Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ibo Ni Èṣù Ń Gbé?

Ibo Ni Èṣù Ń Gbé?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Ẹ̀dá ẹ̀mí ni Èṣù, ibi tí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí wà ló ń gbé. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe ibi tí wọ́n ti ń fi iná jó àwọn èèyàn burúkú ni Èṣù ń gbé, bí èyí tó wà nínú àwòrán tá a lò nínú àpilẹ̀kọ yìí.

“Ogun . . . bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀run”

 Láwọn ìgbà kan, Sátánì Èṣù máa ń lọ káàkiri bó ṣe wù ú ní ọ̀run, kódà ó máa ń wọlé síbi tí Ọlọ́run wà bí àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ ti máa ń ṣe. (Jóòbù 1:6) Àmọ́, Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé “ogun” yóò ṣẹlẹ̀ “ní ọ̀run,” àbájáde ogun yìí ni pé wọ́n á “lé [Sátánì] jù sí ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 12:7-9) Ìṣírò ọjọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì àti àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ láyé jẹ́rìí sí i pé ogun yìí ti wáyé. Ní báyìí, wọ́n ti lé Èṣù wá sí sàkáání ayé, kò sì gbọ́dọ̀ kọjá ibẹ̀.

 Ṣé ohun tí èyí wá túmọ̀ sí ni pé apá ibi kan láyé ni Èṣù ń gbé? Bí àpẹẹrẹ, wọ́n sọ pé ìlú Págámù ìgbàanì ni “ibi tí ìtẹ́ Sátánì wà” àti pé ibẹ̀ ni “Sátánì ń gbé.” (Ìṣípayá 2:13) Lóòótọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí ìjọsìn Sátánì ṣe kún ìlú yẹn fọ́fọ́ ni àwọn ọ̀rọ̀ yìí ń tọ́ka sí. Bíbélì sọ pé Èṣù ń ṣàkóso lórí “gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” Torí náà, sàkáání ilẹ̀ ayé tí wọ́n lé Èṣù sí ló ń gbé, kì í ṣe ibì kan tí ojú àwa èèyàn lè rí.​—Lúùkù 4:5, 6.