Ìwé Kìíní sí Àwọn Ará Tẹsalóníkà 4:1-18

  • Ìkìlọ̀ lórí ìṣekúṣe (1-8)

  • Ẹ túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara yín (9-12)

    • “Ẹ má yọjú sí ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀” (11)

  • Àwọn tó kú nínú Kristi ló máa kọ́kọ́ dìde (13-18)

4  Lákòótán, ẹ̀yin ará, bí ẹ ṣe gba ìtọ́ni lọ́dọ̀ wa nípa bó ṣe yẹ kí ẹ máa rìn kí ẹ lè ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́,+ tí ẹ sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ lóòótọ́, a fi Jésù Olúwa bẹ̀ yín, a sì tún fi rọ̀ yín pé kí ẹ túbọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.  Nítorí ẹ mọ àwọn ìtọ́ni* tí a fún yín nípasẹ̀ Jésù Olúwa.  Ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́ nìyí, pé kí ẹ jẹ́ mímọ́,+ kí ẹ sì ta kété sí ìṣekúṣe.*+  Kí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín mọ bó ṣe máa kó ara* rẹ̀ níjàánu+ nínú jíjẹ́ mímọ́  + àti nínú iyì,  kì í ṣe nínú ojúkòkòrò ìbálòpọ̀ tí kò níjàánu+ bíi ti àwọn orílẹ̀-èdè tí kò mọ Ọlọ́run.+  Kí ẹnikẹ́ni má kọjá ààlà tó yẹ, kó má sì yan arákùnrin rẹ̀ jẹ nínú ọ̀ràn yìí, torí Jèhófà* ń fìyà jẹni nítorí gbogbo àwọn nǹkan yìí, bí a ṣe sọ fún yín ṣáájú, tí a sì tún kìlọ̀ fún yín gidigidi.  Nítorí Ọlọ́run pè wá fún jíjẹ́ mímọ́, kì í ṣe fún ìwà àìmọ́.+  Torí náà, ẹni tí kò bá ka èyí sí, kì í ṣe èèyàn ni kò kà sí, Ọlọ́run+ tó ń fún yín ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀+ ni kò kà sí.  Àmọ́, ní ti ìfẹ́ ará,+ ẹ kò nílò ká kọ̀wé sí yín, nítorí Ọlọ́run ti kọ́ yín láti máa nífẹ̀ẹ́ ara yín.+ 10  Kódà, ẹ̀ ń ṣe bẹ́ẹ̀ sí gbogbo àwọn ará ní gbogbo Makedóníà. Àmọ́, ẹ̀yin ará, a rọ̀ yín pé kí ẹ máa ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. 11  Ẹ fi ṣe àfojúsùn yín láti máa ṣe jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́,+ ẹ má yọjú sí ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀,+ kí ẹ máa fi ọwọ́ yín ṣiṣẹ́,+ bí a ṣe sọ fún yín, 12  kí ẹ lè máa rìn lọ́nà tó bójú mu lójú àwọn tó wà níta,+ kí ẹ má sì ṣe aláìní ohunkóhun. 13  Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀yin ará, a fẹ́ kí ẹ mọ̀* nípa àwọn tó ń sùn nínú ikú,+ kí ẹ má bàa banú jẹ́ bí àwọn tí kò ní ìrètí ṣe máa ń ṣe.+ 14  Nítorí tí a bá nígbàgbọ́ pé Jésù kú, ó sì jí dìde,+ lọ́nà kan náà, Ọlọ́run yóò mú àwọn tó ti sùn nínú ikú nítorí Jésù wá sí ìyè pẹ̀lú rẹ̀.+ 15  Nítorí ohun tí a sọ fún yín nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Jèhófà* nìyí, pé àwa alààyè tí a bá kù nílẹ̀ di ìgbà tí Olúwa bá wà níhìn-ín kò ní ṣáájú àwọn tó ti sùn nínú ikú lọ́nàkọnà; 16  nítorí Olúwa fúnra rẹ̀ yóò sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run pẹ̀lú ìpè àṣẹ, pẹ̀lú ohùn olú áńgẹ́lì+ àti pẹ̀lú kàkàkí Ọlọ́run, àwọn tó ti kú nínú Kristi ló sì máa kọ́kọ́ dìde.+ 17  Lẹ́yìn náà, àwa alààyè tí a kù nílẹ̀ ni a ó gbà lọ pẹ̀lú wọn nínú àwọsánmà+ láti pàdé Olúwa+ nínú afẹ́fẹ́; a ó sì tipa báyìí máa wà pẹ̀lú Olúwa nígbà gbogbo.+ 18  Nítorí náà, ẹ máa fi àwọn ọ̀rọ̀ yìí tu ara yín nínú.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “àwọn àṣẹ.”
Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Grk., “ohun èlò.”
Tàbí “a ò fẹ́ kí ẹ ṣaláìmọ̀.”