Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn ilé tí wọ́n kọ́ bí àgọ́ ló wà ní Àfonífojì Tash Rabat

ILẸ̀ ÀTI ÀWỌN ÈÈYÀN

Ìbẹ̀wò sí Orílẹ̀-èdè Kyrgyzstan

Ìbẹ̀wò sí Orílẹ̀-èdè Kyrgyzstan

ÀWỌN òkè ńlá-ńlá tí yìnyín bò pọ̀ lórílẹ̀-èdè Kyrgyzstan. Àárín gbùngbùn ilẹ̀ Éṣíà ni orílẹ̀-èdè yìí wà. Ó pààlà pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Kazakhstan, Uzbekistan, Tajikistan, àti Ṣáínà. Òkè ló pọ̀ jù ní orílẹ̀-èdè náà. Apá ibi tí òkè Tian Shan ti ga jù ni orílẹ̀-èdè Kyrgyzstan yìí. Òkè náà ga tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje ààbọ̀ mítà (7,439 m). Igbó kìjikìji sì bo apá kan ilẹ̀ náà. Ibẹ̀ ni oko àsálà tó fẹ̀ jù ní àgbáyé wà.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lórílẹ̀-èdè Kyrgyzstan

Àwọn èèyàn ibẹ̀ fẹ́ràn àlejò, wọ́n sì máa ń bọ̀wọ̀ fúnni. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé wọ́n máa ń dìde fún àgbàlagbà láti jókòó nínú bọ́ọ̀sì tàbí kí wọ́n fún wọn ní àga tó lọ́lá jù níbi táwọn èèyàn jókòó sí.

Ìdílé kọ̀ọ̀kan lè ní ọmọ mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àbígbẹ̀yìn ọkùnrin ló máa ń dúró ti àwọn òbí nílé láti máa tọ́jú wọn títí dọjọ́ alẹ́, kódà tó bá ti fẹ́ ìyàwó pàápàá.

Láti kékeré ni wọ́n ti máa ń kọ́ àwọn ọmọbìnrin wọn ní ẹ̀kọ́ ilé tó máa jẹ́ kí wọ́n di aya rere lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ. Tí wọ́n bá fi máa pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16], wọ́n á ti lè dá bójú tó ilé. Wọ́n sábà máa ń ṣètò ẹ̀rù tí ìyàwó máa kó lọ ilé ọkọ. Lára rẹ̀ ni nǹkan ọ̀ṣọ́ tí wọ́n ń tẹ́ sórí bẹ́ẹ̀dì, onírúurú aṣọ àti kápẹ́ẹ̀tì tí wọ́n fọwọ́ hun. Ọkọ ìyàwó sì máa ń san owó orí ìyàwó, á sì tún kó àwọn nǹkan ọ̀sìn pẹ̀lú rẹ̀.

Tí wọ́n bá ń ṣe ayẹyẹ tàbí ìsìnkú, wọ́n máa ń pa àgùntàn tàbí ẹṣin. Wọ́n á pín in sí apá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, wọ́n á sì fún kálukú ní apá tó tọ́ sí i. Ọjọ́ orí àti ipò tẹ́nì kan wà láwùjọ ló máa pinnu apá tí wọ́n máa fún un. Èyí jẹ́ ọ̀nà míì láti fi hàn pé wọ́n máa ń bọ̀wọ̀ fúnni. Lẹ́yìn náà ni wọ́n á wá fún àwọn àlejò ní oúnjẹ ìlú wọn, ìyẹn beshbarmak. Ọwọ́ ni wọ́n fi ń jẹ oúnjẹ yìí.

Komuz ni ohun èlò ìkọrin tó gbajúmọ̀ jù lọ