Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JW LANGUAGE

Ìrànlọ́wọ́ Lórí Android

Ìrànlọ́wọ́ Lórí Android

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ètò ìṣiṣẹ́ JW Language láti máa fi ran àwọn tó ń kọ́ èdè lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ gbọ́ èdè náà, kí wọ́n sì lè lò ó lóde ìwàásù àti nínú ìjọ.

 

Ohun Tuntun Tó Wà ní Version 2.5

  • Ìsọ̀rí Grammar: Wo bí oríṣiríṣi ọ̀rọ̀ ṣe máa ń pinnu bó o ṣe máa hun ọ̀rọ̀, kó o lè mọ òfin ẹ̀hun gbólóhùn nínú èdè tó ò ń kọ́. Yí àwọn ọ̀rọ̀ inú gbólóhùn kan pa dà láti ọ̀rọ̀ ẹlẹ́ni kan sí ẹlẹ́ni púpọ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Jọ̀ọ́ Fi Sọ́kàn Pé:

  • Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, kọ̀ǹpútà ò ní lè fi álífábẹ́ẹ̀tì òde òní kọ ọ̀rọ̀ lábẹ́ ìsọ̀rí Grammar.

  • Ohun tó o ti ṣe ní apá text-to-speech lórí fóònù ẹ ló máa pinnu bí àtẹ́tísí tó wà lábẹ́ Grammar ṣe máa rí, torí náà, o lè ṣètò bó o ṣe fẹ́ kí èdè àti àtẹ́tísí rí lórí fóònù ẹ.

  • Ìsọ̀rí Grammar ò tíì sí ní èdè Arabic àti Low German.

 

NÍ APÁ YÌÍ

Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Máa Ń Béèrè​—JW Language (Lórí Android)

Wo ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tí àwọn èèyàn sábà máa ń béèrè.