Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bó O Ṣe Lè Gbàdúrà Kí Ọlọ́run Sì Gbọ́

Bó O Ṣe Lè Gbàdúrà Kí Ọlọ́run Sì Gbọ́

Jèhófà Ọlọ́run ni “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sáàmù 65:⁠2) A lè bá a sọ̀rọ̀ níbi gbogbo àti nígbà gbogbo. A lè bá a sọ̀rọ̀ nínú ọkàn wa tàbí ká sọ̀rọ̀ jáde. Jèhófà fẹ́ ká máa pe òun ní “Baba,” òun sì ni Baba tó dáa jù lọ tá a ní. (Mátíù 6:9) Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó kọ́ wa bó ṣe yẹ ká máa gbàdúrà, tí òun á sì gbọ́ wa.

GBÀDÚRÀ SÍ JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN NÍ ORÚKỌ JÉSÙ

“Tí ẹ bá béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ Baba, ó máa fún yín ní orúkọ mi.”​—Jòhánù 16:23.

Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yẹn fi hàn kedere pé Jèhófà fẹ́ ká máa gbàdúrà sí òun, kì í ṣe nípasẹ̀ ère, àwọn ẹni mímọ́, àwọn áńgẹ́lì tàbí àwọn baba ńlá tó ti kú, àmọ́ ó ní ká máa gbàdúrà ní orúkọ Jésù Kristi. Tí a bá gbàdúrà sí Ọlọ́run ní orúkọ Jésù, à ń fi hàn pé a mọyì ipa pàtàkì tí Jésù ń kó nínú ọ̀rọ̀ wa. Jésù sọ pé: “Kò sí ẹni tó ń wá sọ́dọ̀ Baba àfi nípasẹ̀ mi.”​—Jòhánù 14:6.

SỌ̀RỌ̀ LÁTỌKÀN WÁ

“Ẹ tú ọkàn yín jáde níwájú rẹ̀.”​—Sáàmù 62:8.

Tá a bá ń gbàdúrà sí Jèhófà, ó yẹ ká máa bá a sọ̀rọ̀ bí ìgbà tí ọmọ kan ń bá bàbá tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Dípò ká máa ka àdúrà jáde nínú ìwé tàbí ká máa ka àdúrà àkàsórí, ńṣe ló yẹ ká bá a sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ látọkàn wá.

GBÀDÚRÀ LỌ́NÀ TÓ BÁ ÌFẸ́ ỌLỌ́RUN MU

“Tí a bá béèrè ohunkóhun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu, ó ń gbọ́ wa.”​—1 Jòhánù 5:14.

Tá a bá wo inú Bíbélì, àá rí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run sọ pé òun máa ṣe fun wa àti ohun tó fẹ́ ká ṣe fún òun. Tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba àdúrà wa, a ní láti gbàdúrà lọ́nà “tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu.” Tá a bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, a ní láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ká lè mọ̀ ọ́n dáadáa. Tá a bá ṣe àwọn nǹkan yẹn, Ọlọ́run á tẹ́wọ́ gba àdúrà wa.

ÀWỌN NǸKAN WO LA LÈ FI SÍNÚ ÀDÚRÀ WA?

Gbàdúrà Nítorí Ohun Tó O Nílò. Tá a bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, a lè béèrè pé kó fun wa ni ohun tá a nílò lójoojúmọ́, bí oúnjẹ, aṣọ àti ibùgbé. A tún lè gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún wa ní ọgbọ́n ka lè ṣe ìpinnu tó tọ́, ká sì tún bẹ̀ ẹ́ pé kó fún wa lágbára ká lè fara da àdánwò. Ó yẹ ká gbàdúrà pé kí ìgbàgbọ́ wa lágbára, kí Ọlọ́run dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, kó sì ràn wá lọ́wọ́.​—Lúùkù 11:3, 4, 13; Jémíìsì 1:5, 17.

Gbàdúrà fún Àwọn Ẹlòmíì. Inú àwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ ọmọ wọn máa ń dùn táwọn ọmọ wọn bá fẹ́ràn ara wọn. Bàbá wa ni Jèhófà, ó sì fẹ́ káwa ọmọ rẹ̀ máa fìfẹ́ hàn sí ara wa. Bí àpẹẹrẹ, ó yẹ kí tọkọtaya máa gbàdúrà fún ara wọn, àwọn ọmọ wọn, ìdílé wọn, àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn. Jémíìsì tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ pé: “Kí ẹ sì máa gbàdúrà fún ara yín.​—Jémíìsì 5:16.

Gbàdúrà Ìdúpẹ́. Bíbélì sọ nípa Ẹlẹ́dàá wa pé: “Ó ń ṣe rere, ó ń rọ òjò fún yín láti ọ̀run, ó sì ń fún yín ní àwọn àsìkò tí irè oko ń jáde, ó ń fi oúnjẹ bọ́ yín, ó sì ń fi ayọ̀ kún ọkàn yín.” (Ìṣe 14:17) Tá a bá ń ronú nípa gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún wa, ìyẹn á mú ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Ká má gbàgbé pé, tá a bá ń pa òfin Ọlọ́run mọ́, ìyẹn ló ń fi hàn pé a moore.​—Kólósè 3:15.

NÍ SÙÚRÙ, KÓ O SÌ MÁA GBÀDÚRÀ

Nígbà míì, inú wa lè bà jẹ́ torí pé Ọlọ́run ò tètè dáhùn àdúrà tá a fòótọ́ inú gbà. Ṣé ó yẹ ká wá ronú pé Ọlọ́run ò nífẹ̀ẹ́ wa ni? Rárá! Jẹ́ ká wo àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn kan tó fi hàn pé kò yẹ ká dákẹ́ àdúrà rárá.

Ọ̀gbẹ́ni Steve tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ ìwé yìí sọ pé: “Ká sọ pé mi ò tẹra mọ́ àdúrà ni, ayé mi ì bá ti dà rú tí mi ò sì ní láyọ̀ mọ́.” Kí ló mú kó yí pa dà? Ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì kọ́ bó ṣe máa tẹra mọ́ àdúrà. Steve sọ pé: “Mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé mo láwọn ọ̀rẹ́ àtàtà tó dúró tì mí gbágbáágbá. Ayọ̀ tí mo ní ò pọ̀ tó báyìí rí.”

Ẹlòmíì tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ ni Jenny tó rò pé òun ò yẹ lẹni tí Ọlọ́run ń gbọ́ àdúrà rẹ̀? Ó sọ pé: “Nígbà tí mo ro ara mi pin pé mi ò já mọ́ nǹkan kan, mo bẹ Ọlọ́run pé kó jẹ́ kí n mọ ìdí ti mo fi nírú èrò yẹn.” Báwo ni àdúrà yẹn ṣe ràn án lọ́wọ́? “Àdúrà tí mo gbà sí Ọlọ́run ti jẹ́ kí n máa fi ojú tó tọ́ wo ara mi. Ó jẹ kí n rí i pé bí ọkàn mi tiẹ̀ ń dá mi lẹ́bi, Ọlọ́run kò dá mi lẹ́bi. Ó tún fún mi lágbára tí ò jẹ kí n sọ̀rètí nù.” Àǹfààní wo ló rí níbẹ̀? Ó sọ pé: “Àdúrà ti jẹ́ kí n túbọ̀ rí i pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run, Bàbá àti Ọ̀rẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ mi, tó sì ń bójú tó mi. Ó ṣe tán láti dúró tì mí nígbà gbogbo tèmi náà bá ń ṣe ohun tó fẹ́.”

“Bí mo ṣe ń wò ó tó ń gbádùn ayé ẹ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ aláìlera, ó jẹ́ kó dá mi lójú pé Jèhófà ti dáhùn àdúrà mi.” Ọ̀rọ̀ tí Isabel sọ nìyẹn nígbà tó rí ọmọ rẹ̀ tó ti di ọmọ ọdún mẹ́rìnlá (14) báyìí tó ń gbádùn ayé ẹ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ aláìlera

Tún wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Isabel. Nígbà tó lóyún, dókítà rẹ̀ sọ fún un pé aláàbọ̀ ara lọmọ tó máa bí. Ọkàn ẹ̀ bà jẹ́ gan-an. Àwọn kan tiẹ̀ gbà á nímọ̀ràn pé kó ṣẹ́yún náà. Isabel sọ pé: “Àníyàn gbà mí lọ́kàn gan-an, ó sì ń ṣe mí bíi pé mo fẹ́ kú.” Kí ló wá ṣe? Obìnrin náà sọ pé: “Mo gbàdúrà sí Ọlọ́run léraléra pé kó ràn mí lọ́wọ́.” Nígbà tó yá, ó bí ọmọkùnrin kan, Gerard lorúkọ ẹ̀, aláàbọ̀ ara sì ni. Ṣé Isabel mọ̀ pé Ọlọ́run dáhùn àdúrà òun? Bẹ́ẹ̀ ni. Ó mọ̀! Báwo ló ṣe mọ̀? Isabel sọ pé: “Ọmọ mi ti di ọmọ ọdún mẹ́rìnlá (14) báyìí. Bí mo ṣe ń wò ó tó ń gbádùn ayé ẹ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ aláìlera, ó jẹ́ kó dá mi lójú pé Jèhófà ti dáhùn àdúrà mi. Mo gbà pé ohun tí Jèhófà Ọlọ́run ṣe fún mi lórí ọ̀rọ̀ ọmọ yìí ni oore tó tóbi jù lọ tó ṣe fún mi.”

Ọ̀rọ̀ ìmoore tó tọkàn wá yẹn ń jẹ́ ká rántí ọ̀rọ̀ tí onísáàmù kan sọ pé: “Jèhófà, wàá gbọ́ ẹ̀bẹ̀ àwọn oníwà pẹ̀lẹ́. Wàá mú ọkàn wọn dúró ṣinṣin, wàá sì fiyè sí wọn.” (Sáàmù 10:17) Ẹ ò rí i pé ọ̀pọ̀ àǹfààní ló wà nínú kéèyàn tẹra mọ́ àdúrà!

Tá a bá wo inú Bíbélì, àá rí àwọn àdúrà tí Jésù gbà. Èyí tá a mọ̀ jù lọ ni èyí tó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Kí la rí kọ́ látinú ẹ̀?