Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Bí Eṣinṣin Ìgbẹ́ Ṣe Máa Ń Dábírà Tó Bá Ń Fò

Bí Eṣinṣin Ìgbẹ́ Ṣe Máa Ń Dábírà Tó Bá Ń Fò

 Ẹnikẹ́ni tó bá ti gbìyànjú àtipa eṣinṣin rí á mọ̀ pé kì í ṣe iṣẹ́ kékeré. Kẹ́ ẹ tó ṣẹ́jú pẹ́, wọ́n ti pa rẹ́ bí isó, ọ̀pọ̀ ìgbà lèèyàn kì í rí wọn pa bọ̀rọ̀.

 Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti rí i pé oríṣi eṣinṣin kan táwọn èèyàn mọ̀ sí eṣinṣin ìgbẹ́, lè fò bí ọkọ̀ òfuurufú táwọn ológun máa ń lò. Àmọ́ tiẹ̀ tún yàtọ̀ torí pé bó ṣe ń fò, láàárín ohun tí kò tó ìṣẹ́jú àáyá kan, á kàn dédé ṣẹ́rí pa dà lórí eré. Ọ̀jọ̀gbọ́n Michael Dickinson sọ pé, “Gbàrà tí eṣinṣin yìí bá bímọ làwọn ọmọ ẹ̀ á ti máa fò kiri bíi pé wọ́n ti ń ṣe é tipẹ́. Ṣe ló dà bíi kéèyàn gbé ọmọ tuntun síbi tí awakọ̀ òfuurufú máa ń jókòó sí, kó wá sọ fún un pé kó wa ọkọ̀ náà, kí ọmọ ọ̀hún sì wà á bí àgbàlagbà ṣe máa wà á gẹ́lẹ́. Ẹ ò rí i pé ó máa yani lẹ́nu.”

 Àwọn tó ń ṣèwádìí fi kámẹ́rà ká bí àwọn eṣinṣin náà ṣe máa ń fò, wọ́n sì rí i pé láàárín ìṣẹ́jú àáyá kan, ìgbà igba [200] ni wọ́n máa ń gbọn ìyẹ́ wọn. Síbẹ̀, tó bá jẹ́ ẹ̀ẹ̀kan ni wọ́n gbọn ìyẹ́, ìyẹn nìkan gan-an ti tó láti mú kí wọ́n ṣẹ́rí pa dà, kí wọ́n sì fò sá lọ.

 Tí nǹkan kan bá fẹ́ kàn wọ́n, báwo ni wọ́n ṣe máa ń yára tó láti fò sá lọ? Àwọn tó ń ṣèwádìí rí i pé àwọn eṣinṣin yìí fi ìlọ́po àádọ́ta [50] yara ju iye àkókò tó máa gba àwa èèyàn láti ṣẹ́jú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Dickinson ṣàlàyé pé, “Kéèyàn tó ṣẹ́jú pẹ́, eṣinṣin yìí ti yára mọ ibi tó lè wu ú léwu àti ohun tó máa ṣe táá fi rọ́nà fò sá lọ lójú ẹsẹ̀.”

 Ọpọlọ eṣinṣin ìgbẹ́ yìí kò ju bíntín bí orí abẹ́rẹ lọ, àmọ́ ṣe ń dábírà yìí ò tíì yé àwọn tó ń ṣèwádìí títí di bá a ṣe ń sọ yìí.

Tí eṣinṣin ìgbẹ́ bá rí ohun tó lè wu ú léwu, ṣe lá kàn dédé ṣẹ́rí pa dà fò gba ibòmíì láàárín ohun tí kò tó ìṣẹ́jú àáyá kan

 Kí lèrò ẹ? Ṣé eṣinṣin ìgbẹ́ tó ń dábírà yìí kàn ṣàdédé wà ni? Àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yẹn?