Àkọsílẹ̀ Lúùkù 1:1-80

  • Ó kọ̀wé sí Tìófílọ́sì (1-4)

  • Gébúrẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa bí Jòhánù Arinibọmi (5-25)

  • Gébúrẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa bí Jésù (26-38)

  • Màríà lọ kí Èlísábẹ́tì (39-45)

  • Màríà gbé Jèhófà ga (46-56)

  • Wọ́n bí Jòhánù, wọ́n sì sọ ọ́ lórúkọ (57-66)

  • Sekaráyà sọ tẹ́lẹ̀ (67-80)

1  Bó ṣe jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ti gbìyànjú láti kó ìròyìn àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ jọ, èyí tí a gbà gbọ́* délẹ̀délẹ̀ láàárín wa,+  bí àwọn tí ọ̀rọ̀ náà ṣojú wọn láti ìbẹ̀rẹ̀,+ tí wọ́n sì jẹ́ ìránṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà ṣe fi àwọn nǹkan yìí lé wa lọ́wọ́,+  èmi náà pinnu, torí mo ti wádìí ohun gbogbo láti ìbẹ̀rẹ̀ lọ́nà tó péye, pé kí n kọ ọ́ ránṣẹ́ sí ọ lẹ́sẹẹsẹ, ìwọ Tìófílọ́sì+ ọlọ́lá jù lọ,  kí o lè mọ bí àwọn ohun tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ ẹnu kọ́ ọ ṣe jẹ́ òótọ́ tó ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.+  Láyé ìgbà Hẹ́rọ́dù,*+ ọba Jùdíà, àlùfáà kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sekaráyà nínú ìpín Ábíjà.+ Ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin Áárónì ni ìyàwó rẹ̀, Èlísábẹ́tì ni orúkọ rẹ̀.  Àwọn méjèèjì jẹ́ olódodo níwájú Ọlọ́run, wọ́n sì ń rìn láìlẹ́bi ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo àṣẹ àti àwọn ohun tí òfin Jèhófà* béèrè.  Àmọ́ wọn ò ní ọmọ, torí Èlísábẹ́tì yàgàn, àwọn méjèèjì sì ti lọ́jọ́ lórí gan-an.  Bó ṣe ń ṣiṣẹ́ àlùfáà nínú iṣẹ́ tí a yàn fún ìpín rẹ̀+ níwájú Ọlọ́run,  gẹ́gẹ́ bí àṣà àwọn àlùfáà,* òun ló kàn láti sun tùràrí+ nígbà tó wọnú ibi mímọ́ Jèhófà.*+ 10  Gbogbo èrò tó pọ̀ rẹpẹtẹ sì ń gbàdúrà níta ní wákàtí tí wọ́n ń sun tùràrí. 11  Áńgẹ́lì Jèhófà* fara hàn án, ó dúró ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún pẹpẹ tùràrí. 12  Àmọ́ ìdààmú bá Sekaráyà nítorí ohun tó rí, ẹ̀rù sì bà á gidigidi. 13  Ṣùgbọ́n áńgẹ́lì náà sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù, Sekaráyà, torí a ti ṣojúure sí ọ, a sì ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ, Èlísábẹ́tì ìyàwó rẹ máa bí ọmọkùnrin kan fún ọ, kí o pe orúkọ rẹ̀ ní Jòhánù.+ 14  Inú rẹ máa dùn, o sì máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn máa yọ̀ nígbà tí o bá bí i,+ 15  torí ẹni ńlá ló máa jẹ́ lójú Jèhófà.*+ Àmọ́ kò gbọ́dọ̀ mu wáìnì rárá tàbí ọtí líle èyíkéyìí,+ ẹ̀mí mímọ́ sì máa kún inú rẹ̀, àní kí wọ́n tó bí i,*+ 16  ó sì máa mú kí ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà* Ọlọ́run wọn.+ 17  Bákan náà, ó máa lọ ṣáájú rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí àti agbára Èlíjà,+ kó lè yí ọkàn àwọn bàbá pa dà sí àwọn ọmọ+ àti àwọn aláìgbọràn sí ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ ti àwọn olódodo, kó lè ṣètò àwọn èèyàn tí a ti múra sílẹ̀ fún Jèhófà.”*+ 18  Sekaráyà sọ fún áńgẹ́lì náà pé: “Báwo ni màá ṣe mọ̀ pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí? Torí mo ti dàgbà, ìyàwó mi sì ti lọ́jọ́ lórí gan-an.” 19  Áńgẹ́lì náà sọ fún un pé: “Èmi ni Gébúrẹ́lì,+ tó ń dúró nítòsí, níwájú Ọlọ́run,+ a rán mi láti bá ọ sọ̀rọ̀, kí n sì kéde ìhìn rere yìí fún ọ. 20  Àmọ́ wò ó! o ò ní lè sọ̀rọ̀, wàá sì ya odi títí di ọjọ́ tí àwọn nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀, torí pé o ò gba àwọn ọ̀rọ̀ mi gbọ́, èyí tó máa ṣẹ ní àkókò tí a yàn fún wọn.” 21  Àmọ́ àwọn èèyàn ṣì ń dúró de Sekaráyà, ó sì yà wọ́n lẹ́nu pé ó pẹ́ gan-an nínú ibi mímọ́. 22  Nígbà tó jáde, kò lè bá wọn sọ̀rọ̀, wọ́n sì fòye mọ̀ pé ó ṣẹ̀ṣẹ̀ rí ohun* kan tó ju agbára ẹ̀dá lọ nínú ibi mímọ́. Ó ń fi ara ṣàpèjúwe fún wọn, síbẹ̀ kò lè sọ̀rọ̀. 23  Nígbà tí àwọn ọjọ́ tó fi ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́* pé, ó lọ sílé rẹ̀. 24  Ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, Èlísábẹ́tì ìyàwó rẹ̀ lóyún, ó sì fi ara pa mọ́ fún oṣù márùn-ún, ó sọ pé: 25  “Ohun tí Jèhófà* ṣe sí mi ní àwọn ọjọ́ yìí nìyí. Ó ti yíjú sí mi kó lè mú ẹ̀gàn mi kúrò láàárín àwọn èèyàn.”+ 26  Nígbà tó pé oṣù mẹ́fà, Ọlọ́run rán áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì+ sí ìlú kan ní Gálílì tí wọ́n ń pè ní Násárẹ́tì, 27  sí wúńdíá kan+ tó jẹ́ àfẹ́sọ́nà* ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jósẹ́fù ní ilé Dáfídì, orúkọ wúńdíá náà ni Màríà.+ 28  Nígbà tí áńgẹ́lì náà wọlé, ó sọ fún un pé: “Mo kí ọ o, ìwọ ẹni tí a ṣojúure sí gidigidi, Jèhófà* wà pẹ̀lú rẹ.” 29  Àmọ́ ọ̀rọ̀ áńgẹ́lì náà rú obìnrin náà lójú gan-an, ó sì fẹ́ mọ ohun tí irú ìkíni yìí túmọ̀ sí. 30  Áńgẹ́lì náà wá sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù, Màríà, torí o ti rí ojúure Ọlọ́run. 31  Wò ó! o máa lóyún,* o sì máa bí ọmọkùnrin kan,+ kí o pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù.+ 32  Ẹni yìí máa jẹ́ ẹni ńlá,+ wọ́n á máa pè é ní Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ,+ Jèhófà* Ọlọ́run sì máa fún un ní ìtẹ́ Dáfídì bàbá rẹ̀,+ 33  ó máa jẹ Ọba lórí ilé Jékọ́bù títí láé, Ìjọba rẹ̀ ò sì ní lópin.”+ 34  Àmọ́ Màríà sọ fún áńgẹ́lì náà pé: “Báwo ló ṣe máa ṣẹlẹ̀, nígbà tó jẹ́ pé mi ò bá ọkùnrin lò pọ̀?”+ 35  Áńgẹ́lì náà dá a lóhùn pé: “Ẹ̀mí mímọ́ máa bà lé ọ,+ agbára Ẹni Gíga Jù Lọ sì máa ṣíji bò ọ́. Ìdí nìyẹn tí a fi máa pe ẹni tí o bí ní mímọ́,+ Ọmọ Ọlọ́run.+ 36  Wò ó! Èlísábẹ́tì mọ̀lẹ́bí rẹ náà ti lóyún ọmọkùnrin kan, ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, oyún rẹ̀ sì ti pé oṣù mẹ́fà báyìí, ẹni táwọn èèyàn ń pè ní àgàn; 37  torí pé kò sí ìkéde kankan tí kò ní ṣeé ṣe* fún Ọlọ́run.”+ 38  Màríà wá sọ pé: “Wò ó! Ẹrúbìnrin Jèhófà!* Kó ṣẹlẹ̀ sí mi bí o ṣe kéde rẹ̀.” Ni áńgẹ́lì náà bá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. 39  Màríà wá gbéra ní àkókò yẹn, ó sì yára rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ olókè, sí ìlú kan ní Júdà, 40  ó wọ ilé Sekaráyà, ó sì kí Èlísábẹ́tì. 41  Ó ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Èlísábẹ́tì gbọ́ tí Màríà kí i, ọmọ inú rẹ̀ sọ, ẹ̀mí mímọ́ sì kún inú Èlísábẹ́tì, 42  ó sì ké jáde pé: “Ìbùkún ni fún ọ láàárín àwọn obìnrin, ìbùkún sì ni fún èso inú rẹ! 43  Báwo ló ṣe jẹ́ pé èmi ni àǹfààní yìí tọ́ sí, pé kí ìyá Olúwa mi wá sọ́dọ̀ mi? 44  Torí wò ó! bí mo ṣe gbọ́ tí o kí mi, ayọ̀ mú kí ọmọ tó wà ní inú mi sọ kúlú. 45  Aláyọ̀ náà ni obìnrin tó gbà gbọ́, torí pé gbogbo ohun tí a sọ fún un látọ̀dọ̀ Jèhófà* ló máa ṣẹ délẹ̀délẹ̀.” 46  Màríà wá sọ pé: “Ọkàn* mi gbé Jèhófà* ga,+ 47  ẹ̀mí mi ò sì yéé yọ̀ gidigidi torí Ọlọ́run Olùgbàlà mi,+ 48  torí pé ó ti ṣíjú wo ipò tó rẹlẹ̀ tí ẹrúbìnrin rẹ̀ wà.+ Torí, wò ó! láti ìsinsìnyí lọ, gbogbo ìran máa kéde pé aláyọ̀ ni mí,+ 49  torí pé Ẹni tó lágbára ti ṣe àwọn ohun ńláńlá fún mi, mímọ́ sì ni orúkọ rẹ̀+ 50  àti pé láti ìran dé ìran, ó ń ṣàánú àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀.+ 51  Ó ti fi apá rẹ̀ ṣe ohun tó lágbára; ó ti tú àwọn tó jẹ́ agbéraga nínú èrò ọkàn wọn ká.+ 52  Ó ti rẹ àwọn ọkùnrin alágbára sílẹ̀ látorí ìtẹ́,+ ó sì gbé àwọn tó rẹlẹ̀ ga;+ 53  ó ti fi àwọn ohun rere tẹ́ àwọn tí ebi ń pa lọ́rùn dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́,+ ó sì ti mú kí àwọn tó lọ́rọ̀ lọ lọ́wọ́ òfo. 54  Ó ti wá ran Ísírẹ́lì ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, ó rántí àánú rẹ̀,+ 55  bó ṣe sọ fún àwọn baba ńlá wa, fún Ábúráhámù àti ọmọ* rẹ̀,+ títí láé.” 56  Màríà dúró sọ́dọ̀ rẹ̀ fún nǹkan bí oṣù mẹ́ta, ó sì pa dà sí ilé rẹ̀. 57  Nígbà tí ó tó àkókò tí Èlísábẹ́tì máa bímọ, ó bí ọmọkùnrin kan. 58  Àwọn aládùúgbò àti àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ gbọ́ pé Jèhófà* ti ṣàánú rẹ̀ gidigidi, wọ́n sì bá a yọ̀.+ 59  Ní ọjọ́ kẹjọ, wọ́n wá láti dádọ̀dọ́* ọmọ kékeré náà,+ wọ́n sì fẹ́ sọ ọ́ ní Sekaráyà, orúkọ bàbá rẹ̀. 60  Àmọ́ ìyá rẹ̀ fèsì pé: “Rárá o! Jòhánù la máa pè é.” 61  Ni wọ́n bá sọ fún un pé: “Kò sí mọ̀lẹ́bí rẹ kankan tó ń jẹ́ orúkọ yìí.” 62  Torí náà, wọ́n fara ṣàpèjúwe fún bàbá rẹ̀ láti béèrè orúkọ tó fẹ́ sọ ọ́. 63  Ó wá ní kí wọ́n fún òun ní wàláà kan, ó sì kọ ọ́ pé: “Jòhánù ni orúkọ rẹ̀.”+ Ni ẹnu bá ya gbogbo wọn. 64  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹnu rẹ̀ là, ahọ́n rẹ̀ ṣí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀,+ ó ń yin Ọlọ́run. 65  Ẹ̀rù sì ba gbogbo àwọn tó ń gbé àdúgbò wọn, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í ròyìn gbogbo nǹkan yìí ní gbogbo ilẹ̀ olókè ní Jùdíà. 66  Gbogbo àwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà sì fi sọ́kàn, wọ́n ń sọ pé: “Kí ni ọmọ kékeré yìí máa dà?” Torí ọwọ́ Jèhófà* wà lára rẹ̀ lóòótọ́. 67  Ẹ̀mí mímọ́ wá kún inú Sekaráyà bàbá rẹ̀, ó sì sọ tẹ́lẹ̀, ó ní: 68  “Ẹ yin Jèhófà,* Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+ torí ó ti yíjú sí àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì ti gbà wọ́n sílẹ̀.+ 69  Ó ti gbé ìwo ìgbàlà*+ kan dìde fún wa ní ilé Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀,+ 70  bó ṣe gbẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ nígbà àtijọ́ sọ̀rọ̀,+ 71  nípa ìgbàlà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa àti lọ́wọ́ gbogbo àwọn tó kórìíra wa;+ 72  láti ṣàánú lórí ọ̀rọ̀ àwọn baba ńlá wa, kó sì rántí májẹ̀mú mímọ́ rẹ̀,+ 73  ohun tó búra fún Ábúráhámù baba ńlá wa,+ 74  pé lẹ́yìn tí a bá ti gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, òun máa fún wa ní àǹfààní láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún un láìbẹ̀rù, 75  pẹ̀lú ìdúróṣinṣin àti òdodo níwájú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ wa. 76  Àmọ́ ní tìrẹ, ọmọ kékeré, wòlíì Ẹni Gíga Jù Lọ la ó máa pè ọ́, torí o máa lọ níwájú Jèhófà* láti múra àwọn ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀,+ 77  láti fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní ìmọ̀ ìgbàlà nípa dídárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n,+ 78  torí ojú àánú Ọlọ́run wa. Pẹ̀lú àánú yìí, ojúmọ́ kan máa mọ́ wa láti ibi gíga, 79  láti fún àwọn tó jókòó nínú òkùnkùn àti òjìji ikú ní ìmọ́lẹ̀,+ kó sì darí ẹsẹ̀ wa ní ọ̀nà àlàáfíà.” 80  Ọmọ kékeré náà wá dàgbà, ó sì di alágbára nínú ẹ̀mí, ó wà ní aṣálẹ̀ títí di ọjọ́ tó fi ara rẹ̀ han Ísírẹ́lì ní gbangba.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “gbà pé ó jẹ́ òótọ́.”
Tàbí “ohun tó ti fìdí múlẹ̀ táwọn àlùfáà máa ń ṣe.”
Tàbí “látinú ilé ọlẹ̀ ìyá rẹ̀.”
Tàbí “ìran.”
Tàbí “iṣẹ́ ìsìn fún gbogbo èèyàn.”
Tàbí “wúńdíá kan tí a ṣèlérí pé ó máa fẹ́.”
Tàbí “ọlẹ̀ máa sọ nínú rẹ.”
Tàbí “ohun tí kò ṣeé ṣe.”
Tàbí “Gbogbo ara mi.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Grk., “èso.”
Tàbí “kọlà fún.”
Tàbí “olùgbàlà tó lágbára.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ìwo.”