] jini.”​—Mátíù 12:31; Lúùkù 12:10.

a Òótọ́ ni pé ìwé Gálátíà 5:19-​21 mẹ́nu ba àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) tó burú jáì, àmọ́ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yẹn nìkan ló burú, torí lẹ́yìn tí Bíbélì mẹ́nu bà wọ́n, ó fi kún un pé “àti nǹkan báwọ̀nyí.” Torí náà, ó yẹ kí ẹni tó ń kà á fi òye mọ àwọn ohun tí Bíbélì ò tò sínú ẹsẹ yẹn, èyí tó pè ní “nǹkan báwọ̀nyí.”

b Àpẹẹrẹ àkànlò èdè Hébérù kan ló wà nínú ìwé Òwe 6:16, tí wọ́n ti lo nọ́ńbà méjì tó yàtọ̀ síra láti fi tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀. Ìwé Mímọ́ sábà máa ń lo irú àkànlò èdè yìí.​—Jóòbù 5:19; Òwe 30:15, 18, 21.