Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Mo Máa Ń Gbàdúrà Lórí Igi Ràgàjì Kan

Mo Máa Ń Gbàdúrà Lórí Igi Ràgàjì Kan

 Rachel tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Dominican Republic báyìí sọ pé: “Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn òbí mi, àmọ́ ó báni nínú jẹ́ pé nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méje ni bàbá mi fi òtítọ́ sílẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ta kò wá lọ́nà tó gbóná janjan. Ìyẹn ò sì jẹ́ kó rọrùn fún mi láti sin Jèhófà bí mo ṣe fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń sọ fún mi pé tí mo bá gbà láti fi Jèhófà sílẹ̀ àwọn máa ra fóònù fún mi, wọ́n á gbé mi lọ gbafẹ́ ní Disneyland àtipé wọ́n á fún mi láǹfààní láti náwó bí mo ṣe fẹ́. Nígbà míì, wọ́n máa ń lù mí bí ẹni máa kú kí n ṣáà lè fi Jèhófà sílẹ̀. Wọ́n tún máa ń sọ fún mi pé ṣèbí nígbà ‘tó o bá lè sọ̀rọ̀, tàbí tó o lè rin ni wàá lè lọ sípàdé.’ Àmọ́ pàbó ni gbogbo ìsapá wọn já sí. Torí mo ti pinnu pé ohun tó bá gbà ni máa fún un, kí n lè máa lọ sípàdé déédéé.

 “Bàbá mi kì í lù mí lójú màámi. Kódà wọ́n máa ń halẹ̀ mọ́ mi pé tí mo bá sọ fún màámi pẹnrẹn àwa méjèèjì làwọn máa ṣe léṣe. Yàtọ̀ síyẹn, bàbá mi máa ń parọ́ pé, bí àwọn ṣe ń kọ́ mi kí ń lè máa gbèjà ara mi tí ẹlòmíì bá fẹ́ bá mi jà ló fà á tí àwọn àpá yánna-yànna fi wà lára mi.

 “Torí pé mò ń bẹ̀rù bàbá mi àti pé mo ṣì kéré ni kò jẹ́ kí n lè sọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ fún màámi. Àmọ́ mo máa ń sọ gbogbo bọ̀rọ̀ ṣe rí lára mi fún Jèhófà. Mo máa ń rin ìrìn tó jìn nínú igbó kan tí igi pọ̀ sí lẹ́yìn ilé wa ní Maryland lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Igi ńlá ràgàjì kan wà níbẹ̀ ìyẹn igi oak, mo máa ń gun igi yìí máa wá jókòó sórí ẹ̀ka rẹ̀ máa sì gbàdúrà àtọkànwá sí Jèhófà. Mo máa ń sọ bí nǹkan ṣe rí lára mi fún un àtohun tó wù mí kí ń ṣe nínú ètò rẹ̀, ìyẹn tí bàbá mi ò bá lù mi pa kí n tó dàgbà. Mo máa ń bẹ̀ ẹ́ kó ràn mí lọ́wọ́ kí n lè fara dà á. Bákan náà, mo máa ń sọ ohun tí màá ṣe nínú ayé tuntun fún Jèhófà, irú ìdílé tó wù mí kí ń ni, àti bí mo ṣe ń fojú sọ́nà dìgbà tí kò ní sí ìrora àti ìbẹ̀rù mọ́, tọ́kàn mi á sì balẹ̀ títí láé.

 “Jèhófà fún mi lókun ó sì dúró tì mí làwọn ìgbà tí bàbá mi ń fi onírúurú nǹkan bẹ̀ mí tó sì ń lù mí ní àlùbami kí n lè fi òtítọ́ sílẹ̀. Ọlọ́run ló ràn mí lọ́wọ́ kí n lè jẹ́ olóòótọ́ ní àkókò yẹn, ó kọjá agbára mi.

 “Ọmọ ọdún mẹ́wàá ni mí nígbà tí mo ṣèrìbọmi, mo sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ́dún méjì lẹ́yìn náà. Bàbá mi ò kọ́kọ́ mọ̀ sí àwọn nǹkan tí mo ṣe yìí, àmọ́ nígbà tí wọ́n mọ̀, wọ́n lù mí débi tí eegun páárí ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi fi yẹ̀.

 “Àwọn kan sọ fún mi pé mo ṣì kéré láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà, ọkàn wọn ò sì balẹ̀ torí wọ́n gbà pé mi ò mọ ohun tí mo tọrùn bọ̀. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, mo rí àwọn ọ̀dọ́ bíi tèmi, tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí tá a jọ wà ládùúgbò tí wọn ò fọwọ́ pàtàkì mú nǹkan tẹ̀mí. Ṣe ni wọ́n kàn ń gbádùn ara wọn tí wọ́n sì ń lọ sílé ijó. Ó ń ṣe mi bíi pé kò sí ohun tó burú nínú ohun tí wọ́n ń ṣe, ó sì máa ń wù mí kémi náà máa ṣe bíi tiwọn. Mo máa ń ronú pé, ‘Ṣé mí ò ní jáwọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù kémi náà lè gbádùn ara mí bíi tàwọn ojúgbà mi báyìí?’ Àmọ́ láwọn ìgbà tí irú èrò yìí bá ti wá sí mi lọ́kàn, ṣe ni mo máa ń gbàdúrà sí Jèhófà.

 “Nígbà tí mo wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15), ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń polówó aṣọ ìgbàlódé ní kí n wá bá àwọn ṣiṣẹ́. Wọ́n ní àwọn máa san owó gọbọi fún mi tí mo bá gbà lati bá wọn ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka wọn tó wà ní Milan lórílẹ̀-èdè Ítálì. Inú mi dùn nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ sọ fún mi. Torí ṣe ni mo kàn ń rò ó pé, èmi náà a wọ aṣọ olówó iyebíye wọ́n á sì máa gbé fọ́tò mi sórí àwọn ìwé ìròyìn, màá wá di ìlú mọ̀ọ́ká. Nígbà yẹn ó ti tó nǹkan bí ọdún mẹ́ta tí mo ti ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé, èrò mi sì ni pé, ‘Àǹfààní ńlá mà rèé, màá lè rówó gbọ́ bùkátà mi kí ń lè máa bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ. Yàtọ̀ síyẹn, màá tún rówó fun màámi láti bójú tó ara wọn nítorí bàbá mi ti fi wá sílẹ̀.

 “Mo gbàdúrà nípa ọ̀rọ̀ náà, mo sì sọ fún màámi torí àwọn náà ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Bákan náà, mo tún sọ fún alàgbà kan tí mo fọkàn tán. Bí mo ṣe máa ń ṣe, mo tún lọ gbàdúrà lórí igi ràgàjì mi. Jèhófà lo alàgbà yìí láti dáhùn àdúrà mi torí ó sọ fún mi pé ki ń ka ohun tó wà ní nínú Oníwàásù 5:​4, tó sọ pé: ‘Nígbàkigbà tí o bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Ọlọ́run, san án.’ Mo ti jẹ́jẹ̀ẹ́ pé Jèhófà ni mo máa fi gbogbo ayé mi sìn, mo wá rí i pé tí mo bá gba iṣẹ́ yìí ó máa ba àjọṣe èmi àti Jèhófà jẹ́. Bí mo ṣe pinnu láti má ṣe gba iṣẹ́ náà nìyẹn o.

 “Pẹ̀lú gbogbo ohun tójú mi rí nígbà tí mo ṣì kéré, mo dúpẹ́ pé ẹ̀mí mi ò bá a lọ. Ní báyìí mo ti ṣègbéyàwó. Èmi àti Jaser ọkọ mí ati Connor ọmọ wá tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án ń láyọ̀. Alàgbà ni ọkọ mi, akéde tí ò tíì ṣèrìbọmi sì ní Connor ọmọ wa. Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) báyìí tí mo ti wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòóko kíkún.

 “Gbogbo ìgbà ni mo máa ń rántí bí mo ṣe máa ń tú ọkàn mi jádé sí Jèhófà lórí igi ràgàjì tó wà nínú ìgbo tó wà lẹ́yin ilé wa. Mo bẹ Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà ìyanu. Ó fún mi lókún, ó tù mí nínú, ó sì tọ́ mi sọ́nà. Léraléra ni Jèhófà ti jọ mí lójú nígbèésì ayé mi, ó sì ti jẹ́ kí ń rí i pé Baba tó ju baba lọ lòun. Mo dúpẹ́, ayọ̀ mi sì kún pé Jèhófà ni mo pinnu láti fayé mi sìn. Ìpinnu tó dáa jù lọ tí mo ṣe nìyẹn.”