Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

SEPTEMBER 19, 2019
GABON

Àkànṣe Ìwàásù Lórílẹ̀-Èdè Gabon

Àkànṣe Ìwàásù Lórílẹ̀-Èdè Gabon

Láti lè dé àwọn ìpínlẹ̀ tí a kì í sábà wàásù dé lórílẹ̀-èdè Gabon, ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Cameroon ṣètò ìwàásù àkànṣe bẹ̀rẹ̀ láti June 1 sí August 31, 2019. Àfojúsùn náà jẹ́ láti wàásù dé ọ̀dọ́ àwọn tó ń gbé làwọn ìlú ńlá mẹ́wàá tí èrò pọ̀ sí jùlọ, ìyẹn Franceville, Koulamoutou, Lambaréné, Libreville, Makokou, Moanda, Mouila, Oyem, Port-Gentil, àti Tchibanga. Àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ló wá láti orílẹ̀-èdè Belgium, Kánádà, France, àti Amẹ́ríkà kí wọ́n lè ti iṣẹ́ ìwàásù yìí lẹ́yìn.

Àwọn tó lé ní mílíọ̀nù méjì ló ń gbé lórílẹ̀-èdè Gabon. Àwọn tó tó ìdá mẹ́jọ nínú mẹ́wàá ló ń sọ èdè Faransé tó jẹ́ èdè àjùmọ̀lò, tí ìdá mẹ́ta nínú mẹ́wàá sì lè sọ èdè Fang tó jẹ́ èdè ìbílẹ̀ wọn. Torí náà, èdè méjèjì la lò láti wàásù.

Ẹnìkan tó ń sọ èdè Fang, tó nífẹ̀ẹ́ Bíbélì, tó sì ń gbé lágbègbè Bissegue nílùú Libreville sọ pé: “Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí màá gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lédè mi!”

Arábìnrin kan tó kópa nínú ìwàásù náà sọ pé: “Iṣẹ́ ìwàásù yìí jẹ́ àpẹẹrẹ ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan tó wà nínú ètò Jèhófà. Àwọn arákùnrin àti arábìnrin kóni mọ́ra, wọ́n jẹ́ olùfẹ́ àlejò ṣiṣé, ọ̀làwọ́, ẹni tó ń gbéniró, tó sì ń fi ìfẹ́ tòótọ́ hàn. Ìyẹn mú mi rántí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa ìjọ tó wà ní Fílípì pé, ‘a ní èrò àti ìfẹ́ tó ṣọ̀kan, a wà níṣọ̀kan délẹ̀délẹ̀, a sì ní èrò kan náà lọ́kàn.’”—Fílípì 2:2.