Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ṣé Torí Kẹ́ Ẹ Lè Jèrè Ìgbàlà Lẹ Ṣe Ń Wàásù Látilé Délé?

Ṣé Torí Kẹ́ Ẹ Lè Jèrè Ìgbàlà Lẹ Ṣe Ń Wàásù Látilé Délé?

 Rárá. A máa ń ṣiṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé o, àmọ́ a ò gbà pé tá a bá ti ń wàásù, a ti lẹ́tọ̀ọ́ sí ìgbàlà nìyẹn. (Éfésù 2:8) Kí nìdí?

 Jẹ́ ká fi wé ohun kan: Ká sọ pé ọkùnrin olówó tí ń fowó ṣàánú kan sọ pé òun máa fún gbogbo ẹni tó bá wá sí ibì kan lọ́jọ́ báyìí-báyìí lẹ́bùn iyebíye kan. Tó o bá gbà pé òótọ́ lẹni yẹn ń sọ, ṣó ò ní ṣe ohun tó ní káwọn èèyàn ṣe yẹn? Ó dájú pé wàá ṣe bẹ́ẹ̀! Wàá tún fẹ́ sọ fáwọn ọ̀rẹ́ rẹ àti ìbátan rẹ nípa àǹfààní tó yọjú yẹn káwọn náà bàa lè jẹ nínú rẹ̀. Síbẹ̀ náà, torí pé o ṣe ohun tí ọkùnrin yẹn ni kó o ṣe kọ́ lo fi dẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ẹ̀bùn. Ńṣe ló fi ẹ̀bùn yẹn ta ọ́ lọ́rẹ.

 Bákan náà, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gba ìlérí Ọlọ́run gbọ́ pé gbogbo àwọn tó bá ṣègbọ́ràn sí i yóò rí ìyè àìnípẹ̀kun. (Róòmù 6:23) A máa ń fẹ́ sọ ohun tá a gbà gbọ́ yìí fáwọn èèyàn, nírètí pé àwọn náà máa rí ìmúṣẹ ìlérí Ọlọ́run gbà. Àmọ́ a ò gbà pé iṣẹ́ ìwàásù ló máa jẹ́ ká lẹ́tọ̀ọ́ sí ìgbàlà. (Róòmù 1:17; 3:28) Ká sòótọ́, kò sóhun tẹ́dàá èèyàn kankan lè ṣe tó fi lè lẹ́tọ̀ọ́ sí ẹ̀bùn àgbàyanu yẹn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. “Kì í ṣe ntori iṣẹ́ rere kan tí a ṣe, ṣugbọn nitori àánú rẹ̀ ni ó fi gbà wá là.”—Títù 3:5, Ìròhìn Ayọ̀.