Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Francesco Carta fotografo/Moment via Getty Images

Ìṣòro Ìdánìkanwà Túbọ̀ Ń Burú Sí I​—Kí Ni Bíbélì Sọ

Ìṣòro Ìdánìkanwà Túbọ̀ Ń Burú Sí I​—Kí Ni Bíbélì Sọ

 Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe kárí ayé fi hàn pé, a tí wọ́n bá kó ẹni mẹ́rin jọ, ó máa ń ṣe ẹnì kan nínú wọn bíi pé òun dá wà.

  •   “Ìṣòro ìdánìkanwà lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni níbikíbi, ì báà jẹ́ àgbàlagbà tàbí ọmọdé.”​—Chido Mpemba, ọ̀kan lára àwọn alága Àjọ Ìlera Àgbáyé Lórí Ọ̀rọ̀ Àjọṣe Àwọn Èèyàn.

 Àwọn kan rò pé àwọn àgbàlagbà àtàwọn tó máa ń fẹ́ dá wà nìkan ló níṣòro yìí. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ torí kò sẹ́ni tí ò lè níṣòro yìí, ì báà jẹ́ ọmọdé, ẹni tára ẹ̀ le, olówó títí kan àwọn tọkọtaya. Ibi tọ́rọ̀ náà burú sí ni pé ìṣòro yìí lè ṣàkóbá fún ìlera wa, kó sì mú kéèyàn máa ronú lọ́nà tí ò tọ́.

  •   Dr. Vivek Murthy tó jẹ́ ọ̀gá àgbà àwọn tó ń ṣiṣẹ́ abẹ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Àkóbá tí ìṣòro ìdánìkanwà máa ń ṣe fún ìlera jọra pẹ̀lú àkóbá tí ẹni tó ń mu sìgá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) lóòjọ́ ń ṣe fún ara ẹ̀.”

Ohun tí Bíbélì sọ

 Ẹlẹ́dàá wa ò fẹ́ ká máa dá wà. Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn èèyàn, ká sì gbádùn àwọn àkókò tá a bá fi wà pa pọ̀.

  •   Ìlànà Bíbélì: “Ọlọ́run wá sọ pé: ‘Kò dáa kí ọkùnrin náà máa dá wà.’”​—Jẹ́nẹ́sísì 2:18.

 Ọlọ́run fẹ́ ká di ọ̀rẹ́ òun. Ọlọ́run sọ pé òun máa sún mọ́ wa tá a bá sapá láti sún mọ́ òun.​—Jémíìsì 4:8.

  •   Ìlànà Bíbélì: “Aláyọ̀ ni àwọn tó ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, torí Ìjọba ọ̀run jẹ́ tiwọn.”​—Mátíù 5:3.

 Ọlọ́run fẹ́ káwa àtàwọn míì máa jọ́sìn òun. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ara máa tù wá, inú wa á sì máa dùn.

  •   Ìlànà Bíbélì: “Ẹ sì jẹ́ ká gba ti ara wa rò ká lè máa fún ara wa níṣìírí láti ní ìfẹ́ àti láti ṣe àwọn iṣẹ́ rere, ká má ṣe máa kọ ìpàdé wa sílẹ̀, . . . àmọ́ ká máa gba ara wa níyànjú.”​—Hébérù 10:24, 25.

 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ìdí tó fi ṣe pàtàkì ká borí ìṣòro yìí, ka àpilẹ̀kọ náà “Ohun Tó O Lè Ṣe Tó Bá Ń Ṣe Ẹ́ Bí I Pé O Kò Ní Ọ̀rẹ́.”

a The Global State of Social Connections, látọwọ́ Meta and Gallup, 2023.