Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Apá kan ìwé Àìsáyà tí wọ́n rí nínú Àkájọ Ìwé Òkun Òkú wà lókè, ìwé Àìsáyà lédè Arábíìkì tòde òní wà nísàlẹ̀. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò yí pa dà títí dòní

Ṣé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ti Yí Pa Dà Ni?

Ṣé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ti Yí Pa Dà Ni?

Àwọn kan máa ń sọ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà lákọsílẹ̀ ti yí pa dà. Wòlíì Àìsáyà sọ pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “wà títí láé.” (Àìsáyà 40:⁠8) Kí ló mú kó dá wa lójú pé àwọn èèyàn kò tíì yí àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ nínú Ìwé Mímọ́ pa dà?

Kò ṣòro rárá fún Ọlọ́run láti dáàbò bo Ọ̀rọ̀ rẹ̀, káwọn èèyàn má bàa bà á jẹ́. Láyé àtijọ́ tí wọ́n máa ń fọwọ́ kọ Ìwé Mímọ́, àwọn adàwékọ máa ń fara balẹ̀ ka lẹ́tà ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ lọ́kọ̀ọ̀kan láti rí i dájú pé wọn ò fi ohunkóhun kún un, wọn ò yí ọ̀rọ̀ kankan pa dà, wọn ò sì fo ọ̀rọ̀ kankan. Síbẹ̀, torí pé àwa èèyàn jẹ́ aláìpé, àwọn adàwékọ kan ṣàṣìṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́.

KÍ LÓ MÚ KÓ DÁ WA LÓJÚ PÉ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ MÍMỌ́ KÒ TÍÌ YÍ PA DÀ?

Àìmọye àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́ tó jẹ́ ara Ìwé Mímọ́ ló ṣì wà títí dòní. Tí ìyàtọ̀ kékeré kan bá wà nínú ẹ̀dà kan, wọ́n á fi wé àwọn ẹ̀dà míì kí wọ́n lè mọ èyí tí kò ní àṣìṣe. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, wo àpilẹ̀kọ náà, “Ṣé Wọ́n Ti Yí Ohun Tó Wà Nínú Bíbélì Pa Dà?” Ó wà lórí ìkànnì jw.org.

Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìwé àfọwọ́kọ kan wà tí wọ́n ń pè ní Àkájọ Ìwé Òkun Òkú, tí àwọn ará Árábù rí nínú àwọn ihò àpáta nítòsí Òkun Òkú lọ́dún 1947. Ara àwọn Ìwé Mímọ́ ni àwọn ìwé àfọwọ́kọ náà jẹ́, wọ́n sì ti wà láti ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì (2000) ọdún. Nígbà táwọn onímọ̀ nípa ìwé àfọwọ́kọ fi àwọn ìwé yẹn wéra pẹ̀lú àwọn Ìwé Mímọ́ tá a ní lónìí, kí ni wọ́n rí?

Àwọn ọ̀mọ̀wé rí i pé ohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lóde òní bá ohun tó wà nínú ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́ yẹn mu. * Nígbà tí wọ́n ṣàyẹ̀wò àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́ náà kínníkínní, wọ́n rí i pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gangan là ń kà nínú Ìwé Mímọ́ lónìí. Ó dá wa lójú pé Ọlọ́run ti dáàbò bo Ìwé Mímọ́ fún wa títí dòní, ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ sì péye.

Torí náà, ọkàn wa balẹ̀ pé ohunkóhun tá a bá kà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jóòótọ́, ó sì péye. Ní báyìí tá a ti mọ àwọn nǹkan yẹn, ẹ jẹ́ ká wo ohun táwọn wòlíì jẹ́ ká mọ̀ nípa Ọlọ́run.

^ ìpínrọ̀ 7 Ìwé The Complete Dead Sea Scrolls in English, látọwọ́ Geza Vermes, ojú ìwé 16.