Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ

“Mi Ò Kì Í Ṣe Òǹrorò Èèyàn Mọ́”

“Mi Ò Kì Í Ṣe Òǹrorò Èèyàn Mọ́”
  • Ọdún Tí Wọ́n Bí Mi: 1973

  • Orílẹ̀-Èdè Mi: Uganda

  • Irú Ẹni Tí Mo Jẹ́ Tẹ́lẹ̀: Oníwà ipá, oníṣekúṣe àti ọ̀mùtí

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ

 Agbègbè Gomba lórílẹ̀-èdè Uganda ni wọ́n bí mi sí. Tálákà ló pọ̀ jù nínú àwọn tó ń gbébẹ̀. A ò ní iná mànàmáná ní ìlú wa, torí náà àtùpà elépo la máa ń lò lálẹ́.

 Àgbẹ̀ làwọn òbí mi, orílẹ̀-èdè Rwanda ni wọ́n ń gbé kí wọ́n tó kó lọ sí Uganda. Wọ́n máa ń gbin kọfí àti ọ̀gẹ̀dẹ̀, wọ́n sì máa ń fi ọ̀gẹ̀dẹ̀ náà ṣe ohun mímu kan táwọn èèyàn ń pè ní waragi. Àwọn òbí mi tún máa ń sin adìyẹ, ewúrẹ́, ẹlẹ́dẹ̀ àti màlúù. Àṣà wa àti bí wọ́n ṣe tọ́ mi dàgbà mú kí n gbà pé ìyàwó kan gbọ́dọ̀ máa gbọ́ràn sí ọkọ ẹ̀ lẹ́nu nígbà gbogbo, kò sì lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ èrò ẹ̀ jáde.

 Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún (23), mo kó lọ sí Rwanda, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sílé ijó pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi. Mo lọ sí ọ̀kan lára àwọn ilé ijó yìí débi pé nígbà tó yá, àwọn aláṣẹ ibẹ̀ fún mi ní káàdì tí mo fi lè máa wọlé lọ́fẹ̀ẹ́. Mo tún gbádùn kí n máa wo àwọn eré oníwà ipá níbi táwọn èèyàn ti ń jà. Agbègbè tí mò ń gbé àti eré ìnàjú tí mò ń ṣe wá sọ mí di oníwà ipá, oníṣekúṣe àti ọ̀mùtí paraku.

 Lọ́dún 2000, mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbé pẹ̀lú obìnrin kan tó ń jẹ́ Skolastique Kabagwira, a sì bí ọmọ mẹ́ta. Bí wọ́n ṣe kọ́ mi láti kékeré, mo retí pé kó máa kúnlẹ̀ síwájú mi tó bá ń kí mi tàbí tó bá fẹ́ béèrè nǹkan lọ́wọ́ mi. Mo tún máa ń sọ pé èmi nìkan ni mo ni gbogbo nǹkan tí ìdílé wa ní, bó bá sì ṣe wù mí ni mo ṣe lè ṣe é. Mo sábà máa ń jáde lálẹ́, tí n bá sì máa fi wọlé ní nǹkan bí aago mẹ́ta òru, màá ti mutí yó kẹ́ri. Tí Skolastique ò bá tètè ṣí ilẹ̀kùn fún mi tí mo bá kan ilẹ̀kùn, ṣe ni mo máa ń lù ú ní àlùbami.

 Nígbà yẹn, ọ̀gá ni mí nílé iṣẹ́ aládàáni kan tó ń pèsè ààbò, owó oṣù mi sì jọjú. Tí mo bá wà nílé pẹ̀lú Skolastique, ó máa ń rọ̀ mí pé kí n bá òun lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì Pentecostal tó ń lọ, torí ó rò pé ìyẹn máa mú kí n yí pa dà. Àmọ́ kò wù mí. Dípò kí n máa bá a lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, ṣe lọkàn mi bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí obìnrin míì. Nígbà tí ìyàwó mi rí i pé ṣe nìwà mi ń burú sí i, ó kó àwọn ọmọ wa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kúrò nílé, ó sì lọ ń gbé pẹ̀lú àwọn òbí ẹ̀.

 Ọ̀rẹ́ wa kan tó jẹ́ àgbàlagbà bá mi sọ̀rọ̀ nípa bí mo ṣe ń gbé ìgbésí ayé mi. Ó ní kí n pa dà sọ́dọ̀ Skolastique. Ó sọ pé kí n ro tàwọn ọmọ tó rẹwà tí mo bí, pé ó yẹ kí wọ́n wà pẹ̀lú bàbá wọn ni. Nígbà tó dọdún 2005, mi ò mutí mọ́, mo fi obìnrin kejì yẹn sílẹ̀, mo sì pa dà sọ́dọ̀ Skolastique. Lọ́dún 2006, a ṣègbéyàwó. Síbẹ̀, mo ṣì máa ń na Skolastique, mi ò sì bọ̀wọ̀ fún un rárá.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ

 Lọ́dún 2008, Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń jẹ́ Joël wá wàásù nílé wa, mo sì tẹ́tí sí i. Ọ̀pọ̀ oṣù lòun àti Ẹlẹ́rìí míì tó ń jẹ́ Bonaventure fi ń wá sọ́dọ̀ mi déédéé, tá a sì jọ ń jíròrò Bíbélì jinlẹ̀. Mo béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè, pàápàá jù lọ nípa ìwé Ìfihàn. Mo ṣáà fẹ́ gbìyànjú láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ẹ̀kọ́ wọn ò tọ̀nà. Bí àpẹẹrẹ, mo béèrè pé kí nìdí tí wọ́n fi sọ pé orí ilẹ̀ ayé ni “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” tí ìwé Ìfihàn 7:9 sọ̀rọ̀ nípa wọn máa gbé, nígbà tí ẹsẹ yẹn sọ pé “wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà,” Jésù Kristi. Kò sígbà tí mo béèrè ìbéèrè tí Joël kì í fi sùúrù dá mi lóhun. Bí àpẹẹrẹ, ó fi ohun tó wà nínú Àìsáyà 66:1 hàn mí, níbi ti Ọlọ́run ti pe ayé ní “àpótí ìtìsẹ̀” rẹ̀. Torí náà, ó ṣe kedere pé ilẹ̀ ayé ni ogunlọ́gọ̀ èèyàn náà dúró sí níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run. Mo tún ka Sáàmù 37:29 tó sọ pé àwọn olódodo ló máa gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé.

 Níkẹyìn, mo gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Torí náà, Bonaventure bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èmi àti Skolastique lẹ́kọ̀ọ́. Bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo túbọ̀ ń rí ìdí tó fi yẹ kí n yí ìgbésí ayé mi pa dà. Mo kọ́ bí mo ṣe lè máa hùwà tó dáa sí ìyàwó mi. Mi ò retí pé kó máa kúnlẹ̀ tó bá fẹ́ kí mi mọ́ tàbí tó bá fẹ́ béèrè nǹkan lọ́wọ́ mi, mi ò sì sọ pé èmi nìkan ni mo ni gbogbo nǹkan tí ìdílé wa ní mọ́. Yàtọ̀ síyẹn, mi ò wo fíìmù oníwà ipá mọ́. Kò rọrùn fún mi láti ṣe àwọn àyípadà yìí rárá, àmọ́ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, mo kọ́ béèyàn ṣe ń lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìkóra-ẹni-níjàánu.

Bíbélì ràn mí lọ́wọ́ láti di ọkọ rere

 Ní ọdún díẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn, mo ti mú Christian ọmọ wa àgbà lọ sọ́dọ̀ àwọn ìbátan wa ní Uganda pé kó máa lọ gbẹ́ níbẹ̀. Àmọ́ lẹ́yìn tí mo ka Diutarónómì 6:​4-7, mo rí i pé ojúṣe èmi àti ìyàwó mi ni láti bójú tó àwọn ọmọ wa, èyí sì kan kíkọ́ wọn láwọn ìlànà Ọlọ́run. Ẹ wo bínú wa ṣe dùn tó nígbà tó pa dà sílé!

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ

 Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé aláàánú ni Jèhófà Ọlọ́run, mo sì gbà pé ó ti dárí àwọn ìwà mi àtijọ́ àtàwọn àṣìṣe mi jì mí. Inú mi dùn pé Skolastique náà kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. A yara wá sí mímọ́ fún Jèhófà, a sì jọ ṣèrìbọmi ní December 4, 2010. Ní báyìí, a fọkàn tán ara wa, a sì ń gbádùn bá a ṣe ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nínú ìdílé wa. Inú ìyàwó mi máa ń dùn gan-an pé ilé ni mo máa ń wá tààrà tí n bá ti ṣíwọ́ níbi iṣẹ́. Ó tún mọyì bí mo ṣe ń bọ̀wọ̀ fún òun tí mo sì ń pọ́n òun lé. Inú ẹ̀ dùn pé mo ti pinnu pé mi ò ní mutí mọ́ àti pé mo ti fi gbogbo ìwà òǹrorò mi sílẹ̀. Lọ́dún 2015 mo di alàgbà, èyí tó mú kí n láǹfààní àtimáa bójú tó àwọn tá a jọ wà nínú ìjọ. Yàtọ̀ síyẹn, mẹ́ta nínú àwọn ọmọ wa márùn-ún ló ti ṣèrìbọmi.

 Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mi ò kàn tẹ́wọ́ gba àwọn ohun tí wọ́n ń kọ́ mi láìwádìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni mo da ìbéèrè bò wọ́n, inú mi sì dùn gan-an bí wọ́n ṣe lo Bíbélì láti dáhùn àwọn ìbéèrè mi. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, èmi àti Skolastique túbọ̀ ń mọyì bó ti ṣe pàtàkì tó pé káwa tà à ń jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ máa fi ìlànà rẹ̀ sílò nígbèésí ayé wa dípò ká máa ṣe ohun tó bá ti wù wá. Mo dúpẹ́, mo tọ́pẹ́ dá pé Jèhófà fà mí láti wá di apá kan ìdílé ẹ̀. Tí mo bá ń ronú nípa irú ìgbésí ayé tí mo ti gbé tẹ́lẹ̀, ó dá mi lójú pé bó ti wù kí ìwà téèyàn kan ń hù tẹ́lẹ̀ burú tó, ó lè yí pa dà pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, àá sì tipa bẹ́ẹ̀ múnú Ọlọ́run dùn.