Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ó Yẹ Kó O Gba Mẹ́talọ́kan Gbọ́ Kó O Tó Lè Jẹ́ Kristẹni?

Ṣé Ó Yẹ Kó O Gba Mẹ́talọ́kan Gbọ́ Kó O Tó Lè Jẹ́ Kristẹni?

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .

Ṣé Ó Yẹ Kó O Gba Mẹ́talọ́kan Gbọ́ Kó O Tó Lè Jẹ́ Kristẹni?

▪ Ìwé tó sọ̀rọ̀ nípa ìsìn, ìyẹn World Religions in Denmark, tí wọ́n tẹ̀ jáde lọ́dún 2007, èyí táwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga ń lò, ṣàlàyé pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ àwùjọ Kristẹni kan tó kéré tó máa ń tẹ̀ lé ohun tó wà nínú Bíbélì dáadáa. Kódà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni àwùjọ Kristẹni kẹta tó léèyàn púpọ̀ ní orílẹ̀-èdè Denmark.

Àmọ́ inú bí bíṣọ́ọ̀bù ṣọ́ọ̀ṣì tó ń jẹ́ Danish National Church gan-an sí òǹkọ̀wé náà nítorí ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nínú ìwé náà. Kí nìdí? Bíṣọ́ọ̀bù náà sọ pé, “Mi ò tíì rí ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn tó ka àwọn [Ẹlẹ́rìí Jèhófà] sí Kristẹni. Wọn ò gba Mẹ́talọ́kan gbọ́, èyí tó jẹ́ ẹ̀kọ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ẹ̀sìn Kristẹni.”

Ìyáàfin Annika Hvithamar tó kọ ìwé náà jẹ́ onímọ̀ nípa ẹ̀sìn láwùjọ ẹ̀dá, ó sọ pé nígbà tá a béèrè lọ́wọ́ àwọn èèyàn ìdí tí wọ́n fi ka ara wọn sí Kristẹni, kò sẹ́ni tó dáhùn pé ó jẹ́ nítorí pé àwọn gbà gbọ́ pé Ọlọ́run jẹ́ Mẹ́talọ́kan. Síwájú sí i, wọ́n pe àkòrí kan nínú apá kan ìwé náà ní “Ṣé Kristẹni Ni Ẹ́?,” ó sọ pé: “Ẹ̀kọ́ mẹ́talọ́kan jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀kọ́ tó ń dá ìṣòro sílẹ̀ nínú ẹ̀kọ́ ìsìn Kristẹni.” Ó tún sọ pé: “Ìdí tí Ọlọ́run táwọn Kristẹni ń jọ́sìn fi jẹ́ ọ̀kan tí kì í sì í ṣe mẹ́ta máa ń ṣòro nígbà gbogbo láti ṣàlàyé fún àwọn tí kò lọ síléèwé ìsìn.”

Ohun tí Bíbélì kọ́ni nípa Ọlọ́run àti Jésù ṣe kedere, kò sì lọ́jú pọ̀. Ó rọrùn láti lóye. Kò sí ọ̀rọ̀ náà “Mẹ́talọ́kan” nínú Bíbélì, kò sì sí èrò tó fara pẹ́ ẹ rárá. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àkọ́bí ọmọ Ọlọ́run ni Jésù Kristi. (Kólósè 1:15) Ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù ni “alárinà . . . láàárín Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn.” (1 Tímótì 2:5) Nígbà tí Bíbélì ń sọ nípa Baba Jésù, ó ní: “Ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”—Sáàmù 83:18.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé ìgbàgbọ́ nínú Jésù ṣe pàtàkì. (Jòhánù 3:16) Nítorí ìdí yìí, ọwọ́ pàtàkì ni wọ́n fi mú àṣẹ tí Jésù pa pé: “Nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún.’” (Mátíù 4:10) Kò sí àní-àní pé Kristẹni la lè pe ẹni tó bá ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti pa àṣẹ Jésù mọ́.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 22]

“Ẹ̀kọ́ mẹ́talọ́kan jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀kọ́ tó ń dá ìṣòro sílẹ̀ nínú ẹ̀kọ́ ìsìn Kristẹni”