Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Ohun Gbogbo Ṣeé Ṣe Lọ́dọ̀ Jèhófà

Ohun Gbogbo Ṣeé Ṣe Lọ́dọ̀ Jèhófà

LỌ́JỌ́ kan tí Mairambubu ìyàwó mi wà nínú bọ́ọ̀sì, ó gbọ́ tẹ́nì kan sọ pé “kò ní sí ikú mọ́, kódà àwọn tó ti kú máa jíǹde.” Ohun tó gbọ́ wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an, ó sì fẹ́ mọ̀ sí i. Torí náà, bí bọ́ọ̀sì yẹn ṣe dúró pé káwọn èèyàn bọ́lẹ̀, ṣe ló gbá tẹ̀ lé obìnrin tó sọ̀rọ̀ yẹn. Apun Mambetsadykova lorúkọ obìnrin náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ni. Nígbà yẹn, ẹni tó bá bá àwọn Ẹlẹ́rìí sọ̀rọ̀ ń fẹ̀mí ara rẹ̀ wewu ni, àmọ́ ohun tí Apun kọ́ wa ló yí ìgbésí ayé wa pa dà.

A MÁA Ń ṢIṢẸ́ BÍ AAGO

Oko kan tó wà nítòsí ìlú Tokmok lórílẹ̀-èdè Kyrgyzstan ni wọ́n bí mi sí lọ́dún 1937. Ọmọ ìbílẹ̀ Kyrgyz ni wá, èdè Kyrgyz la sì ń sọ. Iṣẹ́ oko làwọn òbí mi ń ṣe, wọ́n sì máa ń ṣiṣẹ́ látàárọ̀ ṣúlẹ̀. Ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún ni wọ́n máa ń sanwó fún wọn, àmọ́ wọ́n máa ń kó oúnjẹ fún wọn nígbà gbogbo. Kò rọrùn fún màmá mi láti tọ́jú èmi àti àbúrò mi. Torí náà, ọdún márùn-ún péré ni mo fi lọ síléèwé, lẹ́yìn náà mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ oko.

Àwọn òkè Teskey Ala-Too

Akúṣẹ̀ẹ́ ló pọ̀ jù níbi tí mo gbé dàgbà, nǹkan ò rọrùn fún wa rárá, kódà kéèyàn tó lè rọ́wọ́ mú lọ sẹ́nu àfi kó ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó. Nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́, mi ò kì í ronú nípa ìdí tí Ọlọ́run fi dá àwa èèyàn àtohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wa lọ́jọ́ iwájú. Mi ò ronú ẹ̀ rí pé màá kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àtohun tó ní lọ́kàn fún aráyé, mi ò sì mọ̀ pé ẹ̀kọ́ yẹn máa yí ìgbésí ayé mi pa dà. Ẹ jẹ́ kí n sọ bí òtítọ́ ṣe dé orílẹ̀-èdè Kyrgyzstan àti bó ṣe tàn yí ká fún yín. Ìlú ìbílẹ̀ wa lápá àríwá Kyrgyzstan ló ti bẹ̀rẹ̀.

ÀWỌN TÍ WỌ́N LÉ KÚRÒ NÍLÙÚ MÚ ÒTÍTỌ́ WÁ SÍ KYRGYZSTAN

Ọdún 1956 ni òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dé ìlú Kyrgyzstan. Àmọ́, kò rọrùn rárá torí pé ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ti gbilẹ̀ lọ́kàn àwọn èèyàn. Nígbà yẹn orílẹ̀-èdè Kyrgyzstan wà lára Union of Soviet Socialist Republics (USSR). Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní USSR ò dá sọ́rọ̀ òṣèlú. (Jòh. 18:36) Torí náà, wọ́n gbà pé ọ̀tá ìjọba ni wọ́n, wọ́n sì ń ṣe inúnibíni sí wọn gan-an. Síbẹ̀, ìyẹn ò ní kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run má gbilẹ̀ lọ́kàn àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, kò sì sóhun tí wọ́n lè ṣe láti dí iṣẹ́ náà lọ́wọ́. Èyí jẹ́ kí n kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì kan pé, kò sóhun tí Jèhófà ò lè ṣe.​—Máàkù 10:27.

Emil Yantzen

Inúnibíni tí wọ́n ṣe sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló jẹ́ kí òtítọ́ gbilẹ̀ lórílẹ̀-èdè yẹn. Kí nìdí tí mo fi sọ bẹ́ẹ̀? Ilẹ̀ Siberia wà lára ibi tí USSR ń ṣàkóso, àwọn tí wọ́n bá kà sí ọ̀tá ìlú ni wọ́n máa ń kó lọ síbẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n dá wọn sílẹ̀, ọ̀pọ̀ lára wọn wá sí Kyrgyzstan, àwọn kan nínú wọn ló sì mú òtítọ́ wá síbẹ̀. Ọ̀kan lára wọn ni Emil Yantzen, ọdún 1919 ni wọ́n bí i ní Kyrgyzstan. Inú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ kan tí wọ́n fi sí ló ti pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ kó tó pa dà wálé lọ́dún 1956. Ìtòsí ìlú Sokuluk ni Emil ń gbé, ibẹ̀ ò sì jìnnà sílùú wa. Sokuluk ni wọ́n ti dá ìjọ àkọ́kọ́ sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè Kyrgyzstan lọ́dún 1958.

Victor Vinter

Ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà, Arákùnrin Victor Vinter kó wá sí Sokuluk. Léraléra ni arákùnrin yìí fara da onírúurú inúnibíni. Ẹ̀ẹ̀mejì ni wọ́n rán an lọ sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́ta torí pé kò wọṣẹ́ ológun, ẹ̀yìn náà ni wọ́n tún rán an lọ sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́wàá. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n rán an lọ sí Siberia, ó sì lo ọdún márùn-ún míì níbẹ̀. Láìka gbogbo inúnibíni yìí sí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣì ń wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN DÉ Ọ̀DỌ̀ WA

Eduard Varter

Nígbà tó dọdún 1963, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Kyrgyzstan ti tó ọgọ́jọ [160], orílẹ̀-èdè Jámánì, Ukraine àti Rọ́ṣíà ni wọ́n sì ti wá. Ọ̀kan lára wọn ni Arákùnrin Eduard Varter. Ọdún 1924 ló ṣèrìbọmi ní Jámánì, ó sì wà lára àwọn tí wọ́n rán lọ sí Siberia. Láwọn ọdún 1940, ìjọba Násì rán an lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, ìjọba Kọ́múníìsì ní USSR rán Eduard lọ sí Siberia, síbẹ̀ arákùnrin yìí di ìdúróṣinṣin rẹ̀ mú. Lọ́dún 1961, ó wá sílùú Kant, ibẹ̀ ò sì jìnnà sílùú wa rárá.

Elizabeth Fot; Aksamai Sultanalieva

Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Elizabeth Fot tóun náà jẹ́ olóòótọ́ ń gbé nílùú Kant. Iṣẹ́ aṣọ rírán ló ń ṣe, ó sì mọṣẹ́ gan-an. Torí náà àwọn dókítà àtàwọn olùkọ́ máa ń gbéṣẹ́ fún un títí kan àwọn ọ̀gá ilé iṣẹ́. Ọ̀kan lára àwọn tó ń gbéṣẹ́ fún un ni Aksamai Sultanalieva, ìyẹn ìyàwó ọ̀kan lára àwọn ọ̀gá ní ọ́fíìsì ìjọba. Nígbà kan tí Aksamai gbé iṣẹ́ wá sọ́dọ̀ Elizabeth, ó bi í lóríṣiríṣi ìbéèrè nípa ìdí tí Ọlọ́run fi dá àwa èèyàn àtohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú. Elizabeth dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀ látinú Bíbélì, bí Aksamai ṣe di Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń fìtara wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìyẹn.

Nikolai Chimpoesh

Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn, Arákùnrin Nikolai Chimpoesh tó wá láti orílẹ̀-èdè Moldova di alábòójútó àyíká, nǹkan bí ọgbọ̀n [30] ọdún ló sì fi ṣiṣẹ́ yìí. Bí Arákùnrin Nikolai ṣe ń bẹ àwọn ìjọ wò ló tún ń ṣètò bá a ṣe ń ṣe ẹ̀dà àwọn ìwé wa àti bá a ṣe ń pín in kiri, àwọn aláṣẹ náà sì ń rí gbogbo ohun tó ń ṣe. Torí náà Arákùnrin Eduard Varter gba Nikolai nímọ̀ràn pé: “Táwọn aláṣẹ bá bi ẹ́ pé báwo lẹ ṣe ń ráwọn ìwé yín, sọ fún wọn pé oríléeṣẹ́ wa ní Brooklyn làwọn ìwé náà ti ń wá. Má bẹ̀rù, ṣe ni kó o ṣọkàn akin. Má jẹ́ káwọn ọlọ́pàá KGB kó ẹ láyà jẹ.”​—Mát. 10:19.

Kò pẹ́ sígbà yẹn làwọn ọlọ́pàá KGB pe Nikolai wá sí oríléeṣẹ́ wọn nílùú Kant. Arákùnrin Nikolai sọ pé: “Nígbà tẹ́ni tó ń fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò bi mí pé báwo la ṣe ń rí àwọn ìwé wa, mo sọ fún un pé Brooklyn ni wọ́n ti ń wá. Ṣe ló dákẹ́ lọ gbári, kò mọ ohun tó máa sọ mọ́. Ló bá ní kí n máa lọ, kò sì tún pè mí mọ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn.” Báwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó nígboyà yìí ṣe ń fọgbọ́n wàásù jákèjádò apá àríwá orílẹ̀-èdè Kyrgyzstan nìyẹn. Ọdún 1981 la kọ́kọ́ gbọ́ ìhìn rere nípa Jèhófà ní ìdílé wa, ìyàwó mi Mairambubu ló sì kọ́kọ́ gbọ́ ọ.

ÌYÀWÓ MI MỌ̀ PÉ ÒUN TI RÍ ÒTÍTỌ́

Naryn Region lórílẹ̀-èdè Kyrgyzstan ni Mairambubu ti wá. Lọ́jọ́ kan ní August 1974, ó wá kí àbúrò mi obìnrin nílé, ibẹ̀ la sì ti pàdé. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí mo fojú kàn án ni mo ti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ débi pé ọjọ́ yẹn gangan la ṣègbéyàwó.

Apun Mambetsadykova

Lọ́jọ́ kan tí Mairambubu wà nínú bọ́ọ̀sì tó ń lọ sọ́jà, ìyẹn ní January 1981 ló gbọ́ tí obìnrin kan sọ ọ̀rọ̀ tí mo sọ níbẹ̀rẹ̀. Ohun tó gbọ́ wọ̀ ọ́ lọ́kàn, ó sì fẹ́ gbọ́ sí i, torí náà, ó ní kí obìnrin yẹn sọ orúkọ àti àdírẹ́sì rẹ̀ fún òun. Obìnrin yẹn ní Apun lorúkọ òun, àmọ́ kò fún un ní àdírẹ́sì rẹ̀, torí pé lásìkò yẹn ìjọba fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Torí náà, àdírẹ́sì wa ló gbà dípò kó fún ìyàwó mi ní tiẹ̀. Ṣe ni inú ìyàwó mi ń dùn ṣìnkìn nígbà tó délé.

Mairambubu sọ fún mi pé: “Àwọn nǹkan tí mo gbọ́ múnú mi dùn gan-an. Obìnrin kan sọ fún mi pé láìpẹ́, àwọn èèyàn ò ní kú mọ́. Kódà, àwọn ẹranko ẹhànnà ò ní pani lára mọ́.” Ṣe lohun tó sọ yẹn dà bí àlá tí ò lè ṣẹ. Mo wá sọ fún ìyàwó mi pé: “Jẹ́ kó dé ná, ká gbọ́ àlàyé tó máa ṣe nípa rẹ̀.”

Oṣù mẹ́ta lẹ́yìn ìgbà yẹn ni Apun wá sọ́dọ̀ wa. Lẹ́yìn ìyẹn, òun àtàwọn ará míì máa ń wá sọ́dọ̀ wa, èyí ló sì jẹ́ ká mọ àwọn èèyàn Kyrgyz tó kọ́kọ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn ará yìí ló kọ́ wa nípa Jèhófà àtohun tó ní lọ́kàn láti ṣe fáráyé. Wọ́n fi ìwé Lati Paradise T’a Sọnu Si Paradise T’a Jere-Pada kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. * Ẹ̀dà ìwé yìí kan ṣoṣo ló wà nílùú Tokmok, torí náà, ṣe la fọwọ́ dà á kọ síbòmíì káwa náà lè ní ẹ̀dà tiwa.

Ọ̀kan lára àwọn ohun tá a kọ́kọ́ kọ́ ni ohun tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:​15, a kẹ́kọ̀ọ́ pé Jésù ló máa mú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣẹ, torí òun ni Ọlọ́run yàn láti jẹ́ ọba Ìjọba Ọlọ́run. A rí i pé ìròyìn tí gbogbo èèyàn gbọ́dọ̀ gbọ́ ni! A wá túbọ̀ rí ìdí tó fi yẹ ká dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń wàásù ìhìn rere náà. (Mát. 24:14) Kò pẹ́ kò jìnnà, àwọn nǹkan tá à ń kọ́ nínú Bíbélì ti ń yí ìgbésí ayé wa pa dà.

BÁ A ṢE Ń ṢÈPÀDÉ NÍGBÀ TÍ WỌ́N FÒFIN DÈ WÁ

Arákùnrin kan tó wà nílùú Tokmok pè wá síbi ìgbéyàwó kan. Nígbà tá a débẹ̀, èmi àtìyàwó mi rí i pé ìwà àwọn Ẹlẹ́rìí yàtọ̀ pátápátá. Kò sí ọtí níbi ìgbéyàwó yẹn, gbogbo ohun tí wọ́n ṣe lọ́jọ́ yẹn ló wà létòlétò. Ohun tá a rí níbẹ̀ yàtọ̀ pátápátá sóhun tá a máa ń rí láwọn ìgbéyàwó míì níbi táwọn èèyàn ti máa ń mutí para, tí wọ́n máa ń hùwàkiwà, tí wọ́n sì máa ń bú ara wọn.

A tún lọ sáwọn ìpàdé ìjọ kan ní Tokmok. Àwọn ọlọ́pàá máa ń ṣọ́ wa, torí náà inú igbó la ti máa ń ṣèpàdé tí ojú ọjọ́ bá dáa, àwọn arákùnrin kan sì máa ń ṣọ́nà tá a bá ń ṣèpàdé. Àmọ́ tó bá di àsìkò òtútù, inú ilé la ti máa ń pàdé. Nígbà míì, àwọn ọlọ́pàá máa ń wá síbi tá a ti ń ṣèpàdé, wọ́n á sì ní àfi dandan káwọn mọ nǹkan tá à ń ṣe. Nígbà témi àti Mairambubu ṣèrìbọmi ní July 1982 nínú odò Chüy River, ṣe la fọgbọ́n ṣe é. (Mát. 10:16) Ọ̀kọ̀ọ̀kan làwọn ará ń dé sínú igbó yẹn kí wọ́n má bàa fu ẹnikẹ́ni lára. A kọ orin Ìjọba Ọlọ́run, a sì tẹ́tí sí àsọyé ìrìbọmi.

A MÚ KÍ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ WA GBÒÒRÒ SÍ I

Lọ́dún 1987, arákùnrin kan ní kí n lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹnì kan tó fìfẹ́ hàn àmọ́ tó ń gbé nílùú Balykchy. Wákàtí mẹ́rin la máa lò nínú ọkọ̀ ojú irin ká tó lè débẹ̀. Lẹ́yìn tá a wàásù níbẹ̀ léraléra, a rí i pé ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbébẹ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. A sì gbà pé ọ̀nà kan tá a lè gbà mú kí iṣẹ́ ìwàásù wa gbòòrò sí i nìyí.

Èmi àti Mairambubu máa ń rìnrìn-àjò lọ sí Balykchy gan-an. Ibẹ̀ la sábà máa ń wà ní òpin ọ̀sẹ̀, a máa ń lọ sóde ẹ̀rí, a sì máa ń darí ìpàdé níbẹ̀. Àwọn èèyàn púpọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè fáwọn ìwé wa. Àpò mishok tí wọ́n fi máa ń kó ọ̀dùnkún la fi ń kó àwọn ìwé wa láti Tokmok. Torí pé gbogbo wọn ló fẹ́ gbàwé, tipátipá ni ìwé tó kún inú àpò méjì fi máa ń tó wa lò fún oṣù kan. Kódà, a tún máa ń wàásù nínú ọkọ̀ ojú irin, tá a bá ń lọ àti nígbà tá a bá ń padà bọ̀.

Ọdún mẹ́jọ lẹ́yìn tá a kọ́kọ́ ṣèbẹ̀wò sílùú Balykchy, ìyẹn lọ́dún 1995, a dá ìjọ tuntun kan sílẹ̀ níbẹ̀. Owó kékeré kọ́ la máa ń ná ní gbogbo ọdún tá a fi ń lọ sí Balykchy láti Tokmok. A ò lówó lọ́wọ́, àmọ́ kí ló ràn wá lọ́wọ́? Arákùnrin kan máa ń fún wa lówó nígbà gbogbo ká lè rí nǹkan fi gbéra. Jèhófà rí i pé ó wù wá pé ká mú iṣẹ́ ìwàásù wa gbòòrò sí i, torí náà, ó ṣí àwọn “ibodè ibú omi ọ̀run” fún wa. (Mál. 3:10) Ó dájú pé kò sí nǹkan tí Jèhófà ò lè ṣe!

ỌWỌ́ WA DÍ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ ÀTI BÍBÓJÚTÓ ÀWỌN ỌMỌ WA

Ọdún 1992 ni mo di alàgbà, èmi sì ni ọmọ ìbílẹ̀ Kyrgyz tó kọ́kọ́ di alàgbà lórílẹ̀-èdè wa. Ní ìjọ wa ní Tokmok, a tún rí àwọn ọ̀nà míì tá a lè gbà mú káwọn èèyàn gbọ́ nípa ìjọba Ọlọ́run. A máa ń kọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ iléèwé lẹ́kọ̀ọ́. Ọ̀kan lára àwọn tá a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ nígbà yẹn ti di ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka báyìí, àwọn méjì míì lára wọn sì ti di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. A tún máa ń ran àwọn ará ìjọ wa lọ́wọ́. Láàárín ọdún 1990 sí 1994, àwọn ìwé tó wà lédè Rọ́ṣíà là ń lò, èdè yẹn náà la sì fi ń ṣèpàdé. Àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn tó ń wá sípàdé ló jẹ́ pé èdè Kyrgyz tó jẹ́ èdè ìbílẹ̀ wọn ni wọ́n lóye jù. Torí náà, mo máa ń túmọ̀ ohun tí wọ́n ń sọ nípàdé fún wọn, ìyẹn sì jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ lóye òtítọ́.

Èmi àtìyàwó mi pẹ̀lú mẹ́jọ lára àwọn ọmọ wa lọ́dún 1989

Yàtọ̀ síyẹn, èmi àti Mairambubu tún láwọn ọmọ tá à ń tọ́, torí náà ọwọ́ wa dí gan-an. A máa ń kó wọn lọ sípàdé, a sì máa ń mú wọn dání tá a bá ń lọ sóde ẹ̀rí. Nígbà tí ọmọ wa obìnrin tó ń jẹ́ Gulsayra wà lọ́mọ ọdún méjìlá, ó gbádùn kó máa bá àwọn tó ń kọjá sọ̀rọ̀ Bíbélì. Àwọn ọmọ wa sì fẹ́ràn kí wọ́n máa há àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ sórí. Bá a ṣe ń kọ́ wọn yìí jẹ́ kí wọ́n nítara fún ìjọsìn Ọlọ́run gan-an. Kódà, nínú àwọn ọmọ mẹ́sàn-án tá a bí àtàwọn ọmọ-ọmọ mọ́kànlá tá a ní, mẹ́rìndínlógún [16] ló ń sin Jèhófà tàbí kí wọ́n máa tẹ̀ lé àwọn òbí wọn lọ sípàdé.

ÀWỌN ÀYÍPADÀ ÀGBÀYANU

Ẹnu máa ya àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó mú ìhìn rere wá sí àgbègbè wa láwọn ọdún 1950 tí wọ́n bá rí àwọn àyípadà tó ti wáyé. Bí àpẹẹrẹ, láti ọdún 1990 la ti túbọ̀ ní òmìnira láti wàásù ká sì kóra jọ fáwọn àpéjọ wa.

Èmi àtìyàwó mi lóde ẹ̀rí

Lọ́dún 1991, èmi àtìyàwó mi lọ sí àpéjọ àgbègbè fúngbà àkọ́kọ́ ní Alma-Ata, [Almaty ni wọ́n ń pe ibẹ̀ báyìí] lórílẹ̀-èdè Kazakhstan. Nígbà tó dọdún 1993, àwọn ará ní Kyrgyzstan ṣe àpéjọ àgbègbè fúngbà àkọ́kọ́ ní pápá ìṣeré Spartak Stadium nílùú Bishkek. Ọ̀sẹ̀ kan gbáko làwọn ará fi tún ibẹ̀ ṣe kí àpéjọ náà tó bẹ̀rẹ̀. Nígbà tí alábòójútó pápá ìṣeré yẹn rí ohun tí wọ́n ṣe, inú rẹ̀ dùn débi pé kò gba owó kankan lọ́wọ́ wa.

Nígbà tó dọdún 1994, ohun àgbàyanu míì tún ṣẹlẹ̀. Ètò Ọlọ́run tẹ ìwé kan jáde lédè Kyrgyz. Ní báyìí, àwùjọ àwọn atúmọ̀ èdè kan ti wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa nílùú Bishkek tó ń tú àwọn ìwé wa sí èdè Kyrgyz. Yàtọ̀ síyẹn lọ́dún 1998, ìjọba gbà wá láyè láti fi orúkọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ lábẹ́ òfin ní Kyrgyzstan. Ètò Jèhófà ti gbòòrò gan-an, a sì ti ní àwọn akéde tó lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000]. Ní báyìí, a ti ní ìjọ mẹ́tàlélọ́gọ́rin [83] àti àwùjọ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25]. Àwọn kan nínú wọn ń ṣèpàdé lédè Chinese, Gẹ̀ẹ́sì, Kyrgyz, Russian, Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Rọ́ṣíà, èdè Turkish, Uighur àti Uzbek. Gbogbo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin yìí ló ń sin Jèhófà níṣọ̀kan. Jèhófà ló jẹ́ kí gbogbo àyípadà àgbàyanu yìí wáyé.

Ju gbogbo ẹ̀ lọ, Jèhófà yí ìgbésí ayé mi pa dà. Ìdílé àgbẹ̀ tí kò rí jájẹ ni mo ti wá, ọdún márùn-ún péré sì ni mo fi lọ sílé ìwé. Síbẹ̀, Jèhófà mú kí n di alábòójútó nínú ìjọ, ó tún mú kó ṣeé ṣe fún mi láti kọ́ àwọn tó kàwé jù mí lọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó ṣe kedere pé Jèhófà máa ń ṣe àwọn ohun àgbàyanu. Àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe nígbèésí ayé mi ti jẹ́ kí n pinnu pé mi ò ní yé sọ̀rọ̀ rẹ̀ fáwọn èèyàn, màá sì jẹ́ olóòótọ́ sí i torí pé “ohun gbogbo ṣeé ṣe” lọ́dọ̀ rẹ̀.​—Mát. 19:26.

^ ìpínrọ̀ 21 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é, àmọ́ a ò tẹ̀ ẹ́ mọ́ báyìí.