Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ILÉ ÌṢỌ́ No. 1 2021 | Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Gbàdúrà?

Ṣé ìgbà kan wà tó o gbàdúrà, àmọ́ tó o rò pé Ọlọ́run ò gbọ́ àdúrà rẹ? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kì í ṣèwọ nìkan, ọ̀pọ̀ èèyàn náà ló nírú èrò yìí. Ọ̀pọ̀ èèyàn ti gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ran àwọn lọ́wọ́, síbẹ̀ ìṣòro wọn ò yanjú. Ìwé yìí sọ àwọn ohun tó máa jẹ́ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run ń gbọ́ àdúrà wa. Ó tún sọ ìdí tí Ọlọ́run kì í fi dáhùn àwọn àdúrà kan àti bá a ṣe lè gbàdúrà tí Ọlọ́run á sì gbọ́ àdúrà wa.

 

Ohun Táwọn Kan Sọ Nípa Àdúrà

Ṣé ẹ̀bùn pàtàkì látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni àdúrà, àbí a kàn ń gbàdúrà lásán ni?

Ṣé Ọlọ́run Ń Gbọ́ Àdúrà Wa?

Bíbélì jẹ́ kó dá wa lójú pé tá a bá gbàdúrà lọ́nà tó tọ́, Ọlọ́run máa gbọ́ àdúrà wa.

Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Kì Í Dáhùn Àwọn Àdúrà Kan?

Bíbélì jẹ́ ká mọ irú àwọn àdúrà tí Ọlọ́run máa ń dáhùn àtàwọn tí kì í dáhùn.

Bó O Ṣe Lè Gbàdúrà Kí Ọlọ́run Sì Gbọ́

O lè gbàdúrà sí Ọlọ́run níbikíbi àti nígbàkigbà. Ó lè gbàdúrà sókè tàbí kó o gbà á sínú. Kódà, Jésù kọ́ wa ní ohun tá a lè sọ nínú àdúrà wa.

Bí Àdúrà Ṣe Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́

Báwo ni àdúrà ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro rẹ?

Ṣé Ọlọ́run Ń Gbọ́ Àdúrà Rẹ?

Bíbélì sọ pé tó o bá gbàdúrà sí Ọlọ́run ó ń gbọ́ ẹ, ó sì fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́.