Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ṣé Ó Láwọn Fíìmù, Ìwé Tàbí Orin Tẹ́yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ò Gbọ́dọ̀ Gbádùn?

Ṣé Ó Láwọn Fíìmù, Ìwé Tàbí Orin Tẹ́yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ò Gbọ́dọ̀ Gbádùn?

 Rárá. A kì í ṣòfin nípa irú fíìmù táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wò, ìwé tá à ń kà tàbí irú orin tá à ń tẹ́tí sí. Kí nìdí?

  Bíbélì gba ẹnì kọ̀ọ̀kan wa níyànjú pé kí á kọ́ “agbára ìwòye” wa ká lè fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.​—Hébérù 5:14.

  Àwọn ìlànà kan wà nínú Ìwé Mímọ́ táá jẹ́ kí Kristẹni kọ̀ọ̀kan mọ irú eré ìnàjú tó máa yàn. a Nínú gbogbo ohun tá à ń ṣe nígbèésí ayé, a máa ń “wádìí dájú ohun tí Olúwa tẹ́wọ́ gbà.”​—Éfésù 5:10.

  Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn olórí ìdílé láṣẹ déwọ̀n àyè kan lórí ìdílé wọn. Torí náà, wọ́n lè pinnu irú eré ìnàjú táwọn ìdílé wọn máa wò àtèyí tí wọn ò gbọ́dọ̀ wò. (1 Kọ́ríńtì 11:3; Éfésù 6:​1-4) Àmọ́ nínú ìjọ, ẹnikẹ́ni ò láṣẹ láti pinnu ohun táwọn míì máa ṣe. Wọn ò lè ka fíìmù, orin tàbí àwọn òṣèré kan léèwọ̀ fáwọn ará.​—Gálátíà 6:5.

a Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì dẹ́bi fún ohunkóhun tó ń gbé ìbẹ́mìílò, ìṣekúṣe tàbí ìwà ipá lárugẹ.​—Diutarónómì 18:​10-13; Éfésù 5:3; Kólósè 3:8.