Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Rèbékà Fẹ́ Láti Ṣe Ohun Tí Inú Jèhófà Dùn Sí

Rèbékà Fẹ́ Láti Ṣe Ohun Tí Inú Jèhófà Dùn Sí

Kọ́ Ọmọ Rẹ

Rèbékà Fẹ́ Láti Ṣe Ohun Tí Inú Jèhófà Dùn Sí

ÀWỌN èèyàn máa ń jẹ́ orúkọ náà Rèbékà níbi gbogbo lónìí. Ṣé o mọ ẹnì kan tó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀?— a Rèbékà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹni pàtàkì nínú ìwé kan táwọn èèyàn mọ̀ kárí ayé, ìyẹn Bíbélì. Kí lo mọ̀ nípa Rèbékà?— Ó yẹ ká fẹ́ láti mọ̀ nípa Rèbékà nítorí àpẹẹrẹ rẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ láti sin Jèhófà Ọlọ́run òtítọ́.

Rèbékà ni obìnrin kejì tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pé ó jẹ́ olùjọsìn Jèhófà. Ǹjẹ́ o mọ obìnrin àkọ́kọ́ yẹn?— Sárà ìyàwó Ábúráhámù ni. Sárà ti darúgbó nígbà tó bí Ísákì, ọmọ kan ṣoṣo tó ní. Jẹ́ ká wá ṣàyẹ̀wò bí Rèbékà ṣe fẹ́ ṣe ohun tí inú Jèhófà dùn sí àti bó ṣe fẹ́ Ísákì.

Ó ti lé ní ọgọ́ta [60] ọdún tí Ọlọ́run ti ní kí Ábúráhámù àti Sárà kúrò ní ìlú Háránì lọ sí ilẹ̀ Kénáánì. Nígbà tí Ábúráhámù àti Sárà ti darúgbó, Ọlọ́run ṣèlérí fún wọn pé wọ́n máa bí ọmọ kan, kí wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ísákì. Bọ́rọ̀ ṣe rí yìí, àwọn òbí Ísákì máa fẹ́ràn rẹ̀ gan-an ni. Nígbà tí Sárà kú ní ẹni ọdún mẹ́tàdínláàádóje [127], Ísákì ọmọ rẹ̀ ti dàgbà nígbà yẹn, ikú ìyá rẹ̀ sì bà á nínú jẹ́ púpọ̀. Ábúráhámù kò fẹ́ kí Ísákì fẹ́ ìyàwó láàárín àwọn ọmọ Kénáánì torí pé àwọn èèyàn yìí kì í ṣe olùjọ́sìn Jèhófà. Nítorí náà, ó rán ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ṣeé ṣe kó jẹ́ Élíésérì pé kó lọ fẹ́ ìyàwó wá fún Ísákì nílùú Háránì lọ́dọ̀ àwọn èèyàn òun, ìyẹn sì jẹ́ ìrìn àjò tó lé ní ẹgbẹ̀rin [800] kìlómítà!—Jẹ́nẹ́sísì 12:4, 5; 15:2; 17:17, 19; 23:1.

Nígbà tó yá, Élíésérì dé sí ìlú Háránì pẹ̀lú àwọn kan tí wọ́n jọ jẹ́ ìránṣẹ́ Ábúráhámù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá tó gbé ẹ̀bùn tí wọ́n fẹ́ fún ìyàwó. Wọ́n dúró níbi kànga, nítorí Élíésérì mọ̀ pé àwọn èèyàn máa ń wá síbẹ̀ láti pọnmi fún àwọn ẹran àti ìdílé wọn lọ́sàn-án. Wàyí o, Élíésérì gbàdúrà pé kí obìnrin tó bá máa di ìyàwó Ísákì gbà láti fún òun ní omi mu, kí ó sì sọ pé: “Mu, èmi yóò sì tún fi omi fún àwọn ràkúnmí rẹ.”

Ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn! Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Rèbékà tó “fani mọ́ra gidigidi” wá síbi kànga. Ọ̀dọ́bìnrin náà dá Élíésérì lóhùn, ó ní: “Àwọn ràkúnmí rẹ ni èmi yóò tún fa omi fún.” Bó ṣe ń “sáré léraléra lọ síbi kànga náà láti fa omi,” Élíésérì tẹjú mọ́ ọn “pẹ̀lú kàyéfì.” Rò ó wò ná! Rèbékà ní láti fa omi gálọ́ọ̀nù àádọ́ta lé ní igba [250] kó tó lè pòùngbẹ ràkúnmí mẹ́wàá!

Élíésérì fún Rèbékà ní ẹ̀bùn tó jojú ní gbèsè, ó tún wá mọ̀ pé Bẹ́túélì tó jẹ́ ìbátan Ábúráhámù ló bí i. Rèbékà ní kí Élíésérì àtàwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ wá sílé àwọn kí wọ́n lè “sùn mọ́jú.” Rèbékà tètè lọ sílé, ó sì sọ fún àwọn ará ilé rẹ̀ nípa àwọn àlejò tí Ábúráhámù rán sí wọn láti ìlú Kénáánì.

Nígbà tí Lábánì tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n Rèbékà rí ẹ̀bùn olówó ńlá tó wà lọ́wọ́ àbúrò rẹ̀, tó sì mọ ẹni tí Élíésérì jẹ́, ó ní kó wọlé. Àmọ́ Élíésérì sọ pé: “Èmi kò ní jẹun títí di ìgbà tí mo bá sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀ràn mi.” Nítorí náà, ó ṣàlàyé ìdí tí Ábúráhámù fi rán òun sí wọn. Bẹ́túélì àti ìyàwó rẹ̀ pẹ̀lú Lábánì tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n Rèbékà gbà pé kí Rèbékà fẹ́ Ísákì.

Lẹ́yìn tí wọ́n ti jẹun tán, Élíésérì àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò náà sun ibẹ̀ mọ́jú. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, Élíésérì sọ pé: “Ẹ rán mi lọ sọ́dọ̀ ọ̀gá mi.” Àmọ́ màmá Rèbékà àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ fẹ́ kí wọ́n wà pẹ̀lú wọn “ó kéré tán fún ọjọ́ mẹ́wàá” kí wọ́n tó lọ. Nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ Rèbékà bóyá ó máa bá wọn lọ, ó dáhùn pé, “Mo múra tán láti lọ.” Lójú ẹsẹ̀, ó bá Élíésérì lọ. Nígbà tí wọ́n dé ilẹ̀ Kénáánì, Rèbékà di ìyàwó Ísákì.—Jẹ́nẹ́sísì 24:1-58, 67.

Ṣé o rò pé o rọrùn fún Rèbékà láti fi ìdílé àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sílẹ̀, kó sì lọ síbi tó jìnnà réré, tó sì mọ̀ pé òun lè má pa dà rí àwọn èèyàn òun mọ́?— Kò rọrùn rárá. Àmọ́, Rèbékà rí ìbùkún gbà fún bó ṣe múra tán láti ṣe ohun tí inú Jèhófà dùn sí. Ó wá di ọ̀kan lára àwọn tí a tipasẹ̀ wọn bí Olùgbàlà wa, Jésù Kristi. Àwa náà máa rí ìbùkún gbà bíi ti Rèbékà tá a bá múra tán láti ṣe ohun tí inú Jèhófà dùn sí.—Róòmù 9:7-10.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó bá jẹ́ ọmọdé lò ń ka ìwé yìí fún, má gbàgbé láti dánu dúró níbi tó o bá ti rí àmì dáàṣì (—), kó o sì jẹ́ kí ọmọ náà sọ tinú rẹ̀.

ÌBÉÈRÈ:

▪ Ta ni Rèbékà, ibo sì ni Élíésérì ti rí i?

▪ Kí nìdí tí Ábúráhámù kò fi fẹ́ kí Ísákì fẹ́ ìyàwó láàárín àwọn obìnrin Kénáánì?

▪ Báwo ni Rèbékà ṣe fi hàn pé òun máa jẹ́ aya rere?

▪ Kí la lè ṣe tá a fi lè dà bíi Rèbékà?