Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ìpàtẹ Bíbélì Tó Ń Fògo fún Orúkọ Jèhófà

Ìpàtẹ Bíbélì Tó Ń Fògo fún Orúkọ Jèhófà

Látìgbà tá a ti ṣí ibi ìpàtẹ Bíbélì sí oríléeṣẹ́ wa ní ọdún 2013, ọ̀pọ̀ Bíbélì tó ṣọ̀wọ́n tó sì ṣeyebíye la ti rí gbà ká lè fi kún àwọn èyí tá a pàtẹ. Lára àwọn Bíbélì tá a rí gbà ni Complutensian Polyglot, ẹ̀dà Bíbélì King James tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀ jáde àti ìtumọ̀ “Májẹ̀mú Tuntun” lédè Gíríìkì tí Erasmus ṣe tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀ jáde.