Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Kan Di Púpọ̀

Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Kan Di Púpọ̀

 Marta tó jẹ́ ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Guatemala ń kọ́ èdè Kekchi kó lè máa wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì fún àwọn tó ń sọ èdè náà. Lọ́jọ́ kan, ó rí ọkùnrin kan tó ń jáde kúrò ní ilé ìwòsàn. Nígbà tí Marta wo ìrísí ọkùnrin náà, ó fura pé abúlé Kekchi ní agbègbè olókè kan ni ọkùnrin náà ti wá, ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan làwa Ẹlẹ́rìi Jèhófà sì máa ń wàásù dẹ́bẹ̀. Ó lọ bá ọkùnrin náà, ó sì báa sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìwọ̀nba èdè Kekchi tó gbọ́.

 Marta fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ ọ́, inú ọkùnrin náà dùn, ó sì gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ ó sọ fún Marta pé òun ò lówó tóun máa san fún un. Marta ṣàlàyé fún un pé ọ̀fẹ́ làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó tún sọ fún un pé, ó lè máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lórí fóònù àti pé gbogbo ìdílé ẹ̀ lè dara pò mọ́ ọn. Ọkùnrin náà sì gbà. Torí pé ọkùnrin náà gbọ́ èdè Sípáníìṣì, Marta fún un ní Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Sípáníìṣì. Ó tun fún un ní ìwé tá a fi ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? lédè Kekchi. Lọ́sẹ̀ tó tẹ̀lé e, ọkùnrin náà, ìyàwó ẹ̀ àti àwọn ọmọ wọn méjèèjì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú Marta lórí fóònù. Ẹ̀ẹ̀mejì ni wọ́n ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn lọ́sẹ̀. Marta sọ pé: “Torí pé mí ò lè sọ èdè Kekchi dáadáa, èdè Sípáníìṣì la fi ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Ó ṣe tán ọkùnrin náà àti àwọn ọmọ ẹ̀ gbọ́ èdè Sípáníìṣì. Àmọ́ torí pé ìyàwó ẹ̀ kò gbọ́ èdè Sípáníìṣì, Ọkùnrin náà máa ń túmọ̀ ohun tá à ń sọ fún ìyàwó ẹ̀ lédè Kekchi.”

 Pásítọ̀ ni ọkùnrin yìí ní ṣọ́ọ̀sì ẹ̀. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ọmọ ìjọ ẹ̀ ní ohun tó ń kọ́ láti inú Bíbélì. Àwọn ọmọ ìjọ ẹ̀ fẹ́ràn ohun tí wọn ń gbọ́, wọ́n sì béèrè ibi tó ti ń kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tuntun yìí. Nígbà tó sọ fún wọn nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń ṣe, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ ọn níkọ̀ọ̀kan. Kò pẹ́ tí àwọn bíi mẹ́ẹ̀dógún (15) fi ń dara pọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ lórí fóònù pẹ̀lú Marta. Nígbà tó yá, wọ́n gbé ẹ̀rọ gbohùngbohùn sẹ́gbẹ̀ẹ́ fóònù kí gbogbo wọn báa lè gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ náà.

 Nígbà tí Marta sọ fún àwọn alàgbà ìjọ ẹ̀ nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí, ọ̀kan nínú wọn lọ sí abúlé tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ń gbé. Ó wá sọ fún wọn pé kí wọ́n wá gbọ́ àsọyé kan tí alábòjútó àyíká a fẹ́ sọ ní abúle míì. Abúlé yìí jìnnà díẹ̀, kódà tí wọ́n bá wọ mọ́tò, ó máa gbà wọ́n ní wákàtí kan kí wọ́n tó débẹ̀, á sì gbà wọ́n ní wákàtí méjì tí wọn bá fẹsẹ̀ rìn. Láìka èyí sí, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà gbà láti lọ, àwọn métàdínlógún (17) ló sì pésẹ̀ síbẹ̀.

 Ọ̀sẹ̀ mélòó kan lẹ́yìn náà, alábòjútó àyíká náà àti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà míì lọ lo ọjọ́ mẹ́rin pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà. Láàárọ̀, wọ́n á wo àwọn fídíò tó dá lórí Bíbélì lédè Kekchi látorí ìkànnì jw.org, wọn á sì kẹ́kọ̀ó látinú ìwé pẹlẹbẹ náà Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní? Lọ́sàn-án, wọ́n á wo àwọn fídíò tó wà ní Tẹlifísọ̀n JW. Alábòjútó àyíká náà tún ṣètò pé kí akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan ní ẹni táá máa kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

 Láààrin ọjọ́ mẹ́rin yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà tún wàásù làwọn abúlé Kekchi tó wà lágbègbè náà, wọ́n sì pe àwọn èèyàn wá sí àkànṣe ìpàdé kan. Níbi ìpàdé náà, wọ́n sọ fún àwọn mẹ́tàdínláàádọ́ta (47) tó pésẹ̀ láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìdílé mọ́kànlá (11) sì gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀.

 Lẹ́yìn oṣù díẹ̀, àwọn alàgbà ṣètò láti máa ṣèpàdé ní abúlé yẹn ní gbogbo òpin ọ̀sẹ̀. Ní báyìí, àwọn bí ogójì (40) ló ń wá sípàdé déédéé. Nígbà tí wọ́n sì ṣe Ìrántí Ikú Jésù níbẹ̀, inú wọn dùn gan-an torí pé àwọn mọ́kànléláàádọ́rùn-ún (91) ló wá.

 Nígbà tí Marta rántí bí ìrírí yìí ṣe bẹ̀rẹ̀, ó sọ pé: “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà. Nígbà míì, ó máa ń ṣe mí bíi pé mi ò lè ṣe púpọ̀, àmọ́ ohun èlò la jẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà. Ó mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn ará abúlé yẹn, ó sì fà wọ́n sún mọ́ àwọn èèyàn rẹ̀. Ó dájú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn.”

a Alábòjútó àyíká jẹ́ òjíṣẹ́ kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì máa ṣèbẹ̀wò sáwọn ìjọ tó tó ogún (20) tó wà ní àyíká kan.