Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ṣé Mẹ́talọ́kan Ni Ọlọ́run?

Ṣé Mẹ́talọ́kan Ni Ọlọ́run?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn Kristẹni máa ń kọ́ni pé Ọlọ́run jẹ́ Mẹ́talọ́kan. Àmọ́, kíyè sí ohun tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ (Encyclopædia Britannica) sọ: “Ọ̀rọ̀ náà Mẹ́talọ́kan àti ẹ̀kọ́ mẹ́talọ́kan kò fara hàn nínú Májẹ̀mú Tuntun . . . Ńṣe ni ẹ̀kọ́ náà bẹ̀rẹ̀ sí í fara hàn díẹ̀díẹ̀ láti ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún wá, ọ̀pọ̀ awuyewuye ló sì wáyé lórí rẹ̀.”

 Ká sòótọ́, kò sí ibi kankan tí Bíbélì ti sọ pé Ọlọ́run jẹ́ Mẹ́talọ́kan. Gbọ́ ohun tí àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí sọ:

 “Jèhófà Ọlọ́run wa, Jèhófà kan ṣoṣo ni.”—Diutarónómì 6:4.

 “Ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”—Sáàmù 83:18.

 “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.”—Jòhánù 17:3.

 “Ẹnì kan ṣoṣo ni Ọlọ́run.”—Gálátíà 3:20.

 Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn Kristẹni fi sọ pé Ọlọ́run jẹ́ mẹ́talọ́kan?