Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Wòlíì Jẹ́ Ká Mọ Ọlọ́run

Àwọn Wòlíì Jẹ́ Ká Mọ Ọlọ́run

Nígbà àtijọ́, Ọlọ́run fi àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì rán àwọn wòlíì rẹ̀ sí aráyé. Ṣé àwọn ọ̀rọ̀ yẹn lè jẹ́ ká mọ ohun tá a máa ṣe ká lè rí ìbùkún Ọlọ́run gbà? Bẹ́ẹ̀ ni. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a lè kọ́ lára àwọn wòlíì olóòótọ́ mẹ́ta kan.

ÁBÚRÁHÁMÙ

Ọlọ́run kì í ṣojúsàájú, ó sì fẹ́ bù kún gbogbo aráyé.

Ọlọ́run ṣèlérí fún wòlíì Ábúráhámù pé “gbogbo ìdílé tó wà lórí ilẹ̀ yóò rí ìbùkún gbà nípasẹ̀ rẹ.”​—Jẹ́nẹ́sísì 12:3.

Kí la rí kọ́? Ọlọ́run fẹ́ràn wa gan-an, ó sì fẹ́ bù kún gbogbo èèyàn tó bá ń ṣègbọràn sí i, ì báà jẹ́ ọkùnrin, obìnrin tàbí ọmọdé.

MÓSÈ

Aláàánú ni Ọlọ́run, ó sì máa ń bù kún àwọn tó bá ń sapá láti mọ̀ ọ́n.

Ọlọ́run Olódùmarè fún wòlíì Mósè lágbára láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá. Síbẹ̀, Mósè bẹ Ọlọ́run pé: “Jẹ́ kí n mọ àwọn ọ̀nà rẹ, kí n lè mọ̀ ọ́, kí n sì túbọ̀ máa rí ojú rere rẹ.” (Ẹ́kísódù 33:13) Inú Ọlọ́run dùn sí ohun tí Mósè béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì jẹ́ kó ní ìmọ̀ àti òye nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀, ìwà rẹ̀ àti ìṣe rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Mósè kẹ́kọ̀ọ́ pé Ẹlẹ́dàá jẹ́ “Ọlọ́run aláàánú, tó ń gba tẹni rò.”​—Ẹ́kísódù 34:​6, 7.

Kí la rí kọ́? Tá a bá ń sapá láti túbọ̀ mọ Ọlọ́run, ó máa bù kún wa, lọ́kùnrin, lóbìnrin àti lọ́mọdé. Nínú Ìwé Mímọ́, ó sọ bá a ṣe máa jọ́sìn òun, ó sì jẹ́ ká mọ̀ pé òun ṣe tán láti ṣe ojú rere sí wa, òun sì máa bù kún wa.

JÉSÙ

Jésù wo onírúurú àìsàn torí pé ó jẹ́ aláàánú

Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù, ohun tó ṣe àti ohun tó kọ́ wa, Ọlọ́run máa bù kún wa títí láé.

Ìwé Mímọ́ sọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa ìgbésí ayé Jésù àti ohun tó kọ́ wa. Ọlọ́run fún Jésù lágbára láti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu ńlá, bí àpẹẹrẹ, ó la ojú afọ́jú, ó la etí adití, ó sì mú arọ lára dá. Kódà, ó tún jí òkú dìde. Jésù jẹ́ ká rí díẹ̀ lára àwọn ohun rere tí Ọlọ́run máa ṣe fún aráyé lọ́jọ́ iwájú. Ó ṣàlàyé ohun tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ gbádùn àwọn ohun rere yìí, ó ní: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, pé kí wọ́n wá mọ ìwọ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo àti Jésù Kristi, ẹni tí o rán.”​—Jòhánù 17:3.

Jésù máa ń fọ̀rọ̀ àwọn èèyàn ro ara ẹ wò, ó jẹ́ onínúure àti oníwà tútù. Tọmọdé tàgbà, lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló máa ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ torí ó fìfẹ́ pè wọ́n, ó sọ pé: “Ẹ kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, torí oníwà tútù àti ẹni tó rẹlẹ̀ ní ọkàn ni mí, ara sì máa tù yín.” (Mátíù 11:29) Jésù máa ń ṣoore fáwọn obìnrin, ó máa ń pọ́n wọn lé, ó sì máa ń bọ̀wọ̀ fún wọn. Ó yàtọ̀ pátápátá sáwọn kan nígbà ayé rẹ̀ tí wọ́n máa ń hùwà àìdáa sáwọn obìnrin.

Kí la rí kọ́? Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gan-an, ó sì fi àpẹẹrẹ tó dáa jù lọ lélẹ̀ nípa bó ṣe yẹ ká máa ṣe sí ara wa.

JÉSÙ KÌ Í ṢE ỌLỌ́RUN

Ìwé Mímọ́ sọ pé “ní tiwa, Ọlọ́run kan ṣoṣo ló wà” àti pé Jésù Kristi jẹ́ ìránṣẹ́ tó ń fi ìrẹ̀lẹ̀ sin Ọlọ́run. (1 Kọ́ríńtì 8:6) Jésù sọ kedere pé Ọlọ́run tóbi ju òun lọ àti pé Ọlọ́run ló rán òun wá sáyé.​—Jòhánù 11:​41, 42; 14:28. *

^ ìpínrọ̀ 17 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa Jésù Kristi, wo apá 8 àti 9 nínú ìwé Ìgbàgbọ́ Òdodo Ló Máa Mú Kó O Ní Ayọ̀. Ó wà lórí ìkànnì www.mr1310.com.