Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mo Dúpẹ́ fún Ìṣẹ̀dá Ọlọ́run

Mo Dúpẹ́ fún Ìṣẹ̀dá Ọlọ́run

Wà á jáde:

  1. 1. Òdòdó tó rẹwà máa ń dùn-ún wò gan-an,

    Àwọn òkè tó ga, afẹ́fẹ́ tó tura,

    Oòrùn tó ń tàn tún wúlò fún wa gan-an,

    Àwọn ẹyẹ ń fò ní ojú ọ̀run—

    (ṢÁÁJÚ ÈGBÈ)

    Ọlọ́run mi

    Oníṣẹ́ àrà

    Kí ni mo lè ṣe

    Láti fọpẹ́ mi hàn?

    (ÈGBÈ)

    Màá dúpẹ́ oore rẹ

    Màá sọ fún Baba pé

    Mo dúpẹ́ gan-an

    Torí o nífẹ̀ẹ́ wa

    Màá kíyè sí

    Àwọn iṣẹ́ ọwọ́ Jèhófà Ọlọ́run

    Mi ò ní yéé dúpẹ́ fún oore rẹ.

    Mo dúpẹ́ oore rẹ.

    Mo dúpẹ́ oore rẹ.

  2. 2. Ojú ọ̀run dára, ó sì rẹwà gan-an

    Oníṣẹ́ àrà ni ọ, tẹ́wọ́ gba ìyìn mi!

    Ìró odò tó ń ṣàn máa ń tuni lára gan-an,

    Ìràwọ̀ àti òṣùpá ń tàn yòò​—

    (ṢÁÁJÚ ÈGBÈ)

    Ọlọ́run mi,

    Oníṣẹ́ àrà

    Mo mohun ti màá ṣe

    Láti fọpẹ́ mi hàn.

    (ÈGBÈ)

    Màá dúpẹ́ oore rẹ

    Màá sọ fún Baba pé

    Mo dúpẹ́ gan-an

    Torí o nífẹ̀ẹ́ wa

    Màá kíyè sí

    Àwọn iṣẹ́ ọwọ́ Jèhófà Ọ-lọ́-run

    Mi ò ní yéé dúpẹ́ fún oore rẹ.

    Mo dúpẹ́ oore rẹ.

    (ÀSOPỌ̀)

    Agbára àtọgbọ́n rẹ pọ̀,

    Olóore ni ọ́ Baba,

    O sì nífẹ̀ẹ́ wa.

    Mo dúpẹ́ Baba;

    O ṣeun gan-an Baba.

    (ÈGBÈ)

    Màá dúpẹ́ oore rẹ,

    Màá sọ fún Baba pé

    Mo dúpẹ́ gan-an

    Torí o nífẹ̀ẹ́ wa

    Màá kíyè sí

    Àwọn iṣẹ́ ọwọ́ Jèhófà Ọlọ́run

    Mi ò ní yéé dúpẹ́ fún oore rẹ.

    Mo dúpẹ́ oore rẹ.

    Mo dúpẹ́ oore rẹ.

    A dúpẹ́ oore rẹ.