Ìfihàn Èyí Tí Jòhánù Rí 5:1-14

  • Àkájọ ìwé tó ní èdìdì méje (1-5)

  • Ọ̀dọ́ Àgùntàn gba àkájọ ìwé náà (6-8)

  • Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ló yẹ kó ṣí àwọn èdìdì náà (9-14)

5  Mo sì rí àkájọ ìwé kan lọ́wọ́ ọ̀tún Ẹni tó jókòó lórí ìtẹ́ náà,+ tí wọ́n kọ̀wé sí tojú tẹ̀yìn,* tí wọ́n sì fi èdìdì méje dì pinpin.  Mo sì rí áńgẹ́lì alágbára kan tó ń fi ohùn tó rinlẹ̀ kéde pé: “Ta ló yẹ kó ṣí àkájọ ìwé náà, kó sì tú àwọn èdìdì rẹ̀?”  Àmọ́ kò sí ẹnikẹ́ni ní ọ̀run tàbí ní ayé tàbí lábẹ́ ilẹ̀ tó lè ṣí àkájọ ìwé náà tàbí wo inú rẹ̀.  Mo bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún gidigidi torí a ò rí ẹnì kankan tó yẹ láti ṣí àkájọ ìwé náà tàbí wo inú rẹ̀.  Àmọ́ ọ̀kan lára àwọn àgbààgbà náà sọ fún mi pé: “Má sunkún mọ́. Wò ó! Kìnnìún ẹ̀yà Júdà,+ gbòǹgbò+ Dáfídì,+ ti ṣẹ́gun+ kó lè ṣí àkájọ ìwé náà àti èdìdì méje rẹ̀.”  Mo sì rí ọ̀dọ́ àgùntàn+ kan tó rí bí èyí tí wọ́n ti pa,+ ó dúró ní àárín ìtẹ́ náà àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà àti ní àárín àwọn àgbààgbà náà,+ ó ní ìwo méje àti ojú méje, àwọn ojú náà sì túmọ̀ sí ẹ̀mí méje ti Ọlọ́run+ tí a ti rán jáde sí gbogbo ayé.  Ó wá síwájú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sì gba àkájọ ìwé náà lọ́wọ́ ọ̀tún Ẹni tó jókòó lórí ìtẹ́.+  Nígbà tó gbà á, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin àti àwọn àgbààgbà mẹ́rìnlélógún  + (24) náà wólẹ̀ níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní háàpù kan lọ́wọ́ àti abọ́ wúrà tí tùràrí kún inú rẹ̀. (Tùràrí náà túmọ̀ sí àdúrà àwọn ẹni mímọ́.)+  Wọ́n sì ń kọ orin tuntun+ kan pé: “Ìwọ ló yẹ kó gba àkájọ ìwé náà, kí o sì ṣí àwọn èdìdì rẹ̀, torí pé wọ́n pa ọ́, o sì fi ẹ̀jẹ̀ rẹ ra àwọn èèyàn fún Ọlọ́run+ látinú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n* àti èèyàn àti orílẹ̀-èdè,+ 10  o mú kí wọ́n di ìjọba kan+ àti àlùfáà fún Ọlọ́run wa,+ wọ́n sì máa ṣàkóso bí ọba+ lé ayé lórí.” 11  Mo rí ọ̀pọ̀ áńgẹ́lì, mo sì gbọ́ ohùn wọn, wọ́n wà yí ká ìtẹ́ náà àti àwọn ẹ̀dá alààyè àti àwọn àgbààgbà náà, iye wọn jẹ́ ẹgbẹẹgbàárùn-ún lọ́nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún* àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún,+ 12  wọ́n ń ké jáde pé: “Ọ̀dọ́ Àgùntàn tí wọ́n pa+ ló yẹ láti gba agbára àti ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti okun àti ọlá àti ògo àti ìbùkún.”+ 13  Mo gbọ́ tí gbogbo ẹ̀dá tó wà ní ọ̀run àti ayé àti lábẹ́ ilẹ̀+ àti lórí òkun àti gbogbo ohun tó wà nínú wọn, ń sọ pé: “Kí ìbùkún àti ọlá+ àti ògo àti agbára jẹ́ ti Ẹni tó jókòó sórí ìtẹ́ náà+ àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà+ títí láé àti láéláé.”+ 14  Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà ń sọ pé: “Àmín!” àwọn àgbààgbà náà wólẹ̀, wọ́n sì jọ́sìn.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Grk., “nínú àti lóde.”
Tàbí “èdè.”
Tàbí “ọ̀kẹ́ àìmọye lọ́nà ọ̀kẹ́ àìmọye.”