Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ibi Tó Yẹ Mí

Ibi Tó Yẹ Mí

Wà á jáde:

  1. 1. Ó jọ pé gbogbo ẹgbẹ́ mi

    Ló ti láwọn tọ́n jọ ń kẹ́gbẹ́.

    Mo mọ rere, mo mọ àìdáa;

    Mò ti wá mọbi tó yẹ mí.

    Inú mi dùn pé mo ti mọ,

    Àwọn tó yẹ kí ń bá kẹ́gbẹ́,

    Kí n lè rí ọ̀rẹ́ àtàtà

    Táá gbé mi ró, táá nífẹ̀ẹ́ mi.

    (ÈGBÈ)

    ‘Gbà gbogbo ni mo

    Máa ń ro ọ̀rọ̀ yìí.

    Jèhófà, Ìwọ

    Ni amọ̀nà mi.

    Jọ̀ọ́, jẹ́ n mọbi tó yẹ mí.

  2. 2. Ohun tí mo yàn dá mi lójú.

    Mo mọ̀ pébi tó yẹ mí rèé.

    Ọ̀r’Ọlọrun ló n darí mi,

    O mú mi ṣèpinnu tó tọ́.

    Mo ti wá mọ̀, mo sì tún rí i

    P’ọrẹ tòótọ́ ló yí mi ká.

    Ọmọ ‘yá mi ni gbogbo wọn;

    Jèhófà ló fi wọ́n kẹ́ mi.

    (ÈGBÈ)

    ‘Gbà gbogbo ni mo

    Máa ń ro ọ̀rọ̀ yìí.

    Jèhófà Ìwọ

    Ni amọ̀nà mi.

    Jọ̀ọ́, jẹ́ n mọbi tó yẹ mí.